Wo ohun tí òfin sọ nípa kí ọlọ́pàá ti ìpínlẹ̀ kan lọ gbé èèyàn nípìńlẹ̀ míràn, àti kí ẹni tí wọ́n fẹ́ mú takú

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Latigba ti awọn agbofinro ti gbe igbese lati mu gbajumọ Oniṣẹṣe, Ta ni Oloun, pẹlu ipa lati ilu Ibadan lọ si Ilorin ni awuyewuye ti n lọ lori ọrọ naa.
Ọpọ eeyan lo n sọ pe awọn to wa lati mu un naa ki i ṣe ọlọpaa, nitori wọn ko wọ aṣọ agbofinro ilẹ wa.
Bẹẹ lawọn kan n sọ pe bi wọn ba tilẹ jẹ ọlọpaa tootọ, ṣe o yẹ ki wọn ti ipinlẹ miran waa gbe eeyan niluu abinibi rẹ ni.
Eyi ni BBC News Yoruba fẹ tan imọlẹ si, lati mọ ohun ti ofin sọ gan -an lori iṣẹlẹ yii, ti a fi pe Amofin Adedoyin Onanuga to ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ṣalaye pe:
"Ọlọpaa Kwara ko jẹbi bi wọn ṣe fẹ mu Ta ni Olohun n'Ibadan, ofin faaye gba a"
Nigba to n ṣalaye ọrọ naa laaarọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii, Amofin Adeniyi Onanuga sọ pe:
"Ofin fi aaye gba a,bi wọn ba ti ni iwe aṣẹ imuni naa lati ọdọ ẹka ọlọpaa to wa ni ipinlẹ ti wọn ti n bọ, ofin ti faaye gba wọn lati ṣiṣẹ wọn nipinlẹ miran.
"To ba ti jẹ pe ẹni yẹn ṣe ni, ko si aroye lori ẹ, ibikibi ni wọn ti le mu un.
Ọlọpaa Naijiria wa kaakiri ipinlẹ, o si ni ọna ti wọn maa n gba ṣe iru iṣẹ bayii, wọn yoo gba aṣẹ lati ibi ti wọn ti n bọ, wọn a fi ẹda ẹ ranṣẹ si Kọmiṣanna ọlọpaa ibi ti wọn ti fẹ mu ẹni yẹn, pẹlu iyẹn, wọn le gbe e to ba ti jẹ iwa ọdaran lo hu.
"Koda, ko jẹ America lo wa, wọn le gbe e wale.Ofin faaye gba a."
Amofin Onanuga sọ pe aiwọsọ ọlọpaa awọn eeyan to wa mu Ta ni Olohun ko tumọ si pe wọn ki i ṣe ọlọpaa.
O sọ pe kalukulu lo n daa aabo bo aara rẹ niluu yii.
O fi kun un pe bi ọlọpaa ti ko wọṣọ ba ti fi iwe idanimọ rẹ han, o ti to labẹ ofin lati fi ṣiṣẹ wọn.
"Bi Ta ni Olohun ṣe kọ pe ki wọn ma mu oun lodi sofin"
"Eeyan o le kọ fun ọlọpaa pe ko ma mu oun, kikọ yẹn gan-an lo lodi sofin, nitori o tumọ si pe ẹni yẹn ni nnkan kan to fi n pamọ niyẹn.
"Ko si nnkan to ni ki ẹniyẹn ma lọ si agọ ọlọpaa to wa nitosi, ko lọ sọ ọrọ ara rẹ fun wọn lohun. To ba n kọ pe ki wọn ma mu oun yẹn gan -an lo lodi sofin."
Bẹẹ ni Amofin Onanuga wi.
O ni ẹni ti wọn fẹ mu ti ko jẹ ki wọn mu oun ti ṣẹ labẹ ofin, awọn eeyan rẹ ti wọn ko si fẹ ki wọn mu un lọ naa, awọn naa n ṣẹ sofin ni.
"Igbimọpọ lati di igbesẹ ofin tootọ lọwọ ni iru ẹ labẹ ofin.
"Amọran mi fun ẹni ti ọlọpaa ba fẹ mu ni pe ko jọwọ ara rẹ fun wọn, ko si lọ sọ ohun to mọ lori ohun ti wọn tori ẹ fẹ mu un labẹ ofin."
Ileéṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo sọ̀rọ̀ lórí bí ọlọ́pàá Kwara ṣe fẹ́ gbé Ta ni Ọlọhun lọ sí Ilorin láti Ibadan

