PFIPC: Ààrẹ Tinubu jáwe gbélẹ́ ẹ fún àkọ̀wé àgbà mẹ́ta, pàṣẹ kí wọ́n fí kélé òfin gbé ẹnìkan

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti jawe gbelẹ fun awọn akọwe agba mẹta kan lori idasilẹ awọn ayeru ileeṣẹ to n ṣiṣẹ labẹ ileeṣẹ akọwe ijọba orileede Naijiria.

M.S. Danjuma, Nadungu Gagare, ati Richard P. Pheelangwah ni awọn akọwe agba mẹta naa ti Aarẹ jawe gbele ẹ fun.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti alaga ajọ to n gbogun ti iwa jibiti nilẹ Naijiria, ICPC, Ọmọwe Musa Aliyu jabọ fun aarẹ lori awọn ayederu ileeṣẹ ti wọn da silẹ lati maa fi lu jibiti.

Yatọ si awọn mẹta wọnyi, Aarẹ Tinubu tun paṣẹ pe ki ICPC lọ fi kele ofin gbe ẹnikan to n jẹ George Buchi Nwabueze lori iwa ibajẹ naa.

Alaga ajọ ICPC, Ọmọwe Aliyu lo fidi iroyin yii mulẹ fawọn akọroryin niluu Abuja lọjọ Ẹti, ọsẹ yii, lẹyin to jabọ fun aarẹ fun igbakeji lori abajade awọn iwadii wọn nipa idasilẹ awọn ayederu ileeṣẹ.

Ṣaaju ọjọ Ẹti, ni Aliyu ti kọkọ ṣe ipade pẹlu Aarẹ l'Ọjọbọ.

Aliyu sọ pe ileeṣẹ tuntun ti awọn ṣawari rẹ, lo n ṣiṣẹ labẹ lorukọ ti wọn pe ni "National Brands Development and Made-in-Nigeria Special Project Office."

A gbọ pe wọn ti mu yara fun ileeṣẹ naa layika ileeṣẹ akọwe ijọba Naijiria (OSGF), leyi to lodi si ofin idasilẹ ileeṣẹ, ti aarẹ ko si buwọ lu.

Ọmọwe Aliyu fidi rẹ mulẹ pe awọn ṣawari tuntun yii ninu iṣẹ iwadii awọn to n lọ, gẹgẹ bi Aarẹ ti ṣe paṣẹ fun wọn lati tọpinpin.

Taa ni George Buchi Nwabueze?

Alaga ICPC jẹ ko di mimọ pe ẹni to n ṣagbatẹru ileeṣẹ tuntun yii ni George Nwabueze, ẹni to n lo oniruuru inagijẹ ti awọn eeyan fi n pe e.

"Ọfiisi ayederu ileeṣẹ yii, National Brands Development and Made in Nigeria Special Project Office, ni ẹni to n jẹ George Buchi Nwabueze n ṣagbatẹru rẹ, pẹlu awọn afurasi alabaṣiṣẹpọ ni ileeṣẹ akọwe agba orileede yii, leyi to tako ofin, lai ni ibuwọlu Aarẹ ilẹ Naijiria," Ọmọwe Aliyu sọ bẹẹ.

"Alagbatẹru naa lo tun n ṣiṣẹ pẹlu oniruuru orukọ bii: George Nathan, George Nathan Nwabueze, Honourable George Buchi Nwabueze, Prince George Buchi Nwabueze ati George Nwabueze," o fi kun ọrọ rẹ.

Aliyu sọ pe ajọ ICPC fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ akọwe ijọba lati fi ẹkunrẹrẹ iroyin nipa ayederu ọfiisi naa to wa labẹ iwadii to awọn leti, ti awọn si ti fi ẹkunrẹrẹ abajade tuntun naa to aarẹ leti.

"Mo ti ṣalaye gbogbo ẹkunrẹrẹ abajade iwadii tuntun to Aarẹ leti. ICPC yoo tẹsiwaju ninu iwadii wọn gẹgẹ bo ti yẹ."

Ìgbésẹ̀ Ààrẹ

Aliyu wa fi kun ọrọ rẹ pe, lẹyin abajade tuntun yii, aarẹ ti wa paṣẹ pe ki wọn wa ẹni to n jẹ George Buchi Nwabueze ri, ki wọn si fọwọ ofin gbe e, ati pe ki awọn akọwe agba mẹta lọ rọkunle.

"Aarẹ pa awọn aṣẹ yii pe: ki a tete lọ fi kele ofin gbe Ọmọọba George Buchi Nwabueze; o kede gbele ẹ fun awọn akọwe agba mẹta wọnyi; M.S. Danjuma, Nadungu Gagare, ati Richard P. Pheelangwah," alaga ICPC sọ bẹẹ.

Idagbasoke tuntun yii lo jẹ lara iwadii to n lọ lọwọ nipa idasilẹ ayederu ileeṣẹ ti wọn pe ni Presidential Foreign Intervention Promotion Council, eyi ti Adeniyi Adeyemi n lo fun iwa jibiti, to si ti n foju ba ile-ẹjọ.