Ìjàmbá ọkọ̀ ló sọ mí di ẹlẹ́sẹ̀ kan, ìdí eré ìdárayá Onídà ni mo ti ń gbọ́ bùkátà ọmọ méjì - Aanu Kumuyi

Ìjàmbá ọkọ̀ ló sọ mí di ẹlẹ́sẹ̀ kan, ìdí eré ìdárayá Onídà ni mo ti ń gbọ́ bùkátà ọmọ méjì - Aanu Kumuyi
Published

Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe ko si ohun ti ọkunrin se, ti obinrin naa ko le se.

Amọ ki ni ka ti wa sọ ti obinrin akanda ẹda kan, Kumuyi Aanu Ajimoh, to wa lori kẹkẹ amọ to n kopa ninu ere idaraya kan to nii se pẹlu ifigagbaga pẹlu Idà.

Ere idaraya onida tabi ọlọbẹ yii la n pe ni Fencing, iyanu si ni pe awọn akanda n kpa ninu ija naa.

Ki lo n jẹ Fencing yii, awọn wo lo n kopa ninu rẹ, awọn anfaani tabi aleebu wo lo wa ninu rẹ, bawo si ni wọn se n se ere idaraya naa?

Obinrin naa, tii se ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, ba BBC News Yoruba sọrọ nipa bo se bẹrẹ idije naa ati ohun to da le lori.

"Ki n to bẹrẹ ere idaraya onida yii, agbabọọlu alapẹrẹ ni mi, ẹni ti ko ba mọ aga onirin lo, ko le dangajia ninu ere idaraya alapẹrẹ"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Kumuyi ni ere idaraya naa lo nii se pẹlu lilo ọbẹ tabi ida lati fi ja.

"Fencing jẹ ere idaraya ti eeyan nilo lati maa gbaradi lori rẹ ni ojoojumọ sugbọn ere idaraya to nilo ọpọlọ lilo ni, ọgbọn lo gba.

Ki n to bẹrẹ ere idaraya onida yii, agbabọọlu alapẹrẹ ni mi, ẹni ti ko ba mọ aga onirin lo, ko le dangajia ninu ere idaraya alapẹrẹ.

Amọ ere idaraya Onida yii rọrun gan, o si tun le diẹ ni ọna kan tori ọpọlọ ni Fencing gba.

Ọrẹ mi kan lo mu mi de idi ere idaraya Onida yii, ti mo fi darapọ mọ wọn."

"Mo rinrinajo ni mo ni ijamba ọkọ, wọn sisẹ abẹ fun mi ninu ẹsẹ naa ni ọdun mọkanlelogun sẹyin"

Bakan naa ni Aanu Kumuyi tun salaye fun BBC News |Yoruba nipa ohun to faa, to se ni ijamba ọkọ.

"N ko le sọ bi ijamba naa se sẹlẹ, amọ mo n rinrinajo ni mo ni ijamba ọkọ.

Wọn sisẹ abẹ fun mi ninu ẹsẹ naa ni ọdun mọkanlelogun sẹyin.

Lati igba naa, n ko mọ nipa isẹ abẹ rara.

O le diẹ, ko rọrun rara tori inu wahala naa ni mo ti bimọ meji.

Ere idaraya onida yii lo mu iyipada diẹ diẹ ba aye mi, ti bukata ko fi wọ mi lọrun pupọ.

Imọran ti mo ni fun awọn eeyan to ni ipenija ara bii ti emi ni pe ki wọn mase maa joko sile, ki wọn ma baa ronu pupọ ju.

Ironu maa n mu ni ku iku aitọ ni, ki awọn naa ja ara wọn