Èmi nìkan ni mà á fi òótọ́ inú ṣèjọbà bí mo bá di gómìnà Kwara nítorí mi ò ní bàbá ìsàlẹ̀ - Zakari Muhammed, olùdíje ADC

Oludije sipo gomina ipinlẹ Kwara lẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC Họnọrebu Zakari Muhammed ti ni oun ni ọkọ to le gbe ipinlẹ naa de ebute ogo.
Zakari Muhammed sọ eyi nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori erongba rẹ lati di gomina nibi eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.
O ni ẹgbẹ oṣelu ADC nikan ni ẹgbẹ ti ko ni baba isalẹ to maa fi ootọ inu ṣe ijọba bi wọn ba ni anfaani lati depo nitori awọn to ni baba isalẹ yoo maa ṣiṣẹ ọga wọn bi wọn ba e ipo naa ni dipo sinsin araalu.
"Bi oludije lẹgbẹ oṣelu APC ẹni to ba wa n bẹ bo ba wọle iṣẹ ọga ẹ la a ṣe bẹẹ naa lo ri fun oludije lẹgbẹ oṣelu PDP. Awa o lọga kankan.
"Mo ti ṣẹgbẹ PDP, APC, mo mọ nnkan ti ko jẹ ki nnkan ṣẹlẹ ni APC, mo mọ nnkan ti ko jẹ ki nnkan dun ni PDP, gbogbo atunṣe yẹn lo wa ni ADC."
"Bi ẹ ba sọrọ PDP ẹ mọ ẹni to jẹ ọga PDP ni Kwara, ẹ mọ ẹni ti n jẹ ọga APC ni Kwara, ta lọga ADC?"
O fi kun pe oun ti ṣẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ri eyi to ti fun oun ni iriri nipa awọn ẹgbẹ oṣelu naa to si ṣalaye pe gbogbo awọn kudiẹkudiẹ to waye ninu awọn ẹgbẹ naa lo mu oun lọ darapọ mọ ADC.
O sọ pe gbogbo awọn aikaju oṣuwọn ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ni awọn fẹ ṣe atunṣe si ninu ẹgbe oṣelu ADC.
"Awa yii a ṣẹgbẹ PDP, a ṣẹgbẹ APC, ọpọlọpọ wa a mọ nnkan ti ko jẹ ki nnkan ṣẹlẹ ni APC, a mọ nnkan ti ko jẹ ki nnkan dun ni PDP, gbogbo atunṣe yẹn lo wa ni ADC."
Nigba to n sọrọ lori ẹsun ta wọn kan fi n kan-an pe niṣe ni awọn kan fi di gẹrẹu ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, pe ẹgbẹ oṣelu mii gangan lo n ṣiṣẹ fun, Zakari Muhammed sọ pe oun kii ṣed ọmọ ale, pe ọmọ ale ni o le iru nnkan bẹẹ.
O ni loootọ ni oun ṣe Kọmiṣanna ati SA fun Bukola Saraki nigba to wa nipo gomina, o ni oun ko ri nnkan to buru nibẹ ti oun ba kuro lẹyin lati lọ da duro toun.
O ṣalaye pe oun wa gomina nitori oun ni gbogbo amuyẹ lati di gomina ati pe gbogbo awọn oludije to ku ko da oun.
"Gomina yii emi o wa fun, n di gẹrẹwu kankan o, emi n wa gomina na pe mo fẹ di gomina ipinlẹ Kwara nitori awọn to n wa ko da to mi.
"Wọn o jafafa to mi, wọn o lọ ile ẹkọ ju mi lọ, wọn o ni iriri ju mi lọ. Ẹ ṣi a wo, ẹni ki wọn gbe akọọlẹ ohun ti wọn ti ṣe wa ki emi naa gbe temi wa ka jọ wo o."
"Emi n wa gomina Kwara ni ọda Ọlọrun atawọn eeyan Kwara bi n ba debẹ a a dẹ ṣe nnkan lọtun."
"Ṣiṣe olori lori awọn eeyan mẹtalelogun ko tumọ si pe o ni iriri lati fi gomina lori eeyan miliọnu mẹta"
Zakari Muhammed tun sọrọ lori oludije gomina lẹgbẹ oṣelu APC, Salihu Yakubu Danladi to ni oun ni oun ni iriri julọ ninu awọn to n dije sipo gomina ni Kwara, Muhammed ni olori ile aṣofin naa ko ni iriri to kaju ẹ to bẹẹ lati fi tukọ ipinlẹ Kwara.
O woye pe ṣiṣe gomina le awọn eeyan ti iye wọn le ni miliọnu mẹta kọja ṣiṣe olori le awọn eeyan mẹtalelogun eyi ti olori ile naa fi n yangan.
"Ẹnikan șo pe tori oun ṣe olori ile aṣofin, pe awọn ọmọ igbimọ mẹtalelogun, meloo niyẹn ko to igbimọ alabẹṣekele nibi kan.
Ki ni o n jẹ iriri? Gomina la pe e, lori eeyan to le ni miliọnu mẹta, bi eeyan miliọnu mẹta la n sọ kii ṣọrọ eeyan mẹtalelogun, rara, a n sọrọ nipa ọlaju, a n sọrọ nipa iriri.
"Bi ẹ ba fẹ tun ọkọ yin, ẹ fẹ ki ọkọ yin dele, ẹ ma fun ẹni to ṣẹṣẹ n kọ ọkọ wa ni mọto o, eeyan lọ ra Royce Rols ẹ wa lọ ko ẹni to ṣẹṣẹ n kọ ọkọ wa sidi ẹ, a jaamu ni."

























