Ṣé lóòótọ́ ni ìjọba Eko gbé owó lílẹ pátákó ìpolongo ìbò jáde ní ₦700m?

Aworan aarẹ Bola Tinubu ati Kashim Shettima
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ijọba ipinlẹ Eko ti jiyan iroyin to gba ori ayelujara pe wọn ti mu alekun9 ba iye ti awọn oloṣelu fi n lẹ patako ipolongo ibo di ẹẹdẹgbẹrin miliọnu naira (₦700m).

Kọmiṣanna feto iroyin ati ọgbọn inu ni ipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku ṣe afọmọ rẹ pe ijọba kọ lo ni awọn patako ipolongo ibo.

Eyi lo n waye lẹyin ti iroyin kan gba ori ayelujara pe ẹẹdẹgbẹrin miliọna naira ti ijọba Eko n gba lati fi patako ipolongo awọn oludije ni ko jẹ ki awọn oludije lẹgbẹ oṣelu New Democratic Congress, NDC maa lẹ patako ipolongo ibo wọn si gbogbo awọn aaye kaakiri ipinlẹ Eko.

Omotoso ninu atẹjade naa sọ afọmọ rẹ pe ijọba kọ lo n ri si ọrọ patako ipolongo ibo bikoṣe awọn ileeṣẹ to n ri si ipolowo ọja to je ti aladani, ti wọn si ni ajọ to n ri si ipolongo tijọba ipinlẹ Eko kan maa n mojuto wọn ni.

O fi kun pe ohun to da oun loju ni pe patako ipolongo to wọn julọ ni ipinlẹ Eko ko ju miliọnu mẹwaa naira lọ loṣooṣu, to si jẹ pe ijọba kii da si iye ti awọn ileeṣẹ to n ri si awọn ipolongo naa n gba.

O tẹsiwaju pe ojuṣe LASAA ko ju ki wọn ṣamojuto awọn ibi ti wọn n lẹ patako ipolongo si, ki wọn si ri daju pe wọn n tẹle ofin ati ilana to ti wa nilẹ tẹlẹ.

Kọmiṣanna naa tun ṣalaye pe ṣaaju ki ipolongo eto idibo ọdun 2027 to gberasọ ni LASAA ṣe idanilẹkọọ fawọn ẹgbẹ oṣelu, awọn oludije atawọn ileeṣẹ to n ri si ipolongo, to fi mọ awọn araalu lori awọn ilana ati ofin to de ipolongo ibo fun eto idibo.

O tẹmpẹlẹmọ pe ipinlẹ Eko ni ifarajin si pipese anfaani kan naa fawọn oloṣelu ati awọn oludije, to si rọ awọn alẹnulọrọ lati tẹle gbogbo ofin ati ilana to ba yẹ.

Elo ni awọn ipinlẹ n gba fun lilẹ atẹ ipolongo ibo?

Atẹ ipolongo ibo Atiku ati Amaechi
Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kaakiri awọn ipinlẹ ni Naijiria ni owo ti awọn oludije fun lile patako ati atẹ ipolongo wọn yatọ sira.

Ni oṣu Kẹsan-an ọdun yii ni ajọ to n mojuto eto lilẹ atẹ ipolowo ati ipolongo ni ipinlẹ Kwara iyẹn Kwara State Signage and Advertisement Agency (KWASAA) kede mimu alekun ba iye ti wọn n gba fun lilẹ atẹ ipolongo ibo fawọn oludije sipo oṣelu ṣaaju eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.

Nibi eto kan ti wọn ti pe awọn alẹnulọrọ ni ọga agba ajọ KWASAA, Toba Adeyeye kede pe alekun ti ba owo naa, ti owo naa si ti wa laaarin miliọnu meji naira ati ọgọrun-un miliọnu naira.

Adeyeye nigba to n sọrọ nibi eto naa ṣalaye pe awọn oludije sipo aarẹ maa san ọgọrun-un miliọnu naira, nigba ti awọn oludije sipo gomina maa san aadọta miliọnu naira.

