Halimat Tejuosho: Bọ̀rọ̀kìnní obìnrin tó kó sí gbaga EFCC lórí ẹ̀sùn jìbìtì ₦603m, ohun tó mú City boy Movement kébòsí lóríi rẹ̀

Aworan gbajumọ naa ninu aṣọ dudu ati iboju, aworan idanimọ EFCC wa laarin.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Obinrin gbajumọ kan, Halimat Tejuosho ti kawọ pọn rojọ niwaju adajọ ile ẹjọ giga to wa ni Gwagwalada, niluu Abuja, lori ẹsun lilu jibiti owo ti iye rẹ le ni ₦603m.

EFCC to fẹsun kan obinrin naa sọ pe afurasi ọhun ṣeleri fun obinrin kan pe oun yoo ṣamọna bi yoo ṣe di ọga agba ileeṣẹ ijọba, Nigerian National Petroleum Corporation, NNPCL.

Ẹsun marun un ọtọtọ ni wọn fi kan Tejuosho, eyii to da lori lilu jibiti, fifi ọna eburu gba owo lọwọ eeyan ati iwa ọdaran.

EFFC lo kede igbẹjọ naa loju opo X rẹ.

Yatọ si Tejuosho, ẹlomii to tun n jẹjọ pẹlu rẹ ni Gidado Ibrahim ti wọn jọ gba owo lọwọ naa lọwọ Oluseye Yomi-Sholoye laarin oṣu Kẹjọ si oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 lẹyin ileri pe awọn yoo sọ ọ di GMD ajọ NNPCL.

EFCC tun fẹsun kan Tejuosho pe o gba ₦259.9m ati ₦50m, yatọ si awọn owo mii sinu apo banki to jẹ tirẹ ati ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Haleems Integrated Services Limited.

Mi o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan - Tejuosho

Nigba ti wọn ka ẹsun rẹ fun, o ni oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ọhun.

Lẹyin naa ni agbẹjọro rẹ, Chuks Ugwuru, bẹ ile ẹjọ ki wọn fun ni beeli nitori gbogbo ẹsun mararun ti wọn fi kan an lo ni beeli.

Agbẹjọro naa ni oun bere fun beeli ọhun latari ipo ilera afurasi, o tun mẹnuba esi ayẹwo lati fidi rẹ mulẹ pe obinrin naa ko gbadun.

Amọ agbẹjọro ikọ olupẹjọ, Yahaya Tarfa, kọ jale pẹlu ọpọlọpọ alaye.

Lẹyinorẹyin, adajọ Adepoju sọ pe ẹsun ti wọn fi kan an jẹ eyii ti wọn le gba beeli rẹ, o si fun ni beeli pẹlu ọgọrun miliọnu naira.

O ni ki afurasni fa iwe irinna rẹ le ile ẹjọ lọwọ titi ti ẹjọ naa yoo fi pari.

Adajọ tun fi kun pe afurasi gbọdọ pese oniduro ti yoo maa gbe lagbegbe ti ile ẹjọ naa wa.

Lẹyin naa lo sun ẹjọ ọhun si ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2027.

Ko si ibaṣepọ kankan laarin awa ati afurasi – City Boy Movement

Ẹgbẹ Citiy Boy Movement to n ṣe ipolongo ibo saa keji fun Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe ko si ibaṣepọ kankan laarin awọn ati afurasi naa, fun idi eyii, ki awọn araalu dẹkun ati maa ko wọn pọ.

Ṣaaju asiko yii ni obinrin naa ti jẹ adari ẹka ẹgbẹ naa ni Guusu-iwọ-oorun Naijiria ki wọn to jawe lọ we lọ rọọkun nile fun.

Ọrọ tuntun ti Citiy Boy Movement sọ yii lo n waye lẹyin ti obinrin naa dero ile ẹjọ lori jibiti ti won fẹsun rẹ kan an.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ẹgbẹ ọhun, Arabinrin Aderonke fi lede, o ni Tejuosho kii ṣe ọmọ ẹgbẹ naa tabi aṣoju rẹ, bẹẹ ni ko ni ibaṣepọ kankan pẹlu awọn adari rẹ.

Ẹgbẹ naa juwe ara rẹ gẹgẹ bii ẹgbẹ awọn eeyan iyi ti ọwọ wọn si mọ.

Citiy Boy Movement wa kilọ fun awọn akọroyin ki wọn dẹkun a ti maa so afurasi naa poọ mọ ẹgbẹ awọn.