Àìsàn jẹjẹrẹ kọlu àgbà òṣèrè mííràn

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ awọn ololufẹ ere tiata ni wọn tun ti wọle adura fun agba oṣere nni, Musiliu Dasofunjo, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Baba Jogunomi bayii, ti wọn si n rawọ ẹbẹ si adẹdaa lati lọọra ẹmi rẹ.

Alagba Dasofunjo lo ti fi lede nipa aisan to n ba a finra lati bi ọdun meloo sẹyin, to si jẹ ko di mimọ pe ọpọ owo loun tin a lori aisan ọhun.

Dasofunjo rọ awọn ọkunrin kaakiri agbaye lati maa wa ni ikiyesara lori aisan jẹjẹrẹ to nii ṣe pẹlu nnkan ọmọkunrin, iyẹn prostrate cancer.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lati bi oṣu meloo sẹyin ni aisan jẹjẹrẹ ti n dẹmi awọn eeyan, paapaa awọn oṣere tiata ti aye n gba ti wọn lọwọ legbodo.

Awọn oṣere ti ko din ni mẹsan la gbọ pe aisan jẹjẹrẹ oniruuru ti mu ẹmi wọn lọ, to si jẹ pe ti Tope Osoba ati Taiwo Hassan tọpọ mọ si Ogogo ni awọn eeyan ṣi n sọ lọwọ.

Baba Jogunomi lo tu aṣiri aisan jẹjẹrẹ to n ba a finra fun oṣere akẹgbẹ rẹ, Kunle Afod lasiko abẹwo tiyẹn lọ ṣe sii nile rẹ.

Nibi ifọrọwerọ ọhun ni Dasofunjo ti ṣalaye pe aisan to n bao un finra ni ko jẹ koun wa loju iworan awọn eeyan, nipa kikopa ninu awọn ere agbelewo.

Nibi ifọrọwerọ ọhun lo ti rọ awọn ọkunrin lati fi ọrọ toun ṣe arikọgbọn, nipa ṣiṣe ikiyara lori awọn apẹẹrẹ imọlara keekeekee to le ṣokunfa aisan nla si wọn lara.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Nigba to n ṣalaye, Jogunomi sọ pe ṣadeedee loun bẹrẹ sii kiyesi itọ toun n tọ wi pe o yatọ, bo tilẹ jẹ pe oun ko kọbi ara sii nigba naa.

O ni itọ oun yoo pin si ọtọọtọ, dipo ko lọ si oju kan naa, to si loun ko rii bi nnkan babara.

Siwaju sii lo sọ pe, nigba to ya lo di pe iṣoro nla ni yoo jẹ foun nigba toun ba fẹẹ tọ, to si loju ẹsẹ loun ti gba ile iwosan lọ, lati beere ohun to le fa a, lọwọ awọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo.

O sọ pe oniruuru ayẹwo loun ṣe lawọn ile iwosan kaakiri, ko to di pe wọn ni koun lọ si ile iwosan nni, UCH to wa niluu Ibadan.

Baba Jogunomi jẹ ko di mimọ pe, nigba toun de UCH ni oniṣegun oyinbo sọ pe oun yoo ṣayẹwo jẹjẹrẹ miran, leyi ti yoo jẹ ki wọn ge ẹya ara oun.

"Ko ba ma ti de ipele yii rara, ka ni mo tete kọbi ara si apẹẹrẹ ti mo ri nigba naa ni," Baba Jogunomi sọ bẹẹ.

"Mo n sọ eyi sita, lati le jẹ ki awọn eeyan kọgbọn, ki wọn si mọ pe aisan jẹjẹrẹ n gbilẹ sii lojoojumọ.

"Inu itọ mi ni mo ti kọkọ ri apẹẹrẹ naa. Niṣe ni itọ mi n pin kaakiri, dipo ko lọ si oju kan ṣoṣo. Ṣugbọn nko kọbi ara sii.

"Nigba to to asiko kan, Mo bẹrẹ sii ni iṣoro lati tọ, igba yẹn ni wọn too gba mi lamọran wi pe ki n lọ si ile iwosan. Mo ti ṣe oriṣiriṣi ayẹwo. Nibi ti mo ti lọ ṣe ayẹwo ni wọn ti sọ pe ki n maa lọ si UCH n'Ibadan.

Kí làwọn dókítà sọ?

"Ibẹ ni dokita ti sọ pe wọn yoo ge lara ẹya ara mi, lati fi ṣe ayẹwo jẹjẹrẹ," Agba oṣere naa ṣalaye lẹkunrẹrẹ.

O ni ọrọ ti dokita sọ foun yii, ko ibẹrubojo sọkan oun, to si loun sọ pe oun ko fẹẹ gba ki wọn ge ẹya ara oun lati fi ṣe ayẹwo jẹjẹrẹ.

"Nko le gba ki dokita ge ẹya ara mi lati fi ṣe ayẹwo jẹjẹrẹ," o sọ bẹẹ.

O wa rọ awọn eeyan lati maa kiyesara eyikeyi apẹẹrẹ ti wọn ba ri lara wọn, ki wọn si tete fi to awọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo leti, ko too di pe ohun ti wọn yoo maa na owo nla le lori.