Àgbà òṣèré tíátà, Taiwo Hasan Ogogo ti jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Taiwo Hassan, ti ọpọ mọ si Ogogo ti jade laye.
Ogogo lo jade laye lẹyin to ti kọkọ ba aisan jẹjẹrẹ firan.
Omọ rẹ obinrin, Kira Taiwo, lo fi ikede iku rẹ sita ni irọlẹ ọjọ Aiku lojun opo Instagram rẹ.
Lẹyin naa ni agba oṣere mii, Saheed Balogun tun ikede ọhun sita nibi to ti sọ pe "Inna lillahi wa inna ilayhi raji'un. O le sinmi bayii arakunrin mi, Taiwo Hassan Ogogo. Ki Ọlọrun tẹ ọ si afẹfẹ rere."
Ti ẹ ko ba gbagbe, aarọ ọjọ Isẹgun to kọja la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn ọmọbinrin gbajumọ osere tiata naa, Shakira ati Haleemah Taiwo figbe bọnu lori ayelujara pe aisan jẹjẹrẹ n se baba awọn.
Lẹyin ikede naa ni wọn wa n beere fun iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria ki baba wọn le gbadun, ti wọn si n ke sawọn oni\degun oyinbo ati ti ibilẹ to ba le wo baba wọn san lati jade wa.
Awọn ere ti Ogogo ti kopa

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan Ogogo
Iwọn yii ni diẹ lara awọn ere manigbagbe ti Taiwo Hassan Ogogo ti kopa:
- Atitebi (1994)
- Agbelebu (1995)
- Agbo-Odaju (1995)
- Owo Blow parts 2,3 (1996) oun ni Wole Owolabi
- Omin (2008) o se Adesina
- Elewon (2009) o se Yomi
- Omo Ghetto (2010) as D.P.O
- Aye O (2016) o se Faniyi
- Ọjọ ẹyẹ mi (My Joyous Day) (2016)
- Tenant of the House (2019) o se Hon. Kasali
- Amerah (2021) o se Alhaji
- Aníkúlápó (2022) o se Alaafin Ademuyiwa
- Bank Alert (2023) O se baba agba
- IGE - the unlikely oil merchant (2023) oun lo se Olalere
- Anikulapo: Rise of the Spectre (2024) o se Alaafin Ademuyiwa
Ta ni Taiwo Hassan Ogogo?
Ọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹwa ọdun 1959 ni wọn bi Taiwo Hassan, ti ọpọ eeyan mọ si Ogogo.
Ọmọbibi ilu Ilaro, to wa ni agbegbe Yewa nipinlẹ Ogun nii se, to si jẹ ibeji, tori ibeji ni wọn saba maa n bi ninu idile rẹ.
Bakan naa ni baba ati iya rẹ naa jẹ ibeji.
Ogogo pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ nile ẹkọ Christ Church nilu Ilaro, ko to morile ile ẹkọ girama Gazikia College nilu Eko.
Amọ Ogogo ko le pari ile ẹkọ girama naa tori ọda owo, lẹyin naa lo wa lọ sile ẹkọ ẹkọsẹ ọwọ nibi to ti kọ nipa isẹ atọkọse, ti a mọ si Mẹkaliki.
Gbajumọ osere tiata naa si sisẹ bii Mẹkaliki fun ọdun mẹtala gbako nileesẹ to n pese omi, water corporation.
Ogogo bẹrẹ isẹ tiata lọdun 1981 ni kete to bẹrẹ isẹ mẹkaliki, to si kuro lẹnu isẹ mẹkaliki nileesẹ Water Corporation lọdun 1994, ko le gbajumọ isẹ tiata to yan laayo.
Agba osere naa ti gba oniruuru ami ẹyẹ nidi isẹ tiata, to si tun gba ami ẹyẹ ipa to ko ninu ere Anikulapo, tii se Alaafin Oyo.




























