Ẹgbẹ́ NLC àti TUC parí ìjà, fẹnukò lórí owó oṣù tuntun fáwọn òṣìṣẹ̀

Awọn alakoso ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC nibi ipade ti wọn ti fẹnuko lori ọrọ owo oṣu tuntun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orin "ija d'opin, ogun ti ṣẹ," lẹgbẹ awọn oṣiṣẹ NLC ati TUC n kọ l'Ọjọru, ọsẹ yii, nigba ti wọ fẹnuko lori awọn ohun to mu wọn kẹyin sira wọn lati bi ọsẹ diẹ sẹyin.

Ko si nnkan meji to jẹ ki ẹgbẹ oṣiṣẹ mejeeji gbena woju ara wọn, bi ko ṣe ti ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira tijọba kede pe wọn yoo fun awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bi owo iranwọ ọkọ wiwọ fun oṣu mẹfa.

Ni bayii, awọn alakoso ẹgbẹ naa ti sọ pe awọn ti fẹnuko lori adehun tuntun nipa ọrọ owo oṣu tuntun ti awọn oṣiṣẹ yoo maa gba kakairi Naijiria.

Awọn adari naa sọ eyi nibi ipade apapọ awọn akọroyin to waye niluu Abuja l'Ọjọru, ọsẹ yii, ti wọn si lawọn yoo gbe aawọ aarin wọn sẹgbẹ kan, nitori pe igbayegbadun awọn oṣiṣẹ lo jẹ wọn logun ju ohunkohun lọ.

Bakan naa, ninu atẹjade ti awọn olori ẹgbẹ mejeeji buwọ lu, wọn ni o ṣe pataki lati fẹnuko lori ohun ti yoo mu igbe aye dẹrun fawọn oṣiṣẹ Naijiria.

Atẹjade ọhun ti Aarẹ NLC, Joe Ajaero ati Festus Osifo to jẹ Aarẹ TUC buwọ lu, fidi rẹ mulẹ pe ọrọ oṣiṣẹ ni ojuṣe awọn, to si kọja ifẹ ara ẹni.

Wọn ṣapejuwe aawọ naa gẹgẹ bi aigbọra-ẹni-ye tinu mọlẹbi, eyi ti awọn ti yanju rẹ ni tubi-inubi, nipasẹ awọn adari wọn tẹlẹ.

Atẹjade ọhun sọ pe, "Iṣọkan awọn oṣiṣẹ Naijiria tobi ju ohun to le fa aawọ laarin awọn adari rẹ lọ. Afojusun wa, itan ti a pin, ati ojuṣe wa ni lati daabo bo ẹtọ awọn oṣiṣẹ, a ko si le fi rubọ lori pẹpẹ aigbọra-ẹni-ye."

Bí ááwọ̀ ọ̀hún ṣe bẹ̀rẹ̀

Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun yii ni awọn aṣoju ijọba ṣe ipade pẹlu awọn alakoso NLC, leyi ti Ajaero lewaju ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ.

Nibi ipade naa ni ijọba ti sọ pe awọn yoo san ẹgbẹrun lọna aadọrin naira fun gbogbo oṣiṣẹ patapata gẹgẹ bi owo iranwọ fun ọkọ wiwọ lọ si ibi iṣẹ.

Ijọba jẹ ko di mimọ pe oṣu mẹfa gbako ni ijọba yoo fi san owo yii fun awọn oṣiṣẹ, lati mu igbe aye dẹrun fun wọn laaarin asiko naa.

Ajaero lo gba ori amohunmaworan lọ lati lọ ṣalaye abajade ipade naa lẹkunrẹrẹ pẹlu ijọba, to si loun ti gba ẹnu gbogbo oṣiṣẹ sọrọ.

Eyi lo jẹ ki Osifo naa jade sita lati sọ pe ko si nnkan to jọ ọ, nitori pe kaka ki NLC sọrọ nipa afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ, niṣe lo tẹwọ gba adehun ti ko le fẹsẹ mulẹ.