Kí ló dé tí ìjọba àpapọ̀ yọwọ́ Makinde kúrò níbi ìfilọ́lẹ̀ òpópónà Ibadan sí Ijebu-Ode? Ohun tí a mọ̀ rèé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lọjọ Aje, ọsẹ yii ni ijọba ipinlẹ Oyo fẹsun kan ijọba apapọ ilẹ Naijiria wi pe wọn ko pe Gomina Seyi Makinde sibi ifilọlẹ atunṣe opopona marosẹ Ibadan siluu Ijebu-Ode, to si ni igbesẹ naa kii ṣe ohun to bojumu.

Agbegbe Idi Ayunre to wa nijọba ibilẹ Oluyole nipinlẹ Oyo ni ayẹyẹ ifilọlẹ naa ti waye lọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.

Ijọba ipinlẹ Oyo jẹ ko di mimọ pe igbesẹ naa lo lọwọ oṣelu ninu, eyi ti wọn sọ pe ko lọ ni ibamu pẹlu eto oṣelu awa-ara-wa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Gomina Seyi Makinde ni oludije sipo aarẹ ilẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement, APM ninu eto idibo apapọ ọdun 2027.

Ninu atẹjade ti kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade fi sita fidi rẹ mulẹ pe ohun to ṣẹlẹ naa ni ko ṣẹyin ifigagbaga osẹlu to fẹẹ waye ṣaaju eto idibo apapọ ọdun 2027.

O ni iṣẹ akanṣe opopona naa ṣe pataki pupọ si ipinlẹ Oyo ati awọn awọn ipinlẹ to wa lẹkun Guusu Iwọ-Oorun ilẹ Naijiria, ju ki ọrọ oṣelu yẹpẹrẹ rẹ lọ.

Gomina Dapo Abiodun tipinlẹ Ogun; Minisita fọrọ iṣẹ akanṣe, Dave Umahi; oludije sipo gomina lẹgbẹ APC l'Oyoo, Sarafadeen Alli ati Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja lo wa nibi eto ifilọlẹ naa.

Kò sóhun tó lè dá ìfẹ́ àwọn èèyàn dúró - Ijọba ipinlẹ Ọyọ

Ninu atẹjade naa, Oyelade sọ ọ di mimọ pe ko si awijare kankan ninu idi pataki ti wọn ko fi pe Gomina Makinde sibi ifilọlẹ naa, nitori pe o wa ni isinmi lẹnu iṣẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ipinlẹ naa ni adele gomina lọwọlọwọ, to si jẹ pe ojuṣe adele naa ni lati ṣoju ijọba, bi wọn ba fi iwe pe wọn sibẹ.

O ṣapejuwe eto naa gẹgẹ bi ọrọ oṣelu lasan, eyi ti ko tiẹ le ṣe idena fun iṣakoso Makinde nipinlẹ naa.

"Gbogbo eto lo ti n to fun ọdun 2027, ko si iwa aitọ tabi ifẹkufẹ lati ọdọ ẹnikẹni tabi ẹgbẹ oṣelu kan ti yoo da ifẹ awọn eeyan duro," Oyelade sọ bẹẹ.

O sọ siwaju pe opopona Ibadan si Ijebu-Ode jẹ eyi to ṣe pataki to so ipinlẹ Oyo ati Ogun papọ, bẹẹ lo si tun faaye silẹ lati lọ sawọn ipinlẹ miran kaakiri Guusu Iwọ-Oorun.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe atunṣe ati fifẹ opopona ọhun sii, yoo jẹ ki igbokegbodo ọkọ to ja geere wa fun awọn eeyan, paapaa awọn to n rin irin ajo okoowo laaarin awọn ipinlẹ mejeeji ati awọn agbegbe miran lẹkun naa.