Ìtàn Balogun Oderinlo tí àjà gbé lọ fún àádọ́rin ọjọ́, ó padà dé pẹ̀lú àpò àbìrà tí ọ̀sanyìn wà, ó di alágbára fún Ibadan

Laipẹ yii ni BBC News Yoruba ṣabẹwo si agboole ọkan lara awọn akọni ti itan ko le gbagbe ni ilẹ Ibadan, ipinlẹ Oyo.
Ọkan gboogi lara awọn akọni ilẹ Yoruba ni gbajugbaja Balogun Odeyimika Oderinlo, ẹni to jẹ gbajugbaja ọlọdẹ ati jagunjagun nigba aye.
Ogun marundinlaadọjọ ni itan sọ pe Balogun Oderinlo ja nigba to wa laye, to si bori rẹ, ko to di pe o fi aye silẹ lọdun 1850.
BBC Yoruba ṣalabapade ọkan gboogi lara awọn alẹnulọrọ agboole Balogun Oderinlọ, oun lo si ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa irin-ajo akikanju naa.
Adegboyega Olaifa, to jẹ Arole Balogun Oderinlo sọ pe latigba ti wọn ti bi Odeyimika Oderinlo ni wọn ti sọ pe akikanju ọmọ ti okiki rẹ yoo kan ni.
Bẹẹ si ni akọsẹjaye ti wọn wo fun un tun jẹ ko di mimọ pe alagbara ni pẹlu.
Taani àwọn òbí Odeyinka Oderinlo?
Adegboyega Olaifa ṣalaye pe ọkunrin kan to n jẹ Laanile lo ṣe iṣẹ ọdẹ si ilu kan ti wọn n pe ni Ajagba, ilu to fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Ilorin.
Inu ilu naa ni Laanile wa ibujokoo si, ko to salabapade ọmọbinrin kan to n jẹ Oyeniwun, ẹni to jẹ ọmọ baba kan to n jẹ Aragberi nigba naa.
"Laanilẹ ṣọdẹ lọ si ilu Ajagba ni eti Ilorin, ibẹ i o ti pade ọmọbinrin kan ti wọn n pe ni Oyeniwun, ọmọ Aragberi – O fi ṣ'aya, Olaifa sọ bẹẹ.
O ni ko pẹ to fi obinrin naa ṣe iyawo rẹ, lo loyun, to si bi ọmọ ọkunrin.
"Igba ti o bimọ tan, wọn ki i ku ewu, gbogbo wọn ṣọlọjọjọ rẹ.
Wọn wa dahun wi pe baba ọdẹ ti a ri laipẹ yii nkọ, o ni baba ti rin lọ ọ, baba ti rin lọ inu oko," Olaifa ṣalaye bẹẹ fun BBC.
"Ṣe wọn si ti sọ wi pe, nigba ti wọn da akọsẹjaye rẹ, wọn ni alagbara ọmọ ni, ilumọọka ni, ṣugbọn orukọ ti wọn ba kọkọ pe e, to jọ mọ teeyan ni yoo maa jẹ.
"Igba ti wọn n beere lọwọ rẹ, to ni baba tin rin lọ, ni wọn ba fi n pe ọmọ ni Oderinlo, ki Laanilẹ too de."
O sọ siwaju pe nigba ti Laanile de, to gbọ orukọ ti wọn n pe ọmọ rẹ, o "dahun wi pe baba mi Ige Adubi, ọdẹ ni, emi Laanilẹ, ọdẹ ni mi, ẹ tun wa sọ ọmọ mi ni Oderinlo, a jẹ pe ọdẹ yi mi ka niyẹn.
"Idi ree ti wọn fi n pe baba ni Odeyimika Oderinlo. Kii ṣe pe baba rin lọ, ko wale mọ, inu orukọ yẹn ni Oderinlo ti jade."

Àjà gbé Oderinlo lọ fun àádọ̀rún ọjọ́
Arole Balogun Oderinlo fidi rẹ mulẹ fun BBC wi pe nigba ti Oderinlo wa ni ọmọ mẹẹdogun, aja gbe e lọ, to si ya ọpọ lẹnu, nigba ti wọn ko ri i.
