'Ọ̀lẹ aláìfẹ́ṣẹ́ẹ́ṣe làwọn ọ̀dọ́' Enioluwa tọrọ àforíjìn, àmọ́ ṣé 'Eni' nìkan lèèkàn tó fi ọ̀rọ̀ yí gún àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà lára bí? Àlàyé ọ̀rọ̀ rèé

Ade Enioluwa wọ aṣọ kootu, o si fọwọ lẹran
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ori ayelujara n yeruku lala latari awuyewuye lori ọrọ ti Enioluwa Adeoluwa sọ pe ọlẹ ni awọn ọdọ Naijiria.

Alẹnulọrọ ori ayelujara, GehGeh, ti sọ pe omugọ ni awọn to gba pẹlu Enioluwa wi pe ọlẹ lawọn ọdọ Naijiria.

GehGeh sọ pe ijọba Naijiria lo lẹbi lori iṣoro airiṣẹṣe kii ṣe awọn ọdọ ni ko fẹ ṣiṣẹ.

Nigba to n sọrọ loju opo X rẹ, GehGeh ṣalaye wi pe awọn ọdọ orilẹede Naijiria jara mọ iṣẹ, ati pe ọpọ ninu wọn lo n da iṣẹ silẹ fun ra wọn.

GehGeh ni ọpọ ọmọ Naijiria lo n pese iṣẹ fun ra wọn tori ijọba ti kuna lati pese iṣẹ.

''Ẹnikẹni to ba gba pẹlu Enioluwa wi pe awọn ọmọ Naijiria ko fẹ ṣiṣẹ, iru ẹni bẹẹ ko gbọn rara,'' GehGeh lo sọ bẹẹ.

GehGeh sọ fawọn eeyan to n wi pe ọlẹ lawọn ọdọ Naijiria wi pe ki wọn lọ si orilẹede UK ati ilẹ Yuroopu lati lọ wo bawọn ọmọ Naijiria ṣe n ṣiṣẹ nibẹ.

O ni awọn ọdọ n ṣiṣẹ takun takun ni Naijiria, bo tilẹ jẹ pe oriṣiiriṣii iṣoro ni wọn n koju.

Ohun ti ẹni Enioluwa sọ to di ariwo

Nibi apero kan to da lori awọn ọdọ niluu Port Harcourt nipinlẹ Rivers ni Enioluwa ti rọ awọn ọdọ lati jara mọ iṣẹ ki wọn si ni ifarada.

O sọ nibi eto naa wi pe ki awọn ọdọ Naijiria ma reti aṣeyọri ni kiakia tori aṣeyọri kii ṣe nnkan kiakia lọpọ igba.

Enioluwa sọ ninu fidio kan to wa lori ayelujara wi pe ''awọn ọdọ ko fẹran lati ṣiṣẹ kara mọ, wọn si fẹ ṣe aṣeyọri ni kiakia.

Ẹni lati mọ pe ẹ gbọdọ jara mọ iṣẹ yin, ẹ o si gbọdọ kaarẹ lẹnu iṣẹ.''

Enioluwa tọrọ aforijin lori ọrọ to sọ nipa awọn ọdọ Naijiria

Ẹwẹ, Enioluwa ti tọrọ aforijin lori ọrọ to sọ wi pe ọlẹ lawọn ọdọ Naijiria pe wọn o fẹ ṣe iṣẹ kankan.

Enioluwa sọrọ naa nibi eto kan wi pe awọn ọdọ ko fẹ ṣiṣẹ rara ki wọn to gun oge.

O ni gigun oke ko rọrun fun ẹnikẹni, papaa julọ awọn ti ko fẹ ṣiṣẹ.

Enioluwa tun bẹnu atẹ lu awọn ọdọ kan ti wọn maa n ṣe aroye ni gbogbo igba nipa bi nnkan ṣe ri ni Naijiria.

Amọ, lẹyin ti ọpọ eeyan tako o lori ọrọ to sọ, Enioluwa ti ṣalaye wi pe kii ṣe igbagbọ oun ni pe awọn ọmọ Naijiria ko fẹ iṣẹ ṣe

O ni kii ṣe nnkan toun ni lọkan ni lati ṣapejuwe awọn ọdọ Naijiria gẹgẹ bi ọlẹ ti ko fẹ ṣiṣẹ.

Ọdọmọde alẹnulọrọ ori ayelujara wa sọ pe ọpọ ọdọ lorilẹede Naijiria lo tẹpa mọ iṣẹ wọn.

O wa tọrọ aforijin lọwọ gbogbo eeyan ti wọn ti binu lori ọrọ ti o sọ.

Enioluwa ni o ṣee ṣe ki oun sọrọ boun ṣe sọrọ nitori awọn anfaani toun ti ni, lai na-an ni awọn iṣoro tawọn ọdọ n koju ni Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post