Èrò bàálù tó gbé àrùn Ebola wọ Kenya kú, wọ́n ń wá èèyàn 28 tó farakínra pẹ̀lú rẹ̀

Orilẹede Kenya ti fidi rẹ mulẹ pe arun Ebola ti wọ orilẹede oun.
Minisita feto ilera nilẹ Kenya, Aden Duale lo sisọ loju ọrọ naa pẹlu alaye pe ọmọ orilẹede naa kan, to ti n gbe ni orilẹede Congo tẹlẹ lati ọdun meje sẹyin lo ko arun ọhun wọle.
Aden Duale ni ọkunrin naa lo bẹrẹ aisan ni osu kan sẹyin, to si gba itọju ni ọpọ ile iwosan nilẹ Congo amọ ni kete to wọ ilu Nairobi, tii se olu ilu ilẹ Kenya, lo gbe ẹmi mi.
Duale alaisan Ebola naa lo wọ ọkọ baalu ni ọjọ Satide, to si la oniruuru ayẹwo kọja ni papakọ ofurufu ni Nairobi ko to di pe ẹbi rẹ kang be lọ sile iwosan kan to wa laarin ilu.
Minisita feto ilera ni Kenya ni oun ti gbe igbesẹ akin lati dena itankalẹ arun Ebola ni orilẹede naa nipa riri ẹrọ ayaworan ọlọfintoto sawọn papakọ ofurufu ilẹ naa ati ẹnu ibode to wọ orilẹede naa.
Bi a ko ba gbagbe, o le ni ẹgbẹrun mẹrin awọn eeyan ti arun Ebola ti pa nilẹ Congo ni ọdun yii nikan eyi to jẹ isẹlẹ to tii buru sikeji lati igba ti arun naa ti bẹrẹ.
Lẹyin ti ilẹ Congo kede pe arun Ebola ti suyọ nilẹ naa losu karun, naa ni arun ọhun tun ba ilẹ Kenya ni alejo, to si gbẹmi eeyan meji nibẹ.
Amọ, ajọ eleto ilera ni agbaye ti kede pe orilẹede Uganda ti bọ lọwọ arun naa losu kẹjọ to kọja.
Lati igba naa, gbogbo ohun to jẹ mọ aisan Ebola lo n wa lati ilẹ DR Congo.
Ki ni itumọ arun Ebola ati idi to se nira lati dawọ arun naa duro lasiko yii?
Arun Ebola to bẹ silẹ nilẹ Congo lasiko yii ni wọn pe ni Bundibugyo eyi ti ko wọpọ rara, ti ko si si abẹrẹ tabi itọju to le wo arun naa san.
Amọ wọn ti n se orisi abẹrẹ mẹrin lọwọ bayii fun iwosan arun Ebola, ti wọn si se ifilọlẹ ọkan lara wọn ni osu keje to kọja.
Duale wa fidi rẹ mulẹ pe ẹya arun Ebola ti wọn n pe ni Bundibugyo lo mu ọmọ ilẹ Kenya to jade laye naa.
O ni alaisan naa rinrin ajo lati ilẹ Congo wa si Kampala, tii se olu ilu ilẹ Uganda, ko to wa wọ baalu wa si Nairob.
Duale ni lẹyin ti wọn gbe de ile iwosan ni Nairobi, ni wọn gbe sinu yara iyasọtọ eyi ti wọn pese silẹ fun arun Covid-19.
O ni yara iyasọtọ naa ni alaisan yii ti "bẹrẹ si ni iba, o n gbọn pẹ pẹ pẹ tori otutu, o rẹ ẹ lati inu wa, o nira fun lati gbe nnkan mi, gbogbo isan ara lo n ro o, ti awọn abẹ awọ ara rẹ si n sẹjẹ."
"Awọn dokita gan fura pe o ni iba to mu ko maa sẹjẹ, ti ayẹwo ti wọn se fun si fihan pe Kokoro arun Ebola Bundibugyo lo n ba agọ ara rẹ ja" Duale lo wi bẹẹ.
Alaisan naa ku ni aago mẹjọ abọ alẹ ọjọ Aje, ti wọn si sin -in lọjọ isẹgun nilana eto aabo ilera to peye.
O kere tan, eeyan mejidinlọgbọn lo ni ibapade pẹlu rẹ, to fi mọ awọn ẹbi rẹ ati awọn osisẹ eleto ilera to se itọju rẹ.
Bẹẹ ni awọn alasẹ eto ilera ti n tiraka lati sawari awọn ero mẹtalelogun ati osisẹ baalu mẹrin ti wọn dijọ wọ baalu.
Agba osisẹ ileesẹ eleto ilera kan salaye pe o seese ki alaisi naa kọja labẹ ayẹwo, ko si yege ni papakọ ofurufu nitori awọn oogun to n lo bo aisan rẹ ni asiri.
Igbesẹ wo ni Kenya n gbe lati dena itankalẹ arun Ebola?
Ilẹ Kenya ti so ẹnu ibode rẹ ko le dain lawọn papakọ ofurufu ati ẹnu ibode to wọ orilẹede naa.
Mínísítà náà wa rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ Kenya láti máṣe bẹru nítorí gbogbo eto ti wá nílẹ̀ ni sẹpẹ láti mú àdínkù bá itankale àrùn Ebola náà.
O w agba àwọn ọṣìṣẹ́ elétò ìlera níyànjú láti máa fi ojú sọri, kí wọ́n sì máa ṣe àmúlò àwọn ìgbésẹ̀ òfin ìlera to lè ka itankalę àrùn náà kò.



