Gbogbo akitiyan lati ri Oderinlo lo ja si pabọ, ṣugbọn to pada de lojiji, lẹyin aadọrun ọjọ ti aja ti gbe e lọ.
Kayeefi nla lo jẹ pẹlu awọn ohun ti wọn ri lara rẹ nigba to de, to si jẹ pe latigba naa ni awọn eeyan ti mọ pe alagbara ọmọ ni loootọ.
"Ọdun mẹẹdogun ni Oderinlo wa nigba ti aja gbe e lọ.
Nigba ti aja gbe e lọ, o lo aadọrun ọjọ ki aja too da a pada. Igba ti aja da a pada, o da pada pẹlu ọpa ọwọ rẹ, ẹyẹle ejika rẹ, ati apo abura ti n bẹ lẹgbẹ rẹ," Arole Balogun Oderinlo ṣalaye.
"Ninu apo abura naa, ọsanyin kan n bẹ ninu ẹ, awọn nnkan ti n ṣe alatọna bi Oderinlo ṣe n ṣẹgun ni gbogbo ogun to n ja niyẹn."
Fulani kò rí Ilorin gbà lásìko Oderinlo
Arole Balogun fi kun ọrọ rẹ wi pe gbogbo asiko ti Odeyinka Oderinla fi n gb eniluu Ilorin, ipinlẹ Kwara, awọn Fulani ko ri ilu naa gba.
"Gbogbo igba ti Oderinlo fi wa ni Ilorin, awọn Fulani ko ri Ilorin gba, ṣugbọn nigba ti baba kuro ni Ilorin, o lọ si Olupọna."
O ni kete to de Olupona, ti wọn ti gburo rẹ, ni wọn ti fi jẹ olu-ọdẹ ilu naa, nitori agbara to ni lati ṣọdẹ.
"Igba to de Olupona, wọn fi jẹ Olu-Ọdẹ Olupọna. Wọn ni eeyan nla ni ẹni to de yii o, ẹ jẹ ka fi jẹ Olu-Ọdẹ. Wọn fi baba jẹ Olu-Ọdẹ Olupọna."
Bó ṣe wọ ìlú Ibadan
Laye atijọ, awọn eeyan maa n lọ lati ileto kan si ileto miran lati tẹdo si, ki wọn si bẹrẹ igbe aye tuntun.
Bẹẹ lọrọ ri fun Balogun Oderinlo, to tun fi kuro niluu Olupọna ti wọn ti fi je oye, to si lọ silu Iran.
"Ṣe ẹ dẹ mọ wi pe ara jagunjagun kii balẹ, baba kuro nibẹ, wọn lọ sile Iran – lati Iran, wọn lọ Ile-Ogbo, ibẹ ni wọn ti gbọ wi pe Ibadan tu, ti wọn fi ni ki babalawo d'Ifa pe bo o ni Ibadan yoo ṣe kun," Arole sọ bẹẹ.
Oderinlo fi ìyàwó rẹ̀ tó lóyún àti ọmọ mẹ́fà rúbọ
O ni "Babalawo gbe Ifa ṣanlẹ, o gbe Ifa janlẹ – Ifa sọrọ, o ni – Apẹrẹ ekuru meje, apẹrẹ esan meje, odindi ẹni meje ni wọn yoo fi bọ Ibadan, ti Ibadan yoo fi kun.
"Wọn ti ri apẹrẹ ekuru meje, wọn ti ri apẹrẹ esan meje, o ku odiidi ẹni meje. Balogun Odeyimika Oderinlo lo ko ọmọ bibi inu rẹ mẹfa silẹ, iyawo rẹ to loyun ninu, lo fi ṣe ikeji.
"Wọn du wọn, wọn si fi igba gbe ẹjẹ wọn. Ẹjẹ wọn ni wọn fi fọn ekuru ati isan naa kaakiri.
"Wọn ni ki wọn o fọ-ọn, wi pe ibi ti eera ba ti fi ẹnu gbe ekuru naa de, ibẹ ni Ibadan yoo fẹ de, wọn ṣe bẹẹ. Ṣe Ibadan ti fẹ pari lonii? Ibadan ko tii fẹ pari."

