Ẹ wo bí àwọn Òyìnbó ṣe ń gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá lárugẹ ní orílẹ̀-èdè Brazil

Yoruba lo lede, Yoruba lo ni aṣa ati iṣe, awọn alawọ funfun gan an ree ti wọn tẹwọ gba aṣa ati iṣe Yoruba lorilẹede Brazil.
Ninu ifọrọwanilenu ti BBC News Yoruba ṣe fun adele aṣoju ijọba orilẹede Brazil ni Naijiria lọdun 2019 niluu Eko, Helgies Bandeira, ni o ti ṣalaye bawọn ẹya mii ṣe tẹwọ gba aṣa Yoruba nilẹ okeere.
Lasiko ti adele aṣoju orilẹ-ede Brazil ni Naijiria nigba kan ri naa gba BBC Yoruba lalejo ninu ọgba ileeṣẹ Brazil niluu Eko ni o sọ pe awọn oriṣa Brazil ló ni akara.
O ṣalaye kikun nipa ijọra awọn aṣa Yoruba ati ti orilẹ-ede Brazil.
Helgies ni awọn ti Brazil maa n ro pe aṣa Yoruba ni aṣa ti wọn naa ni.
O ni awọn naa n sin oriṣa bii Ogun, Ọṣun, Ọbatala, Yemoja atawọn mii.
Bakan naa ni Helgies tun sọrọ lori ounjẹ bii akara to jẹ tawọn oriṣa ati akarajẹ to jẹ eyi tawọn eniyan maa n jẹ ni Brazil.
Opọ ọmọ Yoruba ni wọn ko lọ si orilẹ-ede Brazil nipasẹ owo ẹru laye atijọ, eyi ti ọpọ si ti di ero Brazil lati atọmọdọmọ wọn.
Bandeira sọ pe ''wọn ko awọn Yoruba lọ soke okun lasiko owo ẹru, bakan naa ni Yoruba wa ni orilẹede Brazil.
Awọn eeyan kan maa n pe mi ni Oyinbo Yoruba, emi naa si maa n fesi wi pe bo ti ri niyẹn.
Awa naa mọ nipa awọn oriṣa ilẹ Yoruba bii Ogun, Osun, Obatala, Yemoja, gbogbo rẹ lo wa lara aṣa tiwa naa ni Brazil.
Idi niyii ti o fi rọrun fun ọpọ ọmọ orilẹede Brazil lati gbe niluu Eko lai si iyọnu kankan.
O maa n da bi ẹni pe ile ni a wa nigba ti a ba wa niluu Eko ni Naijiria.''
Adele aṣoju ijọba Brazil ni Naijiria tẹlẹri fikun ọrọ rẹ pe ọpọ eeyan lo maa n sọ ede Yoruba ni Brazil.
Bandeira tun sọ pe ''lọpọ igba ni mo maa n wọ aṣọ Yoruba niluu Eko, eyi lo jẹ ki ọpọ eeyan maa pe ni Oyinbo Yoruba.
Bakan naa ni aṣọ Yoruba tun gbajumọ lorilẹede Brazil papaa julọ nipinlẹ Bahia.






