Kí ló wà nínú àdéhùn àlááfíà tí Ààrẹ Tinubu àtàwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tọwọ́ bọ̀ bí ìpolongo ìbò ṣe bẹ̀rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Tinubu
Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, kede pe ipolongo ibo ọdun 2027 ti bẹrẹ fun awọn oloṣelu to ba fẹ dije lọdun to n bọ.
Bi ipolongo naa si ṣe fẹẹ gbera sọ ni Aarẹ Bola Tinubu pẹlu awọn oloṣelu Naijiria ti jọ kọwọ bọwe alaafia pẹlu ileri pe ko ni i si jagidijagan.
Atẹjade ti INEC fi sita lori ipolongo ibo ọdun to n bọ naa ṣalaye pe, awọn ẹgbẹ oṣelu le bẹrẹ ipolongo bayii.
Wọn ni wọn si ni anfaani lati ṣe bẹẹ fun aadọjọ ọjọ (150 days) ṣaaju ọjọ idibo gangan.
Wọnyi lawọn koko to de ofin ipolongo ibo

Oríṣun àwòrán, INEC/X
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ajọ INEC, Zainab Aminu Abubakar, ṣe ṣalaye fun BBC, awọn ofin kan wa to de ipolongo ibo fun awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn si gbọdọ tẹlẹ.
Awọn ofin naa to wa ninu abala kẹrinlelaadọrun-un (94) ẹse keji iwe ofin eto idibo ọdun 2026 ka pe:
- Ipolongo ibo gbọdọ bẹrẹ lọjọ to ba ku aadọjọ ọjọ ti idibo yoo waye.
- Iwọde, ipolongo ibo gbọdọ pari ni wakati mẹrinlelogun ṣaaju ọjọ idibo, eyi ti i ṣe ọjọ kan.
- Ẹgbẹ oṣelu gbọdọ yago fun lilo ọrọ to le da rogbodiyan silẹ niluu lasiko ipolongo.
- Ofin ko faaye gba ṣiṣe ipolongo ibo nile ijọsin, nitori ile ijọsin ki i ṣe ile oṣelu.
- Ofin ko faaye gba ẹgbẹ oṣelu meji tabi ju bẹẹ lọ lati polongo ibo lọjọ kan naa, lasiko kan naa, eyi le di rogbodiyan.
- Ẹgbẹ kọọkan gbọdọ fi to awọn alaṣẹ leti nipa ọjọ ati asiko pẹlu agbegbe to ti fẹẹ polongo ibo rẹ, ko ma baa si akọlukọgba ẹgbẹ oṣelu atawọn ọmọ ẹyin wọn.
Ki lo wa ninu adehun alaafia ