Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi àyájọ́ ọdún Sango àgbáyé tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Oyo

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lopin ọsẹ yii ni aṣekagba ayajọ ọdun Sango agbaye waye ninu gbagede Aafin alaafin ti ilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade, Elewu Ẹtu Akọkọ.

Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ti a wa yii ni eto ọhun bẹrẹ ni pẹrẹu, ti wọn si fi ori rẹ lọjọ Satide to kọja.

Ọpọ awọn aṣoju aṣa kaakiri agbaye bii Paulo Santos lati orileede Portugal, ati Felix Coastales lati orileede Spain ni wọn peju sibi eto ayẹyẹ ọdun Sango naa, to wọn si gbe oriyin fun Alaafin Oyo lori ipa ati akitiyan rẹ nipa gbigbe aṣa ati iṣẹṣe larugẹ.

Yatọ si Alaafin ti awọn aṣoju wọnyi gbe oriyin fun, wọn tun gbe oṣuba kare fun gbogbo awọn to wa nidi igbelarugẹ aṣa ati iṣẹṣe fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe.

Santos ati Coastales pe fun ifọwọsowọpọ laaarin orileede wọn ati ilẹ Naijiria ninu gbigbe aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba larugẹ.

‎Wọn ni ohun to ṣe pataki ni bi aṣa ati iṣe ma ṣe parun, nitori pe ohun ti ọpọ nigbagbọ ninu rẹ ni, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe lati kekere lo yẹ ki wọn ti maa kọ awọn ọmọ.

‎Ayajọ ọdun Sango agbaye yoo ran awọn ọdọ lọwọ

Nunu ọrọ ikinni kaabọ rẹ, Alaafin tilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade ni ayajọ ọdun Sango agbaye jẹ ayajọ ọdun ti ilu Oyo nlo lati pe akiyesi gbogbo orileede agbaye si bi aṣa Yoruba ati ilu Oyo ṣe ṣe pataki sii.‎

‎Ọba Owoade tẹsiwaju wi pẹ, ayẹyẹ yii yoo ran awọn ọdọ lọwọ ati awọn alayọ to wa sibi ayẹyẹ ọhun lati ri aṣa ati iṣẹ ile Yoruba gẹgẹ bi o ṣe yẹ.‎

‎Alaafin pe fun ifọwọsowọpọ laaarin awọn aṣoju ilu Portugal ati Spain ki ipolongo to yẹ le wa fun aṣa ati iṣẹ ile Yoruba jakejado agbaye.

Ipinle Oyo n gbiyanju ninu gbigbe aṣa ati eto igbafẹ larugẹ

Nigba toun naa n sọrọ, ‎Kọmiṣanna fọrọ eto aṣa ati irin-ajo afẹ nipinlẹ Oyo, Wasiu Olatunbosun fidi rẹ mulẹ pe ijọba n ko ipa takuntakun lati rii pe ọwọ aago ko jo ajorẹyin.

Olatunbosun ti Rotimi Babalawo, ẹni to jẹ akọwe agba fun ileeṣẹ to n ṣabojuto aṣa ati irin-ajo afẹ ṣoju rẹ sọ pe ayẹyẹ Ṣango kii ṣe tibilẹ nikan, bi ko ṣe pe o ti di ti agbaye bayii.

‎Rotimi Babalawo ni pẹlu bi ajọ agbaye, UNESCO ti ṣe buwọlu ṣiṣe ajọdun ọdun Sango agbaye, ijọba Ipinlẹ Oyo ko ni fa sẹyin lati mu idagbasoke baa awọn ẹka tọ nii sẹ pẹlu aṣa ati ohun igbafẹ nipinlẹ naa.‎

‎O wa rọ awọn ọdọ ati awọn ọmọ bibi ipinlẹ Oyo lati gbaruku ti ijọba ipinlẹ naa fun gbigbẹ aṣa ati ẹka igbafẹ ipinlẹ naa larugẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Eto ọhun lo ti bẹẹrẹ lati ọjọ kẹfa oṣu kẹjọ ọdun yii pẹlu ọpọ eto, lara awọn eto ti wọn ti ṣe ṣaaju ni ṣiṣe ayajọ ọjọ Ogun ajọbọ, eleyii ti o tun mọ si ayẹyẹ ifilọlẹ ọdun tuntun nilu Oyo ti wọn o si tun fi jijẹ iṣu tuntun.‎

‎Lẹyin eyi ni wọn lọ bọ odo Yemoja, ti wọn si da Ifa Sango ni ọjọ kẹrin.

Bibọ Aje ati Eṣu ni wọn ṣe ni ọjọ karun-un; wọn bọ Ọya ati odo Osun lọjọ kẹfa ati ọjọ keje.‎