Afẹnifere figbeta pé àfikún ti ba ìjínigbé, ìpànìyàn àti ìkọlù tó ń kojú àwọn àgbẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹgbẹ Afẹnifẹre to n ri si alaafia ati gbogbo ohun to ba kan Yoruba lorilẹede Naijiria ti kede pe afikun ti ba ijinigbe, ipaniyan ati ikọlu to n koju awọn agbẹ lapa ilẹ Yoruba.

Atẹjade ti Jare Ajayi, Akọwe apapọ ẹgbẹ Afẹnifẹre fi ṣọwọ si BBC News Yoruba lọjọ Ẹti lo fidi eyi mulẹ.

Afẹnifẹrẹ sọ pe ikọlu ti ko figba kan duro tẹlẹ ti wa n le si i lori awọn agbẹ bayii, wọn ni bi wọn ṣe n kọlu wọn ni wọn n ji awon agbẹ gbe ti wọn si n pa awọn mi-in patapata.

Díẹ lara iku ati ijinigbe to n ṣẹlẹ sawọn agbẹ l'Ondo, Oyo atawọn ibomiran nilẹẹ Yoruba

Nigba ti wọn n ṣalaye nipa awọn iṣẹlẹ to mu iku ati ijinigbe awọn agbẹ dani laipẹ yii, Afẹnifẹre ninu atẹjade naa sọ nipa agbẹ obinrin kan ti wọn pa nipinlẹ Ondo.

"Bakan naa ni wọn ji agbẹ oninnkan ọsin, Ọgbẹni Ooreoluwa Osonuga, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33) gbe lọ niluu Ikenne, ipinlẹ Ogun.

"Iku tun kan awọn agbẹ mẹrin kan lagbegbe Okeogun, nipinlẹ Oyo. Bẹẹ ni wọn ji Ọnarebu Debo Farounbi gbe lọ niluu Ora, ipinlẹ Osun.''

Ẹgbẹ Afẹnifẹre fi kun un pe awọn to ji Farounbi gbe lati ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹfa ọdun 2026 ti kọ lati da a silẹ, pẹlu bi wọn ṣe ti gba miliọnu lọna ọgbọn naira lọwọ awọn ẹbi rẹ gẹgẹ bi awọn ẹka kan ṣe sọ.

Koda, kaka ki wọn yọnda Ọnarebu Farounbi, wọn tun n beere afikun owo ati alupupu ni!

Ọpọ iru awọn iṣẹlẹ yii ni Afenifere kede pe o tun n ṣẹlẹ nilẹẹ Yoruba, amọ ti ko de etigbọọ awọn eeyan nitori iroyin ko gbe e.

''Ọpọ agbẹ lo ti pa oko wọn ti bayii nitori ibẹru ijinigbe ati iṣekupani''

Atẹjade awọn Afẹnifẹre ṣalaye pe loṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, ẹgbẹ awọn agbẹ ti a mọ si "All Farmers Association of Nigeria (AFAN), kede pe jiji awọn agbẹ gbe leralera pẹlu awọn to n ba wọn ṣiṣẹ ti ko ba iṣẹ oko ṣiṣe.

Wọn ni awọn eeyan to n kowo le nnkan ọgbin niluu Eko, Ogun, Oyo, Osun, Ekiti ati Ondo ti ko aarẹ ọkan lori okoowo naa, eyi si n sẹ akoba fun iṣẹ oko ṣiṣe.

Bakan naa lo ti mu adinku ba ire oko ati ọna atijẹ awọn idile agbẹ.

"Ọpọ agbẹ lo ti pa oko wọn ti nitori ibẹru ijinigbe, ibẹru owo nla ti ajinigbe n beere ki wọn too tu ẹni ti wọn na ji gbe silẹ, ati ibẹru ikọlu to kun fun ipanilara."

Bẹẹ ni ẹgbẹ naa wi.

Nnkan mẹta ti Agbẹnusọ Afenifere sọ pe o n ba awọn agbẹ lẹru lagbegbe Oke Ogun ati Ondo ni:

"Ijinigbe, ai le ta ire oko bo ṣe wu wọn nitori awon onibaranda, ati ibẹru awọn to n fi ẹran jẹko oloko bo tilẹ jẹ pe wọn ti kilọ fun wọn titi amọ ti wọn ko dahun."

Iwadii fi han pe awọn ajọ agbaye bii United Nations Food and Agriculture Organization (FAO), Banki Agbaye atawọn mi-in ti ri ọṣẹ́ ti aisi aabo n ṣe fun ipese nnkan oko nilẹẹ Yoruba.

Ewu to n bẹ ninu ai le ṣiṣẹ oko fawọn agbẹ

Adinku yoo ba ipese ohun jijẹ

Owo rẹ yoo wọn si i lọja

Airiṣẹ ṣe fawọn agbẹ atawọn to n ba wọn ṣiṣe oko.

Akoba ni fawọn olokowo ounjẹ.

Alekun le ba iwa ọdaran latari airiṣẹ ṣe mọ.

Ìṣẹ́ ati òṣì le maa peleke si i.

Ọna abayọ ti Afẹnifẹre la kalẹ

Afẹnifẹre gboriyin fun Aarẹ Tinubu lori aṣẹ tuntun to pa pe ki wọn ṣe iwadii kikun lori awọn ohun to n dunkooko mawọn eeyan lorilẹede yii ati idena rẹ.

Wọn rọ awọn gomina ipinlẹ Yoruba mẹfẹẹfa lati koju awọn iṣoro yii pẹlu.

Ṣaaju igba ti ọlọpaa ibilẹ yoo gberasọ ni Naijiria, Afẹnifẹrẹ la awọn ọna wọnyi kalẹ bii ohun ti ijọba le ṣe:

  • Riro ikọ Amọtẹkun lagbara nipa afikun ikọ naa, ipese awọn irinṣẹ ibaraẹnisọrọ igbalode, ipese ọkọ ti wọn yoo fi maa wọde.
  • Ṣiṣe ofin to de ifẹranjẹko, dida ikọ ti yoo maa fọ awọn igbo didi tawọn ọdaran n lo kiri, ki awọn ọdẹ ibilẹ atawọn fijilante maa ṣiṣẹ pọ, ki wọn si ṣe agbekalẹ ibujẹ ẹran igbalode.
  • Bakan naa ni Afẹnifẹre rọ ijọba lati ṣe ibudo tawọn ẹṣọ alaabo yoo ti maa yẹ awọn awọn to ba n wọle lawọn ẹnu abawọle ipinlẹ ti ewu n bẹ lorii wọn, paapaa awọn ikọ adihamọra ogun.
  • "Ki wọn maa dina mọ awọn to ba n gun ọkada pupọ wọle, paapaa bi wọn ba ti dihamọra ogun."Bẹẹ ni atẹjade naa wi.