You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo omi Atan tó ń ‘ṣe ìwòsàn, fún ni lọ́mọ’ ní Ikare Akoko, àmọ́ obìnrin tó bá fọwọ́ kàn án, nǹkan oṣù rẹ̀ yóò gbẹ
Oniruuru asa isẹmbaye ati awọn ohun manigbagbe lo wa nilẹ Yoruba eyi ti a ko gbọdọ fi oju di.
Yatọ si awọn eewọ to wa yika wa, awọn ibudo isẹmbaye kan naa wa to jẹ agbayanu tori awọn isẹ iyanu ti wọn n se ati itan to rọ mọ ọpọ wọn.
Iru ibudo isẹmbaye bẹẹ ni Adagun omi Atan lo wa laarin ori oke meji takọtabo nilu Ikare Akoko nipinlẹ Ondo, eyi ti wọn lo kun fun ọpọ ohun iyanu.
BBC News Yoruba de ilu naa lati mọ si nipa omi naa.
"Wọn n pe oke yii ni oke meji takọ-tabo, ori oke ti mo wa yii ni abo, nigba ti akọ wa lọọkan"
Nigba to n salaye itan to rọ mọ omi yii, ọmọ Ọwa Ale tilu Ikare Akoko, Adeniran Adeyemo salaye pe Ọwa Ale akọkọ, ti wọn n pe ni Ọwa Ale Agbaode lo sawari oke naa.
Adeyemo ni nigba ti baba naa fẹ kuro nilu Ile Ife ni Ifa ti sọ fun pe ibi kan wa ti nnkan abami ẹda wa nibẹ, ibẹ si ni ki wọn tẹdo si.
O fikun pe nigba to de ori oke yii, wọn ri omi yii lootọ to kun dẹnu, akoko yii si jẹ igba ọgbẹlẹ, to nira lati ri omi mu.
"Wọn n pe oke yii ni oke meji takọ, tabo, ori oke ti mo wa yii ni abo, nigba ti akọ wa lọọkan.
O si to Ọwa Ale mẹfa to jẹ lori oke yii, ki wọn to sọkalẹ si Atufẹha, Asirigidi niOkegbe.
Awọn isẹ iyanu wo ni Omi Atan yii ti se fawọn eeyan ilu Ikare Akoko?
Mama Titilayo Adegbitẹ tii se Iyaloja ilu Ikare, fidi rẹ mulẹ fun BBC News Yoruba pe omi Atan se iwosan nla fun ọmọbinrin rẹ lasiko to fẹ bimọ.
"Igba ti ọmọ mi bimọ, wọn se isẹ abẹ fun ni, tawọn dokita si gbagbe ọbẹ sinu rẹ, o mu omi naa, ara rẹ si ya.
Ọbẹ to wa ninu rẹ, ti wọn ti sọ pe awọn maa sisẹ fun lati yọ jade, awọn dokita dẹ sisẹ yẹn, tori inu rẹ tobi gan.
A dupẹ pe nigba ti omi yẹn kan sẹnu ọmọ naa, iyanu dẹ sẹlẹ, etutu wa n jade, omi yẹn n sisẹ ara, o n sisẹ iyanu.
"Ọlọrun si gba ọwọ ọkunrin kan sisẹ ara, o bu omi naa fun mi, mo lo o, bi mo si se mu omi naa, ni mo bimọ"
Bakan naa, Mama Risikat Sulaiman tii se Yeye Gbafinro tilu Ikare Akoko ba BBC News Yoruba sọrọ nipa isẹ iyanu ti omi Atan n se.
O ni nigba ti oun ri idaduro, ti oun wa nile ọkọ lai ri ọmọ bi, Oke Atan ni oun lọ.
"Ọlọrun si gba ọwọ ọkunrin kan sisẹ ara, o bu omi naa fun mi, mo lo o, bi mo si se mu omi naa, ni mo bimọ.
Mo dupẹ lọdọ Ọlọrun lonii, ọmọ naa dẹ wa laye, o dẹ wa laaye, o si tun ni aburo rẹpẹtẹ lẹyin."
Awọn eewọ wo lo rọ mọ Omi Atan?
Oloye Bello Mukaila, nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ salaye awọn nnkan ti wọn n se lati se omi naa lọjọ, gẹgẹ bo se wa lati igba atijọ, titi di oni.
Bakan naa lo mẹnuba awọn eewọ to rọ mọ Omi Atan lọkọọkan:
- Obinrin to ba n se nnkan osu, ko le gun ori oke yii
- A ko gba obinrin laaye ko ki ọwọ bọ omi naa tori o jẹ eewọ
- Ti obinrin ba ti ọwọ bọ omi naa, isun rẹ, iyẹ́n nnkan osu rẹ ko ni gbẹ mọ
- Ti o ba ba obinrin ni ajọsepọ, o gbọdọ wẹ, ki o to wa gun ori oke yii
- Ẹni to ba wọ asọ pupa, ko le gun ori oke yii, ẹnikẹni ko si le mu ohunkohun to ba jẹ pupa gun ori oke yii
- Ẹnikẹni ti ko wa ni mimọ, bo lo igba ọdun lori oke yii, ko le ri ohun to n beere fun gba
- Omi yii ko le sisẹ fun ọmọ Yahoo to ba wa sibi
- Gbogbo awọn ewe to ba ti bu omi Atan sori wọn, gbogbo awọn to n se idanwo asejade ile ẹkọ girama, WAEC, maa n yege ni.
Ọrọ iyanju mi ni pe ofin ti wọn ba pa fun eeyan, lasiko to ba fẹ bu omi naa ni ko tẹle.
Amọ BBC News Yoruba ko le fi idid iwadii imọ ijinlẹ kankan mulẹ boya lootọ ni omi yii n se isẹ iyanu kankan.