Èrò àwọn èèyàn ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí bí Ademola Adeleke ṣe wọlé ṣáá kejì sípò gómìnà Osun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

INEC sọ pe Adeleke bori pẹlu ibo to le ni ẹẹdẹgbẹta (511,067), eyi to fi bori awọn alatako rẹ ti wọn jọ du ipo ọhun.

Kaakiri ijọba ibilẹ ọgbọn ti eto idibo ọhun ti waye, Adeleke bori ni ijọba ibilẹ mọkandinlogun, nigba ti Bola Oyebamiji to ṣe ipo keji bori lawọn ijọba ibilẹ mọkanla.

Giwa agba fasiti apapọ to wa niluu Oye Ekiti, Ọjọgbọn Joshua Ogunwole to jẹ alakoso eto idibo ọhun lo kede Adeleke ni deedee agogo meje kọja iṣẹju mẹrinlelogun ọjọ Aiku, lẹyin akojọpọ gbogob idibo ti awọn araalu di kaakiri.

Awọn ijọba ibilẹ bii Ariwa Ede, Guusu Ede, Ejigbo, Iwo, Egbedore, Ariwa Ife, Ila-Oorun Ife, Aarin-Gbungbun Ife, Oriade, Ifelodun, Orolu, Ayedaade, Ayedire, Odo Otin, Boluwaduro, Iwọ-Oorun Ilesa, Ifedayo, Osogbo ati Ayedire ni Adeleke ti jawe olubori.

Oyebamiji, lo gbegba oroke lawọn ijọba ibilẹ bii Irewole, Isokan, Olorunda, Ila-Oorun Atakumosa, Iwọ-Oorun Atakumosa, Ila-Oorun Ilesa, Boripe, Irepodun ati Obokun.

Alakoso eto idibo naa, Ogunwole ninu ọrọ rẹ sọ pe: "Wi pe lẹyin ti Ademola Nurudeen-Jackson Adeleke ti ṣe awọn ohun amuyẹ labẹ ofin, mo wa kede rẹ gẹgẹ bi oludije to jawe olubori nibi eto idibo gomina to waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, to si pada sipo naa fun saa keji."

Latigba naa ni oniruuru ọrọ ti n jade lori bi Adeleke ṣe wọle sipo gomina lẹẹkeji, to fi jẹ pe nigba ti awọn kan n kii ku oriire, awọn miran n pe fun iwadii lẹkunrẹrẹ lori eto idibo ọhun.

Idi ree ti BBC News Yoruba ṣe ṣe akojọpọ ero awọn araalu nipa abajade eto idibo naa.

Àwọn aráàlú fi ìbo wọn sọ̀rọ̀ - Atiku

Igbakeji aarẹ tẹlẹ nilẹ Naijiria, Atiku Abubakar ti gbe oṣuba kare fun Gomina Ademola Adelele lori aṣeyọri to ṣe nibi eto idibo to waye lọjọ Abamẹta to kọja.

Atiku Abubakar to jẹ oludije sipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC lo fi ọrọ ikini yii ranṣẹ lẹyin ti ajọ eleto idibo INEC kede Adeleke gẹgẹ bi oludije to jawe olubori.

Ninu ọrọ rẹ to fi soju opo 'X' laaarọ oni, Atiku sọ pe "Mo ki Gomina Ademola Adeleke ku oriire lori iyansipo lẹẹkeji gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Osun. Aṣeyọri rẹ lo ṣafihan ẹni ti awọn araalu n fẹ nipa idibo wọn.

Bakan naa lo tun gbe oriyin fawọn araalu lori bi wọn ṣe gba alaafia ati iṣọkan laaye lasiko eto idibo naa.

"Mo gbe oṣuba kare fun awọn eeyan lori ọkan akikanju ati itara ifẹ lati kopa. Mo rọ Gomina Adeleke lati tẹsiwaju awọn aṣeyọri to ti bẹrẹ lati maa sin awọn araalu," Atiku sọ bẹẹ.

Obi, Kwankwaso, Saraki kí Adeleke

Oludije sipo aarẹ Naijiria, Peter Obi ninu ọrọ to fi soju opo 'X' rẹ lọjọ Aiku fi imọ riri han si eto idibo to waye ọhun, to si ni aṣeyọri nla lo jẹ fun Adeleke to pada sipo gomina lẹẹkeji.

O ni eto idibo naa ṣafihan wi pe awọn araalu ni agbara lati yan olori wọn.

"Mo ki Gomina Ademola Adeleke lori eto idibo to gbe e pada sipo lẹẹkeji, bẹẹ ni mo ki awọn ara ipinlẹ Osun fun aṣeyọri eto iṣejọba awa-ara-wa naa," Obi sọ bẹẹ.

Bẹẹ lo sọ pe "Awọn ara ipinlẹ Osun ti sọrọ pẹlu igboya ati idaniloju, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe agbara lati yan awọn adari wa lọwọ awọn araalu.

"Ẹkọ ti eto idibo Osun mu wa ni pe: iṣejọba awa-ara-wa lagbara nigba ti awọn araalu ba ṣe ojuṣe wọn, ti wọn si fi ibo yan ẹni ti wọn fẹ ko dari wọn.

"Gbogbo idibo ni a gbọdọ bọwọ fun, ati pe gbogbo iyansipo ni a gbọdọ daabo bo."

Aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ nilẹ Naijiria, Bukola Saraki, ninu ọrọ toun naa kọ soju opo 'X' rẹ sọ pe idibo igboya lo waye nipinlẹ Osun.

"Mo ki arakunrin mi ati ọrẹ mi, Gomina Ademola Adeleke lori iyasipo pada lẹẹkeji.

"Awọn ara ipinlẹ Osun ti sọrọ, wọn si ti sọrọ to ṣoju-ṣaara. Wọn ti ni ọdun mẹrin lati ṣe idajọ iṣejọba to dara, ati lati ṣagbeyẹwo awọn ileri ati iṣẹ akanṣe to pe ye, wọn si ti sọ pe ko maa tẹsiwaju."

Bakan naa, Gomina tẹlẹ nipinlẹ Kano, Rabiu Kwankwaso ninu ọrọ tiẹ naa loju opo 'X' fi idunnu han si ẹni to pe gẹgẹ bi ọrẹ rẹ, Ademola Adeleke lori aṣeyọri eto idibo to waye l'Osun.

"Gẹgẹ bi olori ẹgbẹ alatako, ati ẹni to to farajin ninu eto oṣelu awa-ara-wa, mo gbe oṣuba kare fun awọn eeyan ipinlẹ Osun lati ṣe ojuṣe wọn, ati ṣiṣe afihan agbara araalu.

Kwankwaso sọ pe abajade eto idibo naa lo ṣafihan pataki kikopa ninu eto idibo, paapaa lati jẹ ki ohun araalu jade sita.

"Aṣeyọri yii lo ran wa leti wi pe awọn araalu ni ojuṣe ti wọn gbọdọ farajin fun, lati jẹ ki ohun wọn jade sita lati gbọ. Ifẹ araalu gbọdọ jọba," Kwankwaso sọ bẹẹ.

Mo ṣì n retí Oyebamiji láti kí mi kú oríire

Nigba to n fi idunnu rẹ han, Adeleke loun dupẹ gidigidi lọwọ Ọlọrun ati awọn ara ipinlẹ Osun lori aṣeyọri naa.

Gomina naa sọ pe oun ṣi n reti alatako rẹ, Bola Oyebamiji lati pe oun lori foonu, ko si ki oun ku oriire lẹyin aṣeyọri eto idibo to waye.

O ni aṣeyọri naa lo waye gẹgẹ bii igbiyanju si eto iṣejọba awa-ara-wa, ati ẹbun fun awọn ara ipinlẹ Osun fun aṣeyọri iṣakoso rẹ.

"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun alagbara. O jẹ aṣeyọri fun eto iṣejọba awa-ara-wa. Aṣeyọri fun eto idibo ipinlẹ Osun," Adeleke sọ bẹẹ lẹyin ikede naa.

"Aṣeyọri yii lo jẹ ọna ti awọn ara ipinlẹ Osun fi san an pada fun mi lẹyin idagbasoke lẹka iṣẹ akanṣe, eto ilera, eto aabo ati awọn miran ti mo ti fifun awọn eeyan mi."

"Mo n reti oludije lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Oyebamiji lati pe mi, ko si ki mi ku oriire. Mo ni Ọlọrun ti kii kuna."

Bakan naa lo dupẹ lọwọ Aarẹ Bola Tinubu, to fi mọ gbogbo awọn alatilẹyin rẹ kaakiri agbaye lori eto idibo to waye naa.

Àjọ SERAP rọ INEC, EFCC, ICPC àtàwọn míìn láti ṣe ìwádìí màgàmágó tó ṣẹlẹ̀ lásìkò ètò ìdìbò Osun

Ajọ kan to n ri sọrọ ẹtọ araalu ati ilana iṣẹ akanṣe, SERAP ti rọ ajọ INEC, EFCC, ICPC lati tọpinpin awọn iṣẹlẹ ti ko bofin mu, eyi to ṣẹlẹ lasiko eto idibo ọhun.

SERAP lo sọ eyi ninu atẹjade ti wọn fi soju opo ayelujara wọn lọjọ Aiku, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe oniruuru iwa fifi owo ra ibo, ṣiṣe idunkooko ati iwa ipa lo ṣẹlẹ lasiko eto idibo gomina ipinlẹ Osun.

"A n rọ awọn ajọ yii lati tọpinpin, ṣe iwadii awọn iroyin nipa fifi owo ra ibo, fifi owo lọ awọn eeyan, ṣiṣagbatẹru eto idibo pẹlu owo, idunkooko, iwa ipa, aṣilo ohun ini ijọba ati awọn iwa miran to tako eto idibo, eyi to ṣẹẹ nibi eto idibo gomina ipinlẹ Osun," SERAP sọ bẹẹ.

Bakan naa ni wọn tun rọ awọn ajọ naa lati "pe awọn oniṣẹ iwadii ati ajọ iṣọkan ilẹ Africa bii AU, ECOWAS, ACHPR atawọn miran fun iranlọwọ ninu iṣẹ iwadii ti ko ni kọlọfin ninu."

SERAP sọ pe awọn ajọ yii ni lati mọ ipilẹ awọn to n fi owo ra ibo, awọn to n ṣe idunkooko ati awọn iwa miran to tako ofin ati ilana eto idibo.