Àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn tó kú níbí ìkọlù Ikire n bèèrè fín ìdájọ́ òdodo

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Lọjọ Aje, ọsẹ yii la gbọ pe wahala kan bẹ silẹ niluu Ikire to wa nipinlẹ Osun, nibi ti awọn eeyan ti dagbere, ti awọn ọlọpaa naa si tun farapa yannayanna.

Mọlẹbi awọn to fara kaaṣa ninu ikọlu ọhun ni wọn ti n beere fun idajọ ododo bayii, ti wọn si n pariwo sita pe awọn ọlọpaa ko ṣe otitọ ninu ikọlu naa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti sọrọ lori ohun to ṣokunfa ikọlu to da ẹmi awọn eeyan legbodo, ti wọn si sọ abajade iwadii ti wọn ṣe.

Ṣugbọn awọn mọlẹbi naa, to fi mọ Sẹnetọ Lere Oyewumi to n ṣoju ẹkun idibo Iwọ-Oorun Osun nile igbimọ aṣofin agba ni wọn ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu atẹjade ti awọn ọlọpaa fi sita nipa iṣẹlẹ naa.

Awọn mọlẹbi naa sọ pe ọlọpaa lo da wahala naa silẹ, ti wọn si fẹẹ yi mọ awọn araalu lori, eyi ti wọn ni ko bojumu to.

Nibi ipade awọn akọroyin ti awọn mọlẹbi naa pe lọjọ Ẹti, ọsẹ yii, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026, wọn fidi rẹ mulẹ pe awọn ko le tẹwọ gba abajade ileeṣẹ ọlọpaa naa.

Wọn jẹ ko di mimọ pe ọrọ ti awọn ọlọpaa fi sita, ko ṣafihan okodoro nipa ohun to ṣẹlẹ lọjọ naa, ati pe eyi to ṣe ojurere fun ọlọpaa ni wọn sọ sita, lati fi ru awọn eeyan loju.

A kò tẹ́wọ́ gba àbọ̀ ìwádìí ọlọ́pàá

"Awa nibi lati sọ okodoro, ati lati tako ọrọ awọn ọlọpaa nipa iṣẹlẹ naa, eyi ti wọn fi n fẹsun kan awọn to fara kaaṣa," awọn mọlẹbi naa sọ bẹẹ.

Wọn fẹsun kan ọlọpaa wi pe "wọn n gbiyanju lati yi ọrọ naa", lojuna lati daabo bo awọn ọlọpaa to "ṣeku pa awọn alaiṣẹ lọna aitọ."

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, awọn mọlẹbi naa jẹ ko di mimọ pe awọn ọlọpaa ko faaye silẹ fun awọn mọlẹbi ti ọrọ ṣẹlẹ si lati sọ ohun to ṣẹlẹ, ko to di pe wọn lawọn pari gbogbo iwadii wọn.

"Gẹgẹ awọn ti ọrọ naa ṣẹlẹ si, a ko gba abajade oloju kan ṣoṣo, ati awijare ti awọn ọlọpaa fi sita nipa iwadii ti wọn lawọn ṣe," wọn fi kun ọrọ wọn.

"O y ani lẹnu wi pe awọn ọlọpaa ko fi anfaani silẹ fun awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn lati sọrọ, ko to di pe wọn lawọn pari iwadii. Sibẹ, wọn jade sita lati gbe ọrọ sita, ti wọn si tun n dunkooko mọ awọn afurasi lati sọ ohun ti ko ṣẹlẹ."

Wọn ni ọpọlọpọ ibeere lo yi ohun to ṣẹlẹ naa ka, ti wọn ko sit ii dahun rẹ, paapaa nipa ohun to gbe ọga ọlọpaa ati awọn ọmọṣẹ rẹ wa si garaaji Naira and Kobo.

"Ko si wahala kankan ni garaaji Naira and Kobo lọjọ tiṣẹlẹ naa waye. Fun idi eyi, ki ni ọga ọlọpaa n w ani garaaji Naira and Kobo lasiko naa?" wọn n beere bẹẹ.

"Bi awọn ọlọpaa ṣe yawọ garaaji naa tun jẹ lọjọ ti awọn tọọgi APC ṣeleri lati gba awọn garaaji l'Osun. Ṣe DPO naa wa si garaaji ni, lati ṣe iranwọ fun gbigba garaaji?

Bakan naa ni wọn sọ pe ko si irọ ninu wi pe awọn eeyan lọ ja ibọ gba lọwọ awọn ọlọpaa, ti wọn si bẹrẹ sii yinbọn fun ọlọpaa, wọn ni irọ to jinna si otitọ ni.

