Gbogbo ìpínlẹ̀ ní Nàíjíríà buwólu ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀

Awọ ọlọpaa to gbe ibọn dani lasiko idanilẹkọọ ati idanrawo
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ile igbimọ aṣofin Naijiria ti sọ pe gbogbo awọn ipinlẹ mẹrindinlọgbọn to wa ni Naijiria ni wọn ti buwọlu idasilẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ, lojuna lati jẹ ki eto aabo tubọ munadoko.

Bakan naa ni ile igbimọ aṣofin agba Naijiria buwọlu iwe ofin idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, pẹlu esi lati ọdọ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati fontẹ lu.

Kamoru Ogunlana to jẹ alakoso ile inu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, fidi rẹ mulẹ pe nipa ajọṣepọ to dan mọnra ni aba naa fi wa si imuṣẹ.

Ogunlana sọ pe bi gbogbo ipinlẹ mẹrindinlọgbọn naa ṣe buwọ lu idasilẹ yii, ti jẹ ki aridaju wa pe gbogbo Naijiria lo buwọ lu idasilẹ naa, ati pe idasilẹ naa lọ ni ibamu pẹlu iwe ofin to sọ pe o kere tan, ipinlẹ mẹrinlelogun gbọdọ buwọ lu aba, ko to di pe wọn fontẹ lu.

Kí nìdí táwọn ìpínlẹ̀ kan kò ṣe tìí fèsì wọn ṣọwọ́ lórí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀?

Awọn ọlọpaa Naijiria lẹnu iṣẹ

Lọna ati yanju eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria, ẹkọ ti n fi oju mimu han lori ọrọ ọlọpaa ipinlẹ ti ijọba apapọ fẹ da silẹ lẹyin atunṣe ofin to n lọ lọwọ.

Gẹgẹ bii ofin ṣe laa kalẹ, awọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ni Naijiria gbọdọ fontẹ lu igbesẹ naa, lẹyin naa ni ile igbimọ aṣofin agba yoo fontẹ lu u ki Aarẹ to fọwọ si.

Amọ ṣa, bo tilẹ jẹ pe ọpọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ bii mejilelọgbọn lo ti buwọlu idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, ipinlẹ mẹrin ọtọọtọ ni ile igbimọ aṣofin wọn ko sọ ipo ti awọn wa lori ọrọ naa.

Eyii lo mu ki ile igbimọ aṣofin agba kede gbedeke ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii fun awọn ile aṣofin ipinlẹ naa ki wọn fi iroyin ibi ti wọn ba iṣẹ de duro ṣọwọ si oun.

Opeyemi Bamidele to jẹ ọkan lara awọn olori ile naa sọ pe ile aṣofin agba ọhun yoo tẹsiwaju pẹlu atunṣe ofin idasilẹ ipinlẹ naa lai naani awọn ipinlẹ ti ko tii sọ ipo ti wọn wa.

Igbesẹ ati ṣe atunṣe ofin naa lo n waye latari awọn kudiẹdkudiẹ to ẹka eto aabo Naijiria lasiko yii.

Lọjọ kẹrin oṣu Kọkanla ni Bamidele kọkọ sọ pe ipinlẹ ọgbọn ni wọn ti fi ọrọ ṣọwọ sile aṣofin agba pe awọn fọwọ si ko to sọ pe wọn ti pe mejilelọgbọn lọjọ Aiku, ọjọ karindunlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 yii.

Ki ni eredi ti awọn ipinlẹ mẹrin ko ṣe tii fi ohun raasẹ sile aṣofin agba?

Awọn ọlọpaa
Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lakọkọ, gbogbo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ lo ti jiroro lori ọrọ ọlọpaa ipinlẹ naa ti wọn si ti mọ igbesẹ ti wọn fẹ gbe lori rẹ amọ kii ṣe gbogbo wọn lo tii ranṣẹ sile aṣofin agba.

Nitori pe awọn ipinlẹ kan ko tii fi ohun ranṣẹ sile aṣofin ko tumọ si pe wọn ko tii sẹ nnkankan nipa rẹ.

Gẹgẹ bii awọn onimọ ṣe sọ, eredi kan gboogi ti awọn kan ko ṣe fẹ faramọ ọlọpaa ipinlẹ ni lilo awọn ọlọpaa naa lati gbogun ti awọn alatako wọn ninu oṣelu.

Ti ẹ ko ba gbage, labẹ alakalẹ idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, gomina ni yoo yan kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ rẹ bo tilẹ jẹ pe ile aṣofin ipinlẹ ọhun gbọdọ buwọlu u.

Awọn ti wọn n tako ọlọpaa ipinlẹ sọ pe agbara gomina lati yan kọmiṣọna ọhun le fun irufẹ gomina bẹẹ lagbara lori kọmiṣọna naa.

Ni ti eto iṣuna, obitibiti owo ni ijọba ipinlẹ yoo na lori ọlọpaa ipinlẹ naa, lara irufẹ owo ọhun ni owo ti wọn yoo fi ra ọkọ, idanilẹkọọ awọn ẹṣọ atawọn inawo mii.

Fun awọn ipinlẹ ti owo wọn ko to nnkan kan, yoo ṣoro diẹ fun wọn lati gbe bukata ọlọpaa ipinlẹ.

Nnkan mii ti awọn eeyan tun n sọ ni iwa ipa ọlọpaa si awọn araalu.

Wọn ni o ṣeeṣe ki titẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ tunbọ buru si ti ọlọpaa ipinlẹ ba bẹrẹ iṣẹ.

Lọna mii ẹwẹ, bawo ni ipinlẹ yoo ṣe maa fiya jẹ ọlọpaa to ba taṣẹ agẹrẹ tabi fiya jẹ araalu lọna ti ko tọ gẹgẹ bo ṣe wa lode oni yii?

Wayi o, ko si ẹri maa jẹ mi rinṣo to fi han pe awọn idi wọnyii lawọn ipinlẹ mẹrin to ku ko ṣe tii ranṣẹ sile aṣofin agba lori ọrọ ọhun.

Ki ni yoo ṣẹlẹ bayii ti gbogbo ipinlẹ Naijiria ko tii buwọlu atunṣe ofin naa?

Ninu abala 9(2) ti ofin ọdun 1999, ida meji ninu mẹta ninu gbogbo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ lo gbọdọ buwọlu atunṣẹ eyikeyi atunṣe ki irufẹ atunṣẹ bẹẹ to le di ofin.

Ni bayii ti ipinlẹ mejilelọgbọn ti buwọlu u, o n tumọ si pe ile aṣofin agba ti ni iye ipinlẹ to nilo lati tẹwaju fun idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Bamidele ti sọ pe awọn yoo tẹsiwaju, yala awọn ipinlẹ mẹrin to ku buwọ lu atunṣe ofin naa tabi bẹẹ kọ.

Ki ni ohun to kan bayii?

Ọjọ kẹtadinlogun oṣu yii to jẹ gbedeke ti ile aṣofun agba fun awọn ipinlẹ naa lo ṣeeṣe ki araalu mọ igbesẹ to kan.

Amọ ṣa, ikuna awọn ipinlẹ ọhun lati fi iroyin igbesẹ ti wọn fẹ gbe ranṣẹ sile aṣofin naa ko di ohunkohun lọwọ mọ latari pe ida meji ninu mẹta awọn ipinlẹ ni Naijiria lo ti buwọlu atunṣe ofun ọlọpaa ipinlẹ naa.