, Ìbò kíkà ti bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ibùdó ìdìbò kọ̀ọ̀kan nípìnlẹ̀ Osun
Ibo kika ti gbera sọ lawọn ibudo ibudo kan bayii.
Fun apẹẹrẹ, ni wọọdu ti Gomina Adeleke ti dibo niluu Ede, ibo kika ti bẹrẹ.
You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìròyìn àtìgbàdégbà nípa ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun
Ibo kika ti gbera sọ lawọn ibudo ibudo kan bayii.
Fun apẹẹrẹ, ni wọọdu ti Gomina Adeleke ti dibo niluu Ede, ibo kika ti bẹrẹ.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ibo ti pari ni awon apa ibi kan ninu idibo sipo gomina to waye lonii ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ ọdun 2026.
Awọn kan ti dibo tan lawọn apa ibi kan niluu Ede ati Ejigbo, amọ awọn kan ṣi n dibo lọwọ l’Osogbo.
Awọn ti wọn ti kadii eto idibo wọn nilẹ naa ni awọn ti wọn tete bẹrẹ.
Bakan naa ni a si ri awọn ti wọn ṣi n dibo lọwọ, latari ai tete bẹrẹ ibo.
Aago kan ọsan tilẹ ti lu kawọn kan too bẹrẹ ibo didi, wọn si wa lẹnu rẹ ta a fi pari iroyin yii.
Ni wọọdu idibo ti Gomina Ademola Adeleke ti dibo, awọn eeyan to ṣi wa lori ila lati dibo nigba ti a n kọ iroyin yii jẹ mejilelọgọrun-un (102), ti wọn ti gba nọmba lati tẹka amọ ti ko ti i kan wọn.
Ohun miran to tun mu idibo pẹ ni pe ọpọ eeyan jade dibo, bo ṣe jẹ pe aago meji ọsan ni awọn eleto idibo kede pe ibo didi yoo pari to, awọn eeyan to n tu yaaya jade ko jẹ.
Bakan naa si ni awọn kan ko tete ri orukọ wọn lati le dibo.
Awọn janduku oloselu da eto idibo ru ni ibudo ìdìbò oludije sipo gomina f'ẹgbẹ ADC nílùú Ejigbo nipinlẹ Osun.
A gbọ pé ṣadeedee lawọn janduku ọhun yabo Ibudo idibo naa ti won si da gbogbo naa ru.
Bayii ni gbogbo eeyan f'ẹsẹ fẹ ẹ.
Amọ, a gbọ pe àjọ NSCDC to jẹ ẹṣọ aabo ara ẹni ni aabo ilu petu si aawọ naa.
Oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu ADC, Najeem Salaam, ti sọ pe eto idibo ki i ṣe ogun jija.
Họnarebu Salaam sọrọ yii lẹyin ti o dibo tan ni wọọdu rẹ niluu Ikire.
Oludije fẹbẹ ADC ni eto idibo jẹ anfaani lati yan awọn adari ti yoo maa ṣakoso ilu.
Bakan naa lo tun ni oun gbọ pe awọn oloṣelu kan ṣe kata-kara ibo ninu eto idibo to waye l’Osun lonii.
Ṣugbọn o fọwọ sọya pe ẹgbẹ oun ADC ko si ninu awọn to ṣe bẹẹ.
Oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu APC, Bola Oyebamiji, ti sọ pe o da oun loju pe oun yoo bori ninu eto idibo gomina ipinlẹ Osun oni.
Oyebamiji sọrọ yii fawọn akọroyin lẹyin to dibo tan ni wọọdu rẹ
Eto idibo n tẹsiwaju kaakiri ipinlẹ Osun to fi mọ wọọdu 10, Unit 13 niluu Osogbo ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Osun.
Awọn eeyan tu yaya jade lati dibo ni wọọdu naa.
Gomina ipinlẹ Osun Ademola Adeleke ti dibo rẹ niluu Ede lati dibo.
Gomina tete jade lati dibo ni kete ti eto idibo naa bẹrẹ
A o maa mu bi o ṣe n lọ wa fun yin lori ikanni BBC News Yoruba
Oni ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ni eto idibo gomina ipinlẹ Osun yoo waye.
Gbogbo eto lo ti to bayii fun eto idibo naa lati gberasọ.
Ṣaaju ni ajọ eleto idibo INEC ṣalaye oludibo to din diẹ ni miliọnu meji (1.9m) ni yoo kopa ninu eto idibo naa.
Lara awọn oludije ni Gomina Admola Adeleke ti ẹgbẹ oṣele Accord, Bola Oyebamiji ẹgbẹ APC ati Najeem Salaam ti ẹgbẹ ADC wa.
A o maa mu bi o ṣe n lọ wa fun yin loju opo wa yii.