Àwọn ọmọ Africa wà nínú àwọn tí wọ́n ń wá níbi àjálù ilẹ̀ rírì tó ti gbẹ̀mí èèyàn tó lé ní 160 ní Nepal, èèyàn 800 míràn di àwátì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, eeyan ọgọjọ lo ti padanu ẹmi wọn nigba ti eeyan to le ni ẹgbẹrin mii ti di awati bayii ni Nepal.
Eyii ko ṣẹyin ilẹ riri to waye latari agbara to kọlu aala Nepal ati Tibet.
Iṣẹlẹ naa wọ awọn abule kan lọ, bẹẹ lo ba ọpọ oju popo jẹ nibẹ.
Aarọ kutu Ọjọru ni iṣẹlẹ naa kọkọ waye ni Rasuwa, ni ariwa ilu Kathmandu, to jẹ olu ilu Nepal.
A gbọ pe ilẹ riri wọ awọn yẹpẹ to wa lara awọn oke kan sinu odo Bhote Koshi, eyii to mu ki odo naa ya wọ aarin ilu.
Awọn adoola ẹmi ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari awọn eeyan nibẹ bayii, wọn si ti doola eeyan 88.
Ileeṣẹ iroyin China to n ṣakoso Tibet sọ pe ogunlọgọ ẹmi lo sọnu nibẹ, nigba ti ijọba Nepal ni awọn gbagbọ pe ọpọ awọn mii ni yoo si paanu ẹmi wọn.
Awọn alaṣẹ sọ pe iṣẹ n lọ lọwọ lati mọ ibi ti awọn arinrinajo afẹ 579 wọlẹ si, to fi mọ awọn 466 mii lati orilẹede mejidinlọgbọn ọtọtọ.
Ninu awọn arinrinajo afẹ ti wọn wa lọwọ yii, 113 ninu wọn lo jẹ ọmọ orilẹede Nepal, 54 wa lati ilẹ Amẹrika nigba ti 33 jẹ ọmọ ilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ.
Ileeṣẹ iroyin China naa sọ siwaju si pe eeyan mẹta ti jade laye nigba ti 265 mii ti di awati ni Tibet.
Lara awọn arinrinajo afẹ ti wọn ṣi n wa naa ni eeyan mejila lati ilẹ Gẹẹsi wa, to fi mọ awọn ọmọ ilẹ Amerika, Malaysia, South Africa ati India.
Alpine Eco Trek, to maa n ṣe atọna fun awọn arinrinajo afẹ ni Nepal fidi rẹ mulẹ pe ọmọ ilẹ Gẹẹsi meji ti wọn n ṣe faaji ni aala Nepal ati Tibet ti di awati.
Ram Kumar Adhikari, to jẹ alakoso Alpine Eco Trek sọ pe awọn ọmọ Ireland meji atawọn ọmọ South Africa naa wa lara awọn ti wọn n wa bayii.


























