You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ohun mẹ́jọ pàtàkì nípa ọdún Iṣẹ̀ṣe nílẹ̀ Yorùbá tí ìjọba Oyo, Ogun àti Eko fi kéde ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́
Gbogbo ogunjọ oṣu Kẹjọ ọdọọdun ni ayajọ ọdun Iṣẹṣe nilẹ Naijiria, paapaa lẹkun Iwọ-Oorun orileede naa.
Awọnoniṣẹṣe lawọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba ṣi n jade sita lati ṣajọyọ ọdun Isẹse yii pẹlu orin, ijo, ati adura gbigba.
Lara awọn ipinlẹ to ti buwọ lu ayajọ naa fawọn oniṣẹṣe naa la ti ri ipinlẹ Ogun, Eko, Osun ati Oyo, ti awọn ijọba naa si tun n kede isinmi fun gbogbo oṣiṣẹ patapata.
Ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun ni awọn ẹlẹsin abalaye ya sọtọ fun ayajọ ọdun iṣẹṣe lati ṣajọyọ ẹsin abalaye lagbaye.
Ki lo de tawọn ijọba ilẹ Yoruba kan kede ọjọ isinmi lẹnu isẹ lati sami ọdun isẹse?
Lati ọdun pipẹ ni awọn agbaagba nidi iṣẹṣe ti n rawọ ẹbẹ si awọn ijọba, paapaa ijọba Naijiria lati buwọ lu ọjọ kan fun wọn ti wọn yoo maa ṣayẹyẹ ọdun iṣẹṣe.
Awọn agbagba ati aṣoju aṣa naa ke gbajare yii, ti wọn si lawọn naa lẹtọọ lati ni ọjọ kan ti wọn yoo maa ṣayẹyẹ ọdun wọn lọdọọdun.
Gbogbo wọn si panupọ ya Ogunjọ osu Kẹjọ ọdọọdun sọtọ lati sami ọdun Isese.
Saaju, ipinlẹ Ọṣun nikan ni wọn ti n kede ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ tẹlẹ lati fi ṣe ajọyọ ọdun Isẹse, eyi si lo mu kawọn ipinlẹ yoku bii Oyo, Ogun ati Eko naa darapọ mọ ipinlẹ Osun.
Bakan naa ni awọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ọyọ wa eekanna mọ gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde lọrun pe ko kede ọjọ ajọdun iṣẹṣe gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.
Lẹyin naa ni ile igbimọ aṣofin ni ipinlẹ Oyo ti buwọlu ofin to ti ọdun Isẹse lẹyin ati kiked ọjọ isinmi lẹnu isẹ fawọn Onisẹse.
Ko pẹ sigba naa si ni iṣejọba gomina Seyi Makinde fi ontẹ lu ofin tawọn asofin buwọlu naa lọdun 2020.
Ki ni pataki ọdun Isẹse nilẹ Yoruba?
Gẹgẹ bi awọn agba awo to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣe sọ, ọdun iṣẹṣẹ jẹ ọdun iranti ipilẹ, ori, ati Olodumare.
Ninu ọrọ tirẹ, Babalawo Jogodo ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba ni ọdun Isẹse ni wọn fi n ranti iṣẹṣe ilẹ Yoruba ni lati dupẹ lọwọ Olodumare.
Awo Jogodo ni awọn ijọba nilo lati tubọ ṣe atilẹyin fun ọdun iṣẹṣe naa nitori ohun ni o n mu iranti wa fun awọn ọmọ karọ o jiire lati mọ pataki wọn ni orilẹ agbaye.
Babalawo Jogodo ni iṣẹṣe ni gbongbo eeniyan ati pe o dara ki a mu imọ nipa ọdun naa kọ awọn ewe yoo mu ki ato ati idurodeede wa lawujọ; yoo si din awọn iwa kotọ gbogbo ku lawujọ.
Agba awo ni ilẹ Yoruba naa sọ ọ di mimọ pe ọdun to yẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba o mu ni koko tori ọdun to so gbogbo wa papọ ni lai fi ti ẹsin miran se.
Jogodo salaye pe yatọ si irẹpọ ti ọdun naa yoo tun mu bawọn ọmọ Yoruba, ọdun naa yoo tun fawọn ọdọ ilẹ yii ni anfaani lati mọ nipa asa ati ise iran wọn.
"Orunmila lo kọkọ fi ipilẹ ilana isẹse lelẹ saaju ẹsin Musulumi ati Kristiẹni, gbogbo ẹlẹsin yoku si lo n tọ ipasẹ ara wọn de idi ẹsin isẹse"
Nigba to n sọrọ lorukọ awọn onisẹse naa, Akọda Awo tilẹ Ibadan, Oloye Ifalere Ọdẹgbọla niṣalaye pe awọn obi, ori, olodumare ni iṣẹṣe ati pe aimọkan lo n ṣe awọn to n ro pe idibajẹ ati iwa okunkun ni.
Akọda Awo ni o yẹ ka jẹ ki awọn araalu mọ pe Isẹse lagba, ayajọ Isẹse yii si ni wọn yoo lo lati gba akanse adura si Ọlọrun ati awọn Alalẹ.
O ni Orunmila lo kọkọ fi ipilẹ ilana isẹse yii lelẹ saaju ẹsin Musulumi ati ti Kristiẹni, nitori gbogbo ẹlẹsin lo n tọpasẹ ara wọn de idi ẹsin isẹse.
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe ẹsin iṣẹṣe ni ẹsin adayeba nilẹ Yoruba, ko to di pe awọn oyinbo alawọ funfun gbe awọn ẹsin bii Kristẹẹni ati Isilaamu wa.
Lara awọn eto to maa n waye lasiko ọdun isese ni adura tawọn ẹlẹsin ibilẹ maa n se, etutu ni orisirisi, iwọde loju popo atawọn eto miran to ni nnkan se pẹlu asa Yoruba.
Ohun mẹjọ pataki nipa ọdun Isese
Wo awọn ohun mẹjọ pataki to yẹ ki o mọ nipa ọdun Isẹse:
- Orukọ ti wọn n pe ọdun naa, Iṣẹ̀ṣe, tumọ si asa ibilẹ ilẹ Yoruba, ọdun naa si lo ni se pẹlu asa ati ise ilẹ wa.
- Oniruuru awọn ẹlẹsin abalaye bii Onisango, Ọlọya, Onifa, Ologun, Babalawo, Ọlọsun ati bẹẹ bẹẹ lọ, lo maa n parapọ se ọdun isẹse.
- Lara awọn ẹlẹsin ibilẹ to maa n se eto lasiko ọdun ibilẹ ni awọn Eleegun, Oloro ati Eyọ
- Awọn ẹlẹsin ibilẹ yii lo wa labẹ aburada ẹgbẹ kansoso ti wọn n pe ni Traditional Religious Worshippers Association Of Nigeria (TRAWASSO)
- Awọn ipinlẹ ti Ọdun Isẹse ti maa n waye ni Osun, Ogun, Lagos, Kwara, Edo, Ondo, Oyo, Ekiti ati Kogi.
- Ogunjọ Osu kẹjọ ọdọọdun si ni ijọba ilẹ Yoruba fontẹ lu fawọn onisẹse lati maa se ọdun naa
- Lara nnkan to maa n waye lasiko ọdun Isẹse ni etutu sise, adura gbigba, orin ati ijo jijo, iwọde ati bẹẹ lọ
- Lọpọ igba, asọ funfun ni wọn saba maa n wọ lati se ọdun Iṣẹ̀ṣe.