Ogun márùndínláàdóje ni Oderinlo jà
Olaifa to jẹ Arole naa sọ siwaju pe ko to di pe ọlọjọ de, Oderinlo ja ogun ti ko din ni marundinlaadoje, ati pe kii ṣe oju ogun naa lo gba sọda sọrun alakeji.
Arole sọ pe baba naa sun ni, ko si pada ji saye mọ nigba ti ọlọjọ de.
"Ogun marundinlaadoje (145) ni gbogbo ogun ti baba ja, ṣugbọn ogun manigbagbe ti gbogbo wa fi le maa ranti rẹ ni ogun Osogbo – Ogun Fulani Osogbo.
To ba ku bii kilomita meji ti yoo de oju ogun to ti n lọ jagun, Oderinlo yoo duro, ẹyẹle ejika rẹ yoo fo lọ, yoo lọ wo gbogbo oju ogun naa, yoosi ka iye wọn.
"To ba jẹ pe eeyan ọgọrun lo wa nibẹ, yoo sọ fun Odeyinka, tori pe ẹyẹ naa gbọ nnkan ti Odeyinka n sọ, bẹẹ ni Odeyinka naa gbọ nnkan ti ẹyẹle n sọ.
"Yoo sọ fun un wi pe awọn eeyan ọgọrun-un lo n lọ ba a jagun, yoo mu ọpa ọwọ rẹ, yoo pe awọn nnkankan sii, yoo fi na ilẹ, irunmọlẹ bii ẹẹdẹgbẹta yoo dide.
"Ṣe ẹnikan le da eeyan marun-un mu? Awọn iṣẹ ti ọpa yẹn n ṣe niyẹn."
Báwo ló ṣe ṣẹ́gun ogun Fulani Osogbo?
"Lọjọ ti wọn yoo ṣẹgun awọn Fulani l'Osogbo yii, Oderinlo ti mu majele gẹgẹ bi ọsanyin ṣe wi, o ti da a sọwọ, ẹyẹle ti fẹnu gbe e, o ti lọ tu u sinu odo Ibulẹ ti awọn Fulani yẹn n mu," Arole sọ bẹẹ fun BBC siwaju.
O ni awọn Fulani naa n jẹun lọwọ ni, ko to di pe wọn lọ mu omi majele naa.
"Awọn Fulani jẹun tan, ki wọn mu omi, ki wọn sibọ soju ogun, bi wọn ṣe n mu omi ni wọn n ku. Awọn to ye ninu wọn ni baba fi bọ odo.
"Idi ree ti wọn n ki baba ni oriki kan niyẹn."
"Ogun marundinlaadoje (145) ni baba ja ki wọn too jade laye.
"Baba ko ku soju ogun, wọn fọwọ rọri ku sinu ile. Inu yara ti mo jokoo si yii, ibẹ ni wọn fọwọ rọri si – oju oori wọn wa nibi.
"Yara aṣọ agbara wọn wa nibẹ. Yara Ṣango lo tẹle e."

Ohun tí a fẹ́ láti ọ̀dọ̀ ìjọba
Arole wa jẹ ko di mimọ pe pẹlu ogun ti Oderinlo ja fun Ibadan to, ati bo ṣe fi ẹbi rẹ ṣetutu fun ilẹ Ibadan, sibẹ, awọn ijọba gbagbe baba-nla oun.
"Baba ja ogun manigbagbe ni 1840 to jẹ ogun Fulani, wọn si fọwọ rọri ku ni 1850.
"A n gbọ ile-ẹkọ girama Ọba Akinyele, a n gbọ ti Lagelu, a n gbọ ọja Aleshinloye, a n gbọ ọja Bola Ige, Bola Ige kii ṣe ọmọ Ibadan, ọmọ Esa Oke ni.
"Ki wọn tiẹ wa orukọ ọja kan, ki wọn fi sọ orukọ Oderinlo, tabi orukọ ileewe kan, ki wọn fi sọ orukọ Oderinlo, tabi orukọ ijọba ibilẹ kan, ki wọn fi sọ orukọ Oderinlo
"Ko jẹ manigbagbe, wọn ko ṣe bẹẹ. A n fi asiko yii rawọ ẹbẹ si ijọba, ki wọn dakun, ki wọn gba ọrọ wa ro," O kadi ọrọ rẹ nilẹ.