"Ki lo de ti DPO ati awọn eeyan rẹ bẹrẹ sii yinbọ lakọlakọ nigba ti alaafia n jọba lọwọ ninu garaaji naa, ati nigba ti ko sẹni kankan to koju wọn?

"Bawo lo ṣe ṣee ṣe fun awọn eeyan ti ko ni nnkan ija oloro lọwọ, ja ibọ gba lọwọ awọn ọlọpaa mẹfa ti wọn di ihamọra ogun?

"A n fi igboya sọ pr awọn ọlọpaa ko tii pari iwadii wọn rara, nitori pe ọna lati daabo bo DPO ati awọn eeyan rẹ to wa ṣiṣẹ buruku ni," wọn sọ bẹẹ.

Ohun tí ọlọ́pàá sọ ṣáájú

Ṣaaju asiko yii, ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun fi sita l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026, wọn ni awọn tọọgi to to ọgbọn ni wọn yabo awọn ọlọpaa, ti wọn si ja ibọn gba mọ wọn lọwọ.

Atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa, Abiodun Ojelade fi sita, sọ pe nibi ikọlu naa ni ibọn tib a awọn eeyan to n lọ, to si tun ba awọn ọlọpaa meji ti wọn sare gbe lọ sile iwosan fun itọju.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe aṣeyọri ninu iwadii si ohun to ṣẹlẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 niluu Ikire, ipinlẹ Osun, nibi ti ọga ọlọpaa Ikire ati awọn eeyan ti sare lọ dahun si ipe pajawiri.

"Ni kete ti wọn de agbegbe Naira and Kobo to wa ni Ikire, awọn tọọgi to di ihamọra ogun to to ọgbọn ni wọn sare ṣe ikọlu si awọn ọlọpaa, ti wọn si fi tipa gba ibọn AK47 lọwọ ọlọpaa kan ninu wọn," atẹjade naa sọ bẹẹ.

Ọlọpaa sọ siwaju pe ọkan lara awọn janduku naa ti wọn n pe ni Ayewo bẹrẹ sii yinbon to ja gba naa soke, to si ba ọlọpaa mẹta ati awọn araalu meji.

Eyi ni wọn lo ṣokunfa iku awọn meji naa, ko to di pe awọn janduku ọhun na papa bora pẹlu ibọn ọlọpaa, gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe ṣalaye.

Wọn loju ẹsẹ lawọn ti gbe awọn ọlọpaa to fara gbọta lọ sile iwosan fun itọju, ki awọn naa ma ba a ku.

"Lẹyin iwadii ti a ṣe nipa iṣẹlẹ naa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun l'Ọjọru, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 rọwọ to afurasi mẹrin ni," ọlọpaa sọ bẹẹ.

Awọn afurasi tọwọ tẹ naa ni: Sikiru Ademola Adedeji, ẹni ọdun mọkanlelogun; Olalere Taiwo, ẹni ọdun mọkanlelogun; Olalere Ademola, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ati Bankole Abiodun toun jẹ ọmọ ogun ọdun.

Bẹẹ ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn gba nnkan ija oloro to da bi ada lọwọ awọna afurasi ọhun.

Bakan naa ni ọlọpaa jẹ ko di mimọ ninu atẹjade wọn wi pe gbogbo awọn afurasi yii ni wọn ti jẹwọ pe tọọgi oloṣelu ni awọn jẹ, ati pe ẹnikan to n jẹ Ayewo, ẹni to ja ibọn AK47 gba ni olori awọn.

"Iwadii ṣi n lọ lọwọ lati rọwọ to Ayewo ati awọn miran ti wọn na papa bora."

Mo wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún - Awakọ̀

Ọkan lara awọn awakọ ti ibọn paayan sinu ọkọ rẹ lọjọ naa ṣalaye ohun ti oju rẹ ri, to si ni awọn rin si asiko nigba naa.

Ọkunrin naa ti ko darukọ ara rẹ sọ pe kii ṣe pe wahala kankan ti n ṣẹlẹ tẹlẹ, ko to di pe awọn bẹrẹ sii gburo ibọn naa.

"Ko sẹni to n ja lasiko yẹn. Ọkọ ọlọpaa lo sare jade, to si di opopona, ibẹ ni mo ti rii pe wahala ti ṣẹlẹ," ọkunrin naa sọ bẹẹ.

"Awọn ọlọpaa ko tii bọ silẹ nigba ti wọn fi bẹrẹ sii yinbọn lati inu ọkọ wọn. Ori irin ni mo wa nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, o si ba mi lojiji, mi o le sọ pe boya ibọn wa lati ibomiran, tabi ko wa lati ibomiran.

"Nureni lorukọ ẹni to jokoo niwaju, nko si mọ orukọ iyawo rẹ. Inu gilaasi ni ọta ibọn gba wọle sii lara."