Wo ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí márùn-ún tó ń da agbègbè Àríwá Nàíjíríà láàmú

Awọn awọn agbebọn kan
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi iṣakoso saa akọkọ ti Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ṣe n tẹnu bepo, gbogbo awọn iṣoro ati wahala agbebọn aṣekupani to wọpọ ninu iṣakoso Aarẹ Muhammed Buhari lo tun ṣi n tẹsiwaju lẹkun Ariwa Iwọ-Oorun Naijiria.

Awọn agbesunmọmi to ti n da agbegbe ipinlẹ Zamfara, Kaduna, Katsina, Sokoto, Kebbi ati Niger laamu lati bi ọdun mẹẹdogun ṣeyin, ti wọn n ji awọn eeyan gbe, pa awọn eeyan danu, ti wọn si n ba awọn abule jẹ kaakiri.

Oniruuru ikọlu awọn agbesunmọmi yii lo ti ko awọn eeyan sinu iporuru ọkan, to si ti ba eto ọrọ aje jẹ, paapaa awọn to gbojule iṣẹ agbẹ ati ọgbin nikan.

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn eeyan lo ti padanu ẹmi wọn, awọn miran padanu ilea ti dukia wọn pẹlu bi wọn ṣe sa asala fun ẹmi ara wọn, nigba ti awọn miran ṣi wa lahaamọ awọn agbebọn titi di asiko yii.

Pẹlu gbogbo ilakaka awọn eleto aabo lati gbogun ti iwa yii, sibẹ, pupọ ninu awọn olori ẹgbẹ agbesunmọmi yii lo ṣi n dunkooko mọ eto aabo Naijiria.

Labẹ iṣakoso Bola Tinubu, ọpọ awọn olori ẹgbẹ aṣekupani yii ni wọn ti pa danu, sibẹ, awọn olori tuntun miran n dide sii lojoojumọ, ti wọn si n dukooko, to si jẹ pe ninu wọn lo ti wa ninu akọsilẹ ti ileeṣẹ aabo lawọn n wa.

Iwadii nipa ikọlu awọn agbesunmọmi ni ẹkun Ariwa Iwọ-Oorun yii lo ṣafihan pe ọpọ awọn olori agbesunmọmi yii lo n dunkooko lawọn buba ti wọn da silẹ funra wọn, nigba ti awọn miran pawọpọ lati gbooro si, ninu iṣẹ ikọlu wọn.

Yusuf Anka to jẹ oniṣẹ iwadii nipa ọrọ aabo, ibọn ati iwa ibọn jẹ ko di mimọ pe bi awọn eeyan ba ni oye nipa awọn olori wọnyi, yoo ni oye ibi iṣoro naa ti bẹrẹ, ati bi ayipada ṣe le wa.

"Awọn eeyan yii ko dide nigba kan naa, gbogbo iṣakoso lo ni olori ti wọn, ati pe ibaṣepọ wa laaarin awọn olori tẹlẹ, ati awọn olori asiko yii," Yusuf Anka sọ bẹẹ.

Ado Aleiro: Gbajugbaja agbebọn

Gẹgẹ bi Yusuf Anka ṣe sọ, Ado Aleiro wa lara awọn olori agbebọn to pẹ julọ lẹkun naa, to si gbajumọ daadaa.

"Agbegbe Yankuzo to wa nijọba ibilẹ Tsafe ni wọn ti bi Ado Aleiro. Ọjọ ori rẹ ti to aadọta ọdun," o sọ bẹẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ Aleiro ni itẹdo si Tsafe, to si n ṣe ikọlu lati ibẹ si Gusau, paapaa oju ọna Gusau-Funtua.

"Iṣẹ wọn ko duro ni Zamfara nikan, wọn tun n wọ awọn agbegbe bii Jibia ati Danmusa nipinlẹ Katsina, leyi to jẹ pe gbogbo awọn ijọba ibilẹ to wa lẹnu ibode Zamfara ni ọrọ naa kan."

Yusuf Anka sọ siwaju pe Ado Aleiro yọ orukọ rẹ jade lati abẹ olori agbesunmọmi tẹlẹ.

"O bẹrẹ lati abẹ akoso Hassan Dan Tawaye, ẹni to gba ipo lọwọ Buhari Daji. Loni, Ado Aleiro ni wọn n ri gẹgẹ bi gbajugbaja olori agbesunmọmi lẹkun naa."