Àwọn ohun tí mo là kọjá ló tọ́ mi sọ́nà tí mò ń tọ̀ báyìí - Dieko, ọmọ Kunle Afolayan sọ̀rọ̀

Dieko Afolayan, ọmọ Kunle Afolayan
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Laipẹ yii ni ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja oṣere tiata nni, Kunle Afolayan, iyẹn Dieko Oreoluwa Afolayan ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọkanlelogun.

Dieko gbe awọn fọto rẹ, nibi to ti dirun sori ayelujara, lati fi ki ara rẹ ku oriire.

Ṣugbọn awọn aworan to gbe sita naa da awuyewuye silẹ lori ayelujara, to fi jẹ pe ọpọ awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ baba rẹ ni wọn n sọrọ buruku si lori imura rẹ.

Dieko ni akọbi Kunle Afolayan lọkunrin, ti ọpọ si nigbagbọ pe iṣẹ ti baba rẹ yan laayo, lo yẹ koun naa yan laayo.

Ṣugbọn ọpọ lo gbagbe pe 'ba a ti waye paari laa ri, kadara ko papọ,' – idi ree ti Dieko fi ya ni ilana ti baba rẹ tọ, tii ṣe iṣẹ tiata.

Ko sohun meji to tun mi ku awọn eeyan bẹrẹ sii sọrọ kugbakugbe si Dieko, bi ko ṣe pe Kunle Afolayan ki ọkan lara awọn ọmọ rẹ toun naa n ṣayẹyẹ ọjọ ibi, ṣugbọn ti ko ki Dieko.

Nigba to n ba BBC sọrọ, Dieko jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan to kan awọn mọlẹbi ori ayelujara kan ohun to n ṣẹlẹ ninu idile oun.

O ni ko ṣe dandan fun awọn eeyan lati mọ ajọṣepọ to wa laaarin oun ati baba oun, nitori pe ko si nnkan to kan wọn nibẹ.

"Ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí"

Dieko Afolayan sọ fun BBC pe oun fẹran lati maa kọrin, lati maa se ounjẹ ati lati maa wọ aṣọ, paapaa lati maa ṣe awọn nnkan ti yoo mu inu oun dun.

O ni ẹnikẹni ko le di oun lọwọ lati ṣe nnkan ti yoo mu inu oun dun, ti yoo si jẹ koun pẹ nile aye.

"Mo nifẹ si ki n maa kọrin, se ounjẹ, ki n maa wọ aṣọ, ki n maa ṣe irun, ki n maa ba awọn eeyan sọrọ. Mo fẹran ki n maa ran awọn eeyan lọwọ," Dieko sọ fun BBC bẹẹ.

O tẹsiwaju pe, "Mo nifẹ lati maa da wa, to maa fun im lanfaani alti ronu daadaa, awọn nnkan ti mo nifẹ si nipa ara mi niyẹn."

"Àwọn ohun tí mo là kọjá ló tọ́ mi sọ́nà"

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe awọn alakọja oun lo tọ oun sọna lati mọ awọn nnkan toun fẹẹ ṣe nile aye.

"Nigba ti mo n dagba, o ni awọn nnkan ti mo n la kọja, lo tọ mi sọna lati mọ awọn nnkan ti mo fẹẹ ṣe laye mi.

"Mo jẹ ẹnikan to fẹran lati maa wọ aṣọ gan, ki maa n ṣe irun ati awọn nnkan to ma jẹ ki n rẹwa."

"Ẹ̀rù maá ń bà mí tẹ́lẹ̀"

Dieko Afolayan, ọmọ Kunle Afolayan
Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Dieko sọ fun BBC pe ko too di pe oun bẹrẹ sii gbe nnkan sori ayelujara, ẹru maa n ba oun lori nnkan ti awọn eeyan yoo sọ.

Ṣugbọn nigba to ya, o loun sunra ki, oun si gbe gbogbo ero naa kuro lọkan, toun si bẹrẹ sii ṣebi akikanju.

O loun ko fẹ ki igbe aye oun jẹ eyi toun yoo maa gbe fu ẹnikẹni, bi ko ṣe fun oun nikan, nitori pe onikaluku lo wa aye tiẹ.

"Nigba ti mo gbe awọn fọto naa sori ayelujara, mo tiẹ ti mọ tẹlẹ pe awọn eeyan maa sọrọ.

"Ki n to maa gbe nnkan sori ayelujara, mo maa n bẹru tẹlẹ nipa ohun ti awọn eeyan yoo sọ, bii pe o yatọ si mọlẹbi rẹ, oun ni tiẹ yatọ.

"Ṣugbọn o de igba kan, ti mo kan ro pe, awọn eeyan kan ma maa sọrọ naani. Mi o ro pe ibi ti mo fẹẹ de, wọn le ni ipa kankan nibẹ.

