Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àgọ́ ara rẹ tí o bá lo òògùn Paracetamol lápọ̀jù, tí májèlé rẹ̀ sì wọlé sí ọ lára?

Ọkunrin kan da oogun sọwọ lati inu agolo oni rọba
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ibudo awọn akọsẹmọsẹ onisegun oyinbo lagbegbe Wales nilẹ UK, ti wọn n pe ni The Royal College of Family Physicians in Wales (RCGP) ti daba pe kawọn eeyan maa ka awọn akọsilẹ ati atọna ti wọn fi sara oogun kọọkan, ki wọn to lo oogun naa.

Bakan naa ni ibudo naa tun salaye pe o se pataki lati maa kan sawọn onisegun ka to lo eyikeyi oogun.

Ọkunrin kan to wọ asọ dudu n rẹrin

Gẹgẹ bi ajọ eleto ilera nilẹ Gẹẹsi, British National Health Service (NHS), ti wi, ti eeyan kan ba lo apọju oogun Paracetamol, o le se akoba nla fun Kindinrin ati ẹdọ foro rẹ.

Lara awọn ami ti eeyan le ri lasiko ti majele ara oogun Paracetamol ba wọ agọ ara rẹ ni aya riru, eebi ati inu rirun.

Awọn isẹlẹ yii lo mu ko se koko fun awọn eeyan lati maa se ayẹwo awọn eroja to wa ninu oogun kọọkan, paapaa ti eeyan kan ba n lo oogun to ju ẹyọ kan lọ lasiko kan naa .

Ki ni awọn onimọ sọ nipa oogun Paracetamol?

Ọwọ eeyan kan mu horo oogun Paracetamol dani, awọn tabileti meji ati igo paracetamol naa wa lori tabili

Gẹgẹ bi akọsilẹ tuntun ti ileesẹ to wa feto akojọpọ akọsilẹ nilẹ UK, National Statistics (ONS), ti salaye, eeyan mẹtadinlọgbọn lo ku lagbegbe Wales lọdun 2024 nitori aloju oogun Paracetamol.

Koda, wọn kọ sori iwe ẹri iku wọn pe oogun Paracetamol lo gbẹmi wọn.

Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita to wa lagbegbe Wales, Dokita Will Mcintosh RCGP, salaye pe ohun to wọpọ ni fun awọn ọdọ lati maa mu oogun Paracetamol laimọye igba lai jẹ pe dokita kankan dari wọn lati se bẹẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amọ, o fikun pe o lewu pupọ fun agọ ara ki eeyan kan maa lo orisi oogun meji ti ikọọkan wọn ni eroja oogun paracetamol ninu.

Dokita McIntosh fikun pe ẹru wuwo to wa nidi isẹ sise ati iwe kika lo maa n mu ki ọpọ ọdọ maa lo oogun ti wọn n ta lori igba lai beere itọni nipa lilo rẹ lọdọ awọn dokita.

"Paapaa ajakalẹ arun ba n ba eeyan kan ja, koda, ti ko ba le pupọ ju, o dara lati maa sinmi." Dokita Mcintosh lo sọ bẹẹ.

Bakan naa lo tẹnumọ pe nigba miran, awọn eeyan maa n kẹyin si pataki wiwa aaye lati sinmi nitori pe wọn fẹ wa idẹrun ni kiakia.

"Fun irufẹ awọn aisan yii, agọ ara wa nilo isinmi ati akoko lati baa run ja. Amọ a le lo awọn oogun ti wọn n ta lori igba naa."

O salaye pe awọn ibudo itaja ti wọn ti n ta awọn oogun naa maa n sọrase lati ta oogun sita lọpọ yanturu, idi si ree ti gbekede fi wa nipa iye oogun paracetamol ti eeyan kan le ra.

Dokita naa tun fikun pe awọn onisegun oyinbo naa nimọ pupọ nipa ewu to wa ninu lilo oogun Paracetamol ju iye ti o yẹ fun lilo lọ, paapaa laarin awọn agbalagba.

O ni ewu naa le se akoba pupọ fun awọn agbalagba ti wọn ko ni okun ninu pupọ.

"Nitori naa, a lero pe iye awọn ti eyi yoo se akoba fun ko ni pọ pupọ mọ."

Lẹyin o rẹyin, o wa gba awọn eeyan ni imọran lati maa ka awọn iwe atọna to wa ninu paali oogun kọọkan, ki wọn to lo oogun naa.

Wo awọn ohun to yẹ ki o maa se akiyesi ti o ba n lo oogun Paracetamol

Ẹnikan to wọ asọ alawọ buluu gbe ike Paracetamol to kun fun oogun lọwọ, o n d ọpọ oogun si ọwọ rẹ

Gẹgẹ bi ileesẹ eleto ilera nilẹ UK, National Health Service (NHS), se wi, iye oogun Paracetamol ti agbalagba kan le mu laarin wakati mẹrinlelogun ni oogun Paracetamol mẹjọ to jẹ Kilogiramu ẹẹdẹgbẹta.

Ibudo eleto ilera naa wa sekilọ pe awọn oogun kan ti wọn se lawọn ileesẹ apoogun to ni orukọ gan le ni eroja Paracetamol ninu.

Nitori naa ni wọn se ni yoo dara ki awọn eeyan maa ka iwe atọna to wa lara tabi ninu paali oogun kan, ki wọn to lo o.

Wọn tun se ikilọ pe eeyan kan ko gbọdọ lo oogun Paracetamol leralera ju ọjọ mẹta lọ lai jẹ pe o kan si dokita rẹ.

Bakan naa, ibudo eleto ilera naa tun fewe ọmọ mọ awọn eeyan leti pe ti eeyan kan ba n lo oogun Paracetamol, wọn ko gbọdọ oogun naa pẹlu oogun miran to ni eroja to wa ninu Paracetamol ninu.

Ikilọ ibudo eleto ilera naa si tun kan awọn ọpọlọpọ oogun ti wọn n lo lati setọju naisan Kata ati iba.