Kira Taiwo: Ọmọ Ogogo sọ̀rọ̀ lórí àwọn tó fẹ́ fi ìtọ́jú bàbá rẹ̀ pawó ńlá, àlàyé rèé

Taiwo Hassan (Ogogo) ati ọmọ rẹ, Kira Taiwo

Oríṣun àwòrán, Kira Taiwo/ Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin fidio to ṣe lọsẹ to kọja lati kede pe Taiwo Hassan (Ogogo) ti ni aisan jẹjẹrẹ to wa ni ipele kẹrin, ọmọ oṣere naa; Shakira Taiwo, ti ṣe fọnran miran, nibi to ti ni awọn eeyan kan n gbiyanju lati fi idile Ogogo pawo nitori aisan naa.

Lori ẹka Tiktok ni Kira ti kede eyi lọjọ Abamẹta.

O ni awọn eeyan naa n yọju pe awọn fẹ tọju Ogogo, awọn ni oogun Jẹjẹrẹ lọwọ, amọ owo to le sọ idile awọn di ẹdun arinlẹ ni wọn n beere.

"Awọn kan n beere N800k, N5m, 11,000 dollars, N18,000 dollars"

Ninu fidio naa ni Kira ti sọ pe:

"Awọn eeyan kan n gbiyanju lati fi wa pawọ niru ipo yii, ẹ bẹru Ọlọrun.

"Eyi a wa, a beere N800k, N5m, 11,000 dollars, N18,000 dollars. Ṣe ẹ fẹ sọ wa dẹni ti ko lowo lọwọ ni? A ki i ṣe biliọnia."

Ọmọ Ogogo sọ pe idile awọn ko ni iru owo bẹẹ, o ni ohun to jẹ awọn logun ni kawọn ri itọju fun baba awọn.

Shakira Taiwo tun sọ pe oun paapaa ko fi gbogbo ara ni alaafia lasiko yii nitori ọrọ baba oun yii.

"Mo fẹ yẹ ifunpa mi wo, ara temi naa ko ṣe daadaa."

Ọ tun ṣalaye bi aarẹ Ogogo ṣe n nipa lara ẹgbọn oṣere naa to pe ni Big Daddy.

Kira sọ pe niṣe ni baba naa n beere pe ṣe Taiwo (Ogogo) yoo ku ni.

O fi kun un pe baba naa funra rẹ ko ni ilera pipe mọ latigba ti ọrọ aburo rẹ ti ṣẹlẹ.

O sọrọ nipa owo ti idile naa fi n ra oogun ara riro fun Ogogo bo ṣe wọn to, to jẹ eyi to kere ju ninu rẹ bẹrẹ lati ẹgbẹrun lọna aadọta naira (50,000) soke.

Shakira ni baba daadaa ni baba oun, amọ ailera to n koju yii ko tiẹ fẹ jẹ koun le wo oju rẹ.

O ni bi Oluwa ṣe n ṣe nnkan rẹ, Eledumare naa lo ye, amọ oun n wa iyanu ti yoo ṣẹlẹ, ti alaafia yoo fi pada sara Ogogo.

Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju

Ọsẹ to kọja yii ni awọn ọmọ Ogogo meji, Kira ati Lima Taiwo, ke gbajare lori ayelujara, pe baba awọn ti ni aisan jẹjẹrẹ to ti wa ni ipele kẹrin.

Wọn fi omije rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria, pe ki wọn dide iranlọwọ nipasẹ oogun ibilẹ, to ba si ṣe ti oloyinbo to daju naa ni.

Awọn ọmọ naa sọ pe awọn dokita oyinbo ni ko fẹ tọju Ogogo mọ, lo jẹ kawọn jade beere ọna mi-in.

Wọn sọ nigba naa pe awọn ko ba tilẹ gbe e lọ si India fun itọju, amọ ilera rẹ ko gbe irinajo naa mọ.

Kira ati Lima sọ nigba naa pe awọn ko tọrọ owo o, iranlọwọ ni gbogbo ọna miran lawọn tori ẹ wa sori ayelujara.

Ko ju ọjọ meji lẹyin ikede naa, ti okiki kan pe Ogogo ti jade laye latari aisan naa, amọ irọ gbuu ni eyi pada jẹ.

Opin ọsẹ to kọja yii si ni awọn agba oṣere lagbo tiata Yoruba korajọ, ti wọn ṣe adua nilana ẹsin Islam fun Taiwo Hassan; gbajumọ oṣere tawọn eeyan mọ si Ogogo.