You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
₦800,000 ni mo fi ń ra oògùn lásìkò tí mo ń ṣàìsàn – Ronke Oshodi Oke
Gbajugbaja oṣere tiata, Ronke 'Oshodi Oke' Ojo, ti sọrọ soke lori ohun to la kọja lasiko to n ṣaisan.
Oṣere naa ni owo ti iye rẹ to ₦800,000 loun n na loṣoṣu lati ra ooogun lasiko naa.
Gbajumọ oṣere naa lo sọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle African A List, nibi to ti ṣalaye pe awọn akẹgbẹ oun ati alaga ẹgbẹ awọn awakọ, MC Oluomo lo dide iranlọwọ fun oun.
Lasiko to n sọrọ nipa iye to n na lori oogun loṣoṣu, o ni owo naa pọ jọjọ.
O ni "Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o jẹ Ọlọrun, mo tun dupẹ lọwọ MC Oluomo atawọn akẹgbẹ mi ti wọn jẹ ki wa laaye lonii yii.
"Ṣe ẹ mọ nnkan to n tumọ si ki eeyan maa fi ₦800,000 ra oogun lọṣoṣu?"
"Sotaya Gaga fi owo ranṣẹ si mi ṣugbọn a kii sọrọ"
Ronke tun mẹnuba ibaṣepọ rẹ pẹlu oṣelẹ mii, Tayo Sobola ti inagijẹ rẹ n jẹ Sotayo Gaga.
O ṣalaye pe gbajumọ oṣere naa fi owo ranṣẹ si ooun lasiko ti oun dubulẹ aisan bo tilẹ jẹ pe ibasẹpọ awọn mejeji ko duro dede.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ₦150,000 ni Sotayo fi ranṣẹ si oun amọ awọn mejeji ko tii ba ara wọn sọrọ lati nnkan bii ọdu mẹfa ṣeyin.
O ni "Emi ati Sotayo ko tii sọrọ fun ọjọ pipẹ, kii ṣe pe a n ja o, amọ a ni ariyanjiyan kekere kan ni.
"Nnkan bii ọdun marun un tabi mẹfa sẹyin ni a sọrọ kẹyi. Ṣugbọn nigba to gbọ pe mo n ṣaisan, o fi ₦150,000 ranṣẹ si mi."
Nigba ti wọn bere lọwọ rẹ boya Sotayo ti pe e lẹyin naa, Ronke sọ pe awọn mejeji kii sọrọ ni gbogbo igab ti wọn ba pade ara wọn, niṣe ni wọn kan maa n gba ẹgbẹ ara wọn kọja.
O ṣalaye pe asiko ti oun n ṣaisan naa loun darapọ mọ ijọ CCC alasọ funfun.
Ronke fidi rẹ mulẹ pe oun kii ṣe idẹyẹsi ẹsin to yatọ si ẹsin oun.