Awọn oludije sipo sẹnetọ maa san ọgbọn miliọnu naira, awọn oludije sile igbimọ aṣojuṣofin maa san miliọnu mẹwaa naira, ti awọn oludije sile aṣofin ipinlẹ maa san miliọnu meji naira ti wọn ba fẹ lẹ atẹ ipolongo ibo wọn ni ipinlẹ Kwara.

O fi kun pe owo naa maa gba awọn oludije naa laaye lati lẹ posita ipolongo ibo wọn, ṣe ipolongo ni ita gbangba, lo awọn ọkọ ti wọn tẹ awọn orukọ oludije si, gbe bana sita ni gbogbo awọn aaye ti ijọba ba ti faaye gba wọn.

Ni ipinlẹ oyo ẹwẹ, ajọ to n mojuto eto lilẹ atẹ ipolowo ati ipolongo OYSAA ni aadọta miliọnu naira ni awọn oludije sipo aarẹ yoo san nigba tawọn ba n dije sipo gomina yoo maa ọgbọn miliọnu naira.

Adari ajọ naa, Oludolapo Eso-Ajanaku sọ pe awọn oludije gbọdọ san owo yii, ki wọn si gba aṣe latọdọ ijọba ki wọn to bẹrẹ si ni lẹ awọn patako ipolongo wọn.

Ni Ekiti, miliọnu marun-un naira ni awọn oludije to kopa nibi eto idibo ninu oṣu kẹfa san fun lilẹ atẹ ipolongo eto idibo wọn.

Aworan Peter Obi ati Rabiu Kwankwaso

Ki ni ero awọn onimọ lori mimu alekun ba owo atẹ ipolongo?

Nigba ti BBC News Yoruba kan si onimọ nipa ero awujọ, Nicholas Uwerunonye ni kaakiri Naijiria ni alekun owo atẹ ipolongo ibo ti waye ni awọn ipinlẹ mii bii Ekiti, Oyo, Ogun, Abia ati olu ilu Naijiria ti mu alekun ba owo ipolongo wọn.

Uwerunonye woye pe awọn ajọ yii, labẹ ofin ni anfaani lati mu alekun ba iye owo lati lẹ atẹ ipolongo ibo ni tootọ lati le mojuto bi awọn eeyan ṣe kan maa n gbe atẹ ipolowo ati ipolongo wọn sita.

O ni sibẹ, gẹgẹ bi ofin ti ajọ to n mojuto eto idibo ni Naijiria, INEC gbe kalẹ lati fi aaye gba gbogbo awọn oludije lati ṣeto ipolongo wọn pẹlu asiko ati aaye kan naa lai si idiwọ fun, o maa ṣoro fun awọn ẹgbẹ alatako lati ko owo tabua bayii sita fun awọn ajọ yii.

O sọ pe labẹ ijọba awaarawa ti Naijiria n lo, o ni kii ṣe ohun to bojumu fun ijọba lati maa lo awọn ajọ rẹ lati fi maa ni awọn ẹgbẹ alatako lara.

O tẹsiwaju pe gbigbe owo gegege bayii kalẹ fawọn oludije n mu alekun ba owo ti awọn oludije n na lori eto idibo to si le mu kawọn oludije naa ṣi iwa wu nigba ti wọn ba depo nipasẹ ọgbọn lati fi kọkọ ri owo ti wọn n lori ipolongo ibo.

Onimọ naa tun sọ pe ti a ba ṣe agbeyẹwo ofin ti INEC gbe kalẹ pe o ni gbedeke iye ti oludije kọọkan le na lori eto idibo ti iye ti wọn ba na sori ipolongo ibo le mu wọn lugbadi ofin.

Bakan naa lo rọ awọn ajọ ijọba lati maa fi awọn oludije lẹgbẹ alatako si erongba ki wọn to maa gbe ofin jade lojuna ati le faaye gba awọn oludije mii lati le kopa ninu ipolongo ibo bo ṣe yẹ.

Uwerunonye wa rọ ajọ INEC lati maa fun awọn ajọ bayii ni gbedeke iye ti wọn le maa gba lọwọ oludije kọọkan ki wọn ba a le ri ṣaridaju rẹ pe awọn oludije naa ko ṣẹ sofin.