Latari fidio kan to gbode kan lori ayelujara, eyi to ṣafihan bawọn eeyan kan ti a gbọ pe ọlọpaa ipinlẹ Kwara ni wọn ṣe fẹ gbe gbajumọ ẹlẹsin ibilẹ nni, Ta ni Olọhun lọ pẹlu ipa niluu Ibadan lọ si Ilorin, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fi atẹjade sita lori rẹ lati ṣalaye.
Atẹjade ti DSP Ayanlade Olayinka, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo fi sita lọjọ Iṣẹgun, ṣalaye pe:
"Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Oyo fẹ ko ye gbogbo eeyan, pe awọn agbofinro to wa yẹn n ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu iwe aṣẹ imuni to wa lati ile ẹjọ Majisreeti Ilorin (Upper Ilorin Magistrates' Court).
"O ni i ṣe pẹlu awọn ẹsun to le da omi alaafia ilu ru.
"Aṣẹ naa wa lẹyin ti Ta ni Olohun kọ lati tẹle adehun gbigba oniduuro rẹ ti kootu fun lanfaani rẹ, eyi lo fa a ti ile ẹjọ fi paṣẹ pe ki wọn lọọ gbe e."
Atẹjade naa tẹsiwaju, pe nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ri eyi lo paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa naa pada sibi ti wọn ti wa.
O si gba olupẹjọ nimọran lati lọ sile ẹjọ to yẹ niluu Ibadan, nigba to jẹ ibẹ ni olujẹjọ ti lodi sofin.
Wọn ni eyi ni ilana ti ofin la kalẹ nipa ibi ti iṣẹlẹ ba ti waye.
Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Oyo rọ awọn araalu lati ṣe suuru, ki wọn ma si ṣe huwa ti yoo mu ọrọ naa le ju bo ṣe wa lọ.
Bi wọn ba ni ifotonileti pajawiri, awọn ẹrọ ibanisọrọ wọnyi ni ọlọpaa sọ pe wọn le pe lati kan si Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Oyo:
: 615, 08081768614 ati 07055495413.
Kí ló dé tí Ọlọ́pàá láti Kwara fẹ́ gbé 'Tani Olohun' ní Ibadan, ṣùgbọ́n tí Sunday Igboho fárígá?

Oríṣun àwòrán, screenshot
Laaarọ kutu oni, ọjọ Iṣẹgun ni awọn ọlọpaa ya bo ile gbajumọ ori ayelujara to maa n sọrọ tako ẹsin nni, Abdulazeez Adegbola Ifatimileyin, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Tani Olohun.
Ile rẹ to n gbe niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo lawọn ọlọpaa naa ti ko wọ aṣọ ti lọ ka a mọ, ti wọn si fẹẹ jii gbe lọ.
Ilu Ilorin tii ṣe ipinlẹ Kwara ni wọn sọ pe awọn ọlọpaa ọhun ti wa, pẹlu ọkọ bọọsi alawọ funfun ti ko ni nọmba idanimọ.
Kete ti awọn ọlọpaa ọhun ti de si adugbo ti Tani Olohun n gbe, la gbọ pe wọn ti gba ile rẹ lọ, ti wọn si ni ko tẹle awọn lọ si agọ awọn.
Ṣugbọn a gbọ pe loju ẹsẹ ni ọkunrin naa ti sọ pe oun ko le tẹle ẹnikẹni jade kuro ninu ile oun, ati pe imura wọn ko jọ ti ọlọpaa, bi ko ṣe pe oun fura pe wọn fẹẹ ji oun gbe ni.
Ninu fọnran ti ọkunrin naa gbe soju opo rẹ ni Facebook, eyi ti BBC News Yoruba ri, la ti ri nibi ti awọn ọlọpaa ọhun ti fi agidi gbe Tani Olohun, ti wọn si gbe jade kuro ninu ile rẹ.
Igba ti wọn de ibi ti wọn ti fẹẹ gbe e sinu ọkọ bọọsi wọn, ni Tani Olohun yari mọ wọn lọwọ, wi pe oun ko le tẹle wọn lọ sibikankan.
Lara awọn ara adugbo la gbọ pe wọn da si ọrọ naa, ti wọn si lawọn ko nii jẹ ki wọn gbe ọkunrin naa kuro ni ayika ọhun.
Nibẹ ni awọn eeyan ti bẹrẹ sii ranṣẹ sawọn alẹnulọrọ laaarin ilu lati dide iranwọ fun ọkunrin naa, ki wọn ma ba a jiigbe lọ.
Sunday Igboho dá sí ọ̀rọ̀ náà
Awọn alẹyinju aanu la gbọ pe wọn tete ranṣẹ si olori ẹṣọ aabo ibilẹ nni, Iru Ekun, Sunday Adeyemo tọpọ mọ si Igboho lati wa ṣe iranwọ fun Tani Olohun, lori awọn to fẹẹ jii gbe.
Ninu fọnran ọhun, ni Igboho ti n ba ẹnikan sọrọ, to si n sọ pe oniruuru nnkan lo n ṣẹlẹ kaakiri, leyi to n ko ipenija ba ọrọ eto aabo nilẹ Yoruba.
Igboho ni igbesẹ naa ko bojumu to, nitori pẹ ọrọ ẹsin ni wọn jọ n fa, ati pe awọn ọlọpaa to wan aa ti da wahala nla silẹ, leyi to jẹ ki wọn ti gbogbo ọna to wọ inu adugbo ti Tani Olohun n gbe pa.
"Mo ti sọ fun ọga ọlọpaa ipinlẹ Kwara wi pe ko ma ṣe da si ọrọ ẹsin mọ. Wọn n ji awọn eeyan gbe ni Kwara, wọn n pa awọn eeyan lojoojumọ, wọn n ji ọba ati ijoye gbe, ẹ ko da si eyi, ẹ wa sọ pe ki wọn maa ji eeyan gbe n'Ibadan, ko le ṣee ṣe," Igboho sọ bẹẹ.
"Mo ti sọ fun ọga ọlọpaa Kwara ko ye e da si ọrọ ẹsin mọ."


























