You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé rèé lórí ohun tí Ademola Adeleke lọ ṣe lọ́dọ Tinubu àti Wike ní Abuja
L'Ọjọbọ, ọsẹ yii ni Gomina Ademola Adeleke tipinlẹ Osun ṣabẹwo si aarẹ ilẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu nile agbara, Aso Rock to wa niluu Abuja.
Adeleke lo lọ ṣabẹwo naa pẹlu ikọ akọwọrin rẹ, lati fi imọriri han lori aṣeyọri to ṣe nibi eto idibo gomina to waye nipinlẹ Osun lopin ọsẹ to kọja.
Deedee agogo marun-un kọja iṣẹju marundinlọgbọn irọlẹ ni Adeleke wọnu ọgba Aso Rock na pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Land Cruiser SUV rẹ.
Lara awọn to kọwọrin pẹlu Adeleke ni oludamọran pataki lori ọrọ eto aabo, Nuhu Ribadu; alakoso igbimọ iṣakopso ipolongo rẹ, Sẹnetọ Lere Oyewumi; Ọgbẹni Sunday Bisi; olori awọn oṣiṣẹ gomina, Akinleye Kazeem ati ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun, Bamidele Salam.
Kete ti Adeleke ti wọnu Aso Rock, lo ti gba ọdọ Aarẹ Tinubu lọ lati ṣepade idakọnkọ, ppaa lati dupẹ fun bo ṣe faaye gba alaafia lasiko idibo to gbe e wọle fun saa keji.
Nibẹ ni Adeleke ti fi iwe-ẹri ti ajọ eleto idibo, INEC gbe fun un l'Ọjọru, ọsẹ yii niluu Osogbo, to si fi han Aarẹ lati ri.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Adeleke bori idibo gomina ipinlẹ Osun to waye lọjọ Satide, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ pẹlu ibo to le ni idaji miliọnu kan (511,067), to si bori awọn akẹgbẹ rẹ bii Bola Oyebamiji tẹgbẹ oṣelu APC toun ni ibo to le ni ẹgbẹrun lọna irinwo (444,815)
Ijọba ibilẹ mọkandinlogun ni Adeleke ti bori, nigba ti ẹni to tẹle e, Oyebamiji bori lawọn ijọba ibilẹ mọkanla, gẹgẹ bi ajọ INEC ṣe kede.
Kí ni Ààrẹ Tinubu sọ?
Tinubu, nigba to n sọrọ, gbe oṣuba kare fun Gomina Adeleke lori akitiyan rẹ lati awe olubori, to si ni aṣeyọri naa lo ṣafihan ifẹ ọkan awọn araalu.
Aarẹ sọ pe aṣeyọri Adeleke fidi rẹ mulẹ pe eto oṣelu awa-ara-wa yoo tẹsiwaju lati maa goke agba nilẹ Naijiria lojoojumọ.
O wa rọ Gomina Adeleke lati jẹ ki awọn ara ipinlẹ Osun w ani iṣọkan, lai nii ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu yoowu ti wọn wa, ko si gbajumọ iṣẹ idagbasoke ilu ati iduroṣinṣin eto ọrọ aje.
Adeleke ṣàbẹ̀wò sí Wike
Bakan naa ni Gomina Ademola Adeleke tun ṣabẹwo si minisita fọrọ FCT, Nyesom Wike lẹyin to kuro lọdọ Aarẹ.
Akọwe iroyin Wike, Lere Olayinka lo gbe awọn aworan abẹwo naa soju opo ayelujara rẹ, lati fi to gbogbo awọn eeyan leti.
Olayinka jẹ ko di mimọ pe Adeleke lọ ṣafihan iwe-ẹri rẹ pẹlu Wike, lẹyin to kuro lọdọ Aarẹ Tinubu