Kí ló mú kí ọkùnrin kan fi ọ̀bẹ pa èèyàn kan nílé sinimá l'Eko, tí ẹ̀mí òun náà fi bọ́? Àlàyé rèé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa iku awọn meji kan nile iworan, IMAX Cinemas to wa lagbegbe Lekki nipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Adebisi Abimbola lo fidi rẹ mulẹ fawọn akọroyin lọjọ Abamẹta to kọja yii.

Ọkunrin kan ti wọn lo ti fa ifakufa sara ni wọn lo gun ẹṣọ aabo ile iworan naa titi to fi jade laye, to si tun ṣe ẹṣọ aabo miran leṣe, iyẹn lalẹ ọjọ Ẹti to kọja yii.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, ọkunrin naa lo lọ si sinima ọhun pẹlu nnkan ija oloro bii ada ati ọbẹ, to si loun fẹẹ wọle.

Bi awọn ẹṣọ aabo ṣe ri ọkunrin naa, ni wọn ti sọ fun un pe ko le wọle, ati pe kii ṣe iru eeyan bii tiẹ ni wọn n wa nibẹ.

Ọrọ yii ni wọn lo bi ọkunrin naa ninu, to fi fa ọbẹ ati ada ọwọ rẹ yọ, to si gun ọkan lara awọn ẹṣọ aabo ọhun, ẹni ti wọn lo ku loju ẹsẹ.

Nibẹ naa lo tun ti gun ẹṣọ aabo kan yooku, tiyẹn naa si sa asala fun ẹmi ara rẹ, ko to di pe awọn eeyan to wa nibẹ lọ dawo bo o.

Irú èèyàn wo ni ọkùnrin náà?

Lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe aṣọ idọti lo wa lọrun ọkunrin naa, ti igbagbọ si wa pe ko ni ibikankan to n gbe.

Wọn ni irisi rẹ jọ ti ẹni to ti mu ọti, to si tun ti fa egboogi oloro, ati pe ọrọ ẹnu rẹ ko ba ti eeyan gidi mu.

Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀

Agbẹnusọ ọlọpaa naa, Adebisi Abimbola sọ pe afurasi naa ku ẹṣọ aabo pa, to si tun ṣe ipalara fun ẹṣọ aabo miran to wa ni sinima naa.

"Eeyan meji la le fidi rẹ mulẹ pe wọn ti ku," Adebisi sọ bẹẹ fawọn akọroyin, to si jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ.

O ni awọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ iru eeyan ti ọkunrin to ṣe ikọlu naa jẹ, ki awọn si le mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe awọn ti mu ọga ẹṣọ aabo sinima naa si ahamọ awọn, lati gbọ ọrọ ẹnu rẹ, eyi to sọ pe yoo ran iṣẹ iwadii awọn lọwọ.

Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe awọn ti n ṣe igbiyanju lati lọ wo fọnran akaalẹ inu ọgba naa, lati fi ri okodoro bi iṣẹlẹ naa ṣe bẹrẹ, ati awọn to lọwọ si i.

Abimbola wa fidi rẹ mulẹ pe iwadii awọn yoo lọ kaakiri, lati mọ kulẹkulẹ ibẹrẹpẹpẹ ati opin to fa iku awọn meji ati ẹni to farapa.