You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé ohun tó fa ilẹ̀ rírì Nepal tó mú ẹ̀mí èèyàn 700 lọ
Iṣẹlẹ omiyale ati ilẹ riri to waye ni aala orilẹede Nepal ati Tibet ti mu ẹmi eeyan to le ni 700 lọ nigba ti wọn ṣi n wa eeyan 2,400 mii bayii.
Ileeṣẹ iroyin China, CCTV, jabọ pe eeyan 16 lo ku lo ni Tibet nigba ti ọpọ ile ti wo lulẹ nibẹ.
Ọjọru to kọja ni iṣẹlẹ naa waye to si wọ ọpọ ile ati dukia lọ lawọn agbegbe to yi aala naa ka.
Awọn adoola ẹmi sọ pe ọrọ naa ti doju ẹ bayii latari bo ṣe ṣoro lati de ọdọ awọn ti wọn ko tii doola, ati pe o tun ṣeeṣe ki omiyale mii waye lẹyin iṣẹlẹ yii.
Ki lo fa iṣẹlẹ naa?
Iwadii ileeṣẹ US Geological Survey (USGS) fi han pe nnkan ti wọn n pe ni 'glacier' to wo lo faa, iyẹn "glacial collapse."
Wọn ni eyii lo lagbara to bẹẹ to fi mi isalẹ omi to wa nibẹ titi.
Eyii lo faa ti omi odo ọhun fi ṣan pẹlu agbara fun ọgọrun kilomita to si lọ ṣọṣẹ ni iha Ariwa Nepal.
Iye eeyan to ti ku atawọn to di awati
Lọwọ yi, ojojumọ ni iye awọn to n ku atawọn to di awati n pọ si.
Amọ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, apapọ eeyan 734 la le fidi rẹ mulẹ pe wọn ti dagbere faye nigba ti wọn ṣi n wa apapọ eeyan 2,498.
Ijọba orilẹede naa ti kede apapọ ọmọ ilẹ okeere ti iye wọn jẹ 261 ti wọn ni wọn ko mọ ibi ti wọn wa ti wọn ko si le kan si bayii.
Ọgagun Rajaram Basnet to n gbẹnusọ fun ileeṣẹ ọmọ ogun Nepal sọ fun BBC pe bi agbebe naa ṣe ri, ojo to n rọ leralera ati oju ọjọ n mu ko ṣoro fun awọn lati doola awọn eeyan to ha.
Awọn orilẹede ti awọn eeyan wọn wa ninu iṣẹlẹ naa ni India China, Amẹrika, Ukraine, Malaysia, Australia, UK, South Africa ati Canada.