Wo àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kànlá ní Nàìjíríà tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kìlọ̀ pé ó léwu fáwọn èèyàn rẹ láti lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alakoso ilẹ Gẹẹsi ti gbe awọn ikilọ tuntun jade fun awọn ọmọ Naijiria to ba fẹẹ rin irin ajo lọ sawọn ipinlẹ kan.
Ipinlẹ mọkanla ni awọn alakoso ilẹ Gẹẹsi ni kawọn eeyan ṣọra fun nilẹ Naijiria, nitori pe awọn agbegbe naa lewu gidi.
Yatọ si awọn ipinlẹ mọkanla wọnyi, wọn tun ni ki awọn eeyan ṣọra fun awọn agbegbe miran lawọn ipinlẹ mọkandinlogun, to fi mọ Federal Capital Territory tii ṣe olu ilu ilẹ Naijiria.
Àwọn ìpínlẹ̀ wo?
Ajọ ilẹ okeere nilẹ Gẹẹsi kan ti wọn pe ni Commonwealth and Development Office (FCDO) lo gbe awọn ikilọ naa soju opo wọn l'Ọjọbọ, ọsẹ yii.
FCDO tọka si awọn ipinlẹ bii Borno, Yobe, Adamawa, Gombe, Katsina ati Zamfara sọ pe awọn ipinlẹ naa lewu pupọ lati de, to si n ṣe ikilọ fawọn eeyan lati ma ṣe lọ sibẹ.
Bakan naa ni wọn tun darukọ awọn agbegbe odo lawọn ipinlẹ bii Delta, Bayelsa, Rivers, Akwa Ibom ati Cross River.
Ajọ naa sọ pe awọn agbegbe ọhun lo jẹ pe ko sọna ti awọn eeyan le gba debẹ, to kọja ori omi ati ira.
"ko si opopona to de awọn eeyan le gba de awọn agbegbe yii to kọja ori omi ati odo odo nla," ajọ naa sọ bẹẹ.
Fun awọn ipinlẹ mọkandinlogun to ku, to fi mọ FCT, ilẹ Gẹẹsi gba awọn ọmọ ilẹ rẹ lati rin irin ajo lasiko to ba yẹ.
Latra awọn ipinlẹ naa ni: Bauchi, Kaduna, Kano, Kebbi, Jigawa ati Sokoto lẹkun Ariwa.
Awọn yooku ni Niger, Kogi, Plateau, Taraba, Kwara ati Benue, to fi mọ FCT ati Abuja.
Lẹkun Ila-Oorun, ipinlẹ Abia, Anambra ati Imo ni ajọ FCDO sọ pe kawọn eeyan ṣọra.
Àmọ̀ràn
FCDO tun gba awọn arinrin-ajo lamọran pe ki wọn ma ṣe rin irin-ajo si awọn agbegbe to wa lẹgbẹ odo ni awọn ipinlẹ bii Delta, Bayelsa ati Rivers.
Ijọ ilẹ Gẹẹsi rọ awọn eeyan lati ṣọra, ki wọn si maa wa ni ikiyesara, bẹẹ ni ki wọn ṣagbeyẹwo eto aabo ko to di pe wọn rin irin-ajo lọ si Naijiria.
"Awọn alakoso naa sọ pe "ko si agbegbe kankan ti awọn le fọwọ eto aabo to pe ye sọya" fun, ti wọn si rọ awọn eeyan to n murasilẹ lati ṣabẹwo si Naijiria, lati ka awọn amọran ti wọn gbe sita ko to di pe wọn gbera.
Siwaju sii ni FCDO tun sọ fawọn arinrin-ajo lati ṣe iwadii finnifinni nipa ibi ti wọn n lọ, ki wọn si gba iwe aabo ẹmi, ti wọn ba pinnu lati lọ.
O ṣekilọ pe "iwe aabo ẹmi irin-ajo le ma jẹ eyi ti ko wulo, bi o ba rin irin-ajo to lodi si awọn amọran lati ileeṣẹ Foreign, Commonwealth & Development Office (FCDO)."
Àwọn agbègbè wo ni FCDO sọ
Awọn ikilọ tuntun yii lo jẹ pe awọn iroyin bii ilana amuyẹ lati wọle, ewu eto aabo, anfaani si ilera ati iranlọwọ ni Naijiria.
Bakan naa ni wọn tun fi kun un nipa ilana ọmọ bibi igbalode ati oyun igbalode, to fi mọ gbigba ọmọ lati oke okun.
FCDO sọ pe ki gbogbo awọn arinrin ajo rii daju pe wọn gba awọn iwe ẹri to kun ọpọlọpọ ojuṣe ati iranlọwọ, paapaa awọn ohun ti yoo ba jẹ pajawiri.
Awọn agbegbe ti ilẹ Gẹẹsi rọ awọn eeyan lati ma ṣe rin si ni:
Borno
Yobe
Adamawa
Gombe
Katsina
Zamfara
Delta
Bayelsa
Rivers
Akwa Ibom
Cross Rivers




























