Wo ìdí tí ìjọba Nàìjíríà fi kéde ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba Naijiria ti kede Ọjọ iṣẹgun ọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹjọ gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.

Isinmi naa wa fun ṣiṣe ayajọ Eid Ul Mawlid to jẹ ayajọ ọjọ ti awọn musulumi jakejado agbaye maa n ṣe ajọyọ ibi Anọbi Muhammad.

Gẹgẹbi atẹjade ti ileeṣẹ eto abẹle nijọba apapọ Naijiria fi sita, eyi ti akọwe agba ileeṣẹ naa, Magdalene Ajani, fọwọ si, wọn rọ awọn ọmọ Naijiria lati wo awokọṣẹ anọbi Muhammad, ki wọn si gbadura fun alaafia orilẹede Naijiria.

Ki ni pataki ajọdun Eid Ul Mawlid

Fun ọpọ Musulumi, wọn maa n lo asiko ayajọ ọdun naa lati ranti awọn ẹkọ ti Anọbi Muhammad kọ nigba aye rẹ ati aanu gbogbo to ṣe.

Awọn miran atilẹ tun maa lo ayajọ ọjọ naa lati gbadura, ṣeto wẹjẹwẹmu, tabi jade pẹlu awọn mọlẹbi wọn.