Russia ṣekúpa èèyàn mẹ́jọ ní Ukraine, àwọn mọ́kàndínlógójì farapa

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ọmọ ogun orileede Russia la gbọ pe wọn tun ti ju ado oloro saarin gbungbun ọja ilẹ Ukraine, nibi ti ọpọ awọn eeyan ti farapa, ti awọn mẹ́jọ si gbagbẹ ku.

Ilu Kryvyi Rih lorileede Ukraine ni ado oloro ọhun ti ṣọṣẹ lọganjọ oru, lasiko ti awọn eeyan ti sun lọ fọnfọn, ti awọn miran si n ṣiṣẹ oojọ wọn lọwọ.

Awọn alakoso ilẹ Russia ti wa fidi rẹ mulẹ agbegbe ti ado oloro naa ti dun, ni wọn ti n ṣe awọn eroja ohun elo oju ogun loriṣiriṣi.

Ileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ Ukraine ti jẹ ko di mimọ pe iṣẹ ti duro lawọn agbegbe ti ikọlu ọhun ti n waye, lati le daabo bo awọn eeyan kuro lọwọ iku.

Aarẹ ilẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky ti fidi rẹ mulẹ pe iṣẹ ti n lọ lati rii pe wọn dawọ gbogbo ikọlu ọhun duro laipẹ, pẹlu bo ṣe pe awọn wa lori iṣẹ.

Ṣugbọn ṣa, Andrey Vorobyov to jẹ gomina ẹkun Moscow sọ pe ikọlu to waye lagbegbe naa lo jẹ eyi to lagbara ju, ninu eyi to ti ṣẹlẹ loṣu diẹ sẹyin.