"Mi o fẹ ki aye mi jẹ aye ti mo maa maa gbe fun ẹnikan, nitori pe aye mi ni, mo si ti di ọdọ, mo si le yan ohun to wu mi latiu fi aye mi.

"Ohun ti awọn eeyan maa n ṣe, maa n ni ipa, mi o ro pe awọn to ba n ka nnkan ti awọn eeyan ba n sọ sabẹ ohun ti mo ba gbe sita le dun mọ wọn ninu.

"Wọn tiẹ maa n beere lọwọ mi pe, bawo lo ṣe maa n ri lara mi, ti mo si maa gbe kuro lara, ṣugbọnm mo lero pe nitori awọn to n wo mi gẹgẹ bi awokọṣe, mo ti ṣe ipinnu pe bi ohunkohun ba tiẹ ṣẹlẹ, mo ni lati duro ṣinṣin.

"Awọn kan tiẹ maa sọ fun mi pe eeyan gidi ni baba mi, ki lo de ti mo n ṣe baba mi bẹẹ, ati oniruuru nnkan miran bẹẹ."

"Mo fẹ́ẹ́ fi ipa rere tèmi sílẹ̀"

Ọmọkunrin naa sọ pe ọpọ lo maa n fẹ koun tẹle ipa ti baba oun n fi lelẹ, to si ni ko le ri bẹẹ, nitori pe ọtọọtọ ni nnkan toun pẹlu baba oun nifẹ si.

Bẹẹ lo sọ pe oun ko lero pe awọn eeyan ori ayelujara lẹtọ lati mọ ohun to n ṣẹlẹ laaarin oun ati baba oun.

"Awọn eeyan to ti sọ pe mo n ba apẹẹrẹ ti baba mi fi lelẹ jẹ, iwọ to yẹ ko maa gbajumọ okoowo baba rẹ.

"Mi o lero pe awọn to wa lori ayelujara ni ẹtọ lati mọ ohun to n ṣẹlẹ laaarin emi ati baba mi, ati ninu idile mi.

"Mo jẹ eeyan kan to pamọ, ohun ti mo si ma maa jẹ titi lailai niyẹn, ohun ti wọn ba fẹẹ sọ, ki wọn maa sọ ọ.

"Nnkan ti mo ṣa fẹẹ sọ ni pe mo n fi ipa rere ati aye temi, to fi mọ ọna temi lelẹ, ko sẹni to lẹtọ si ohun to n ṣẹlẹ laye mi, nigba ti kii ṣe pe awọn lo n bọ mi, awọn kọ lo n fun mi lounjẹ, awọn si kọ lo n san owo ile-ẹkọ mi."

O fi kun ọrọ rẹ pe ọpọ awọn to n sọrọ soun lori ayelujara, lo jẹ pe wọn ko ni le sọrọ, nigba ti wọn ba pade oun nita, nitori pe ori ayelujara nikan ni wọn ti lẹnu.

"Ti ẹ ba ri mi nita, ẹ ko ni sọ nnkankan, o dabi ẹni pe ayelujara ti fun awọn eeyan ni ẹmi," o sọ bẹẹ fun BBC.

"Ìdí tí mo ṣe fa aṣọ ya mọ́ra mí lára"

Nigba to n sọrọ nipa awọna dojukọ to ba pade bo ṣe dagba, o ni awọn nnkan toun ko le gbagbe ni, to si loun n dupẹ pe oun ko ba awọn adojukọ naa lọ.

"Nnkan to su mi debi pe mo fẹẹ pa ara mi nigba yẹn, nitori pe mo jẹ ẹnikan ti kii sọrọ, fun idi eyi, ti awọn ero ọkan mi ba ṣe n pọ si, o maa n ru mi loju

"Lọjọ kan ni mo fa aṣọ ya mọ ara mi lara, ti mo sọ pe o ti su mi, mi o fẹ gbe ile aye mọ.

"Bakan naa ohun ti wọn maa n pe ni ifipabanilopọ ṣẹlẹ si mi ni kekere, o si da mi lọkan ru gidi, kii ṣe nnkan kekere. O ṣe akoba pupọ fun mi, ṣugbọn ogo ni fun Ọlọrun wi pe mo wa nibi loni.

"Mo tun jẹ ki awọn to fẹran mi yi mi ka, wọn si n fẹ rere fun mi.

"Mi o ro pe mo ni erongba lati lọ sinu tiata, ti mo ba tiẹ wọnu ẹ, nko le pẹ nibẹ, nitori pe kii ṣe nnkan ti mo nifẹ si. Nnkan ti mo ri ni pe, baba mi ati awọn yooku n ṣe ti wọn, mi o si rii gẹgẹ bii pe emi naa gbọdọ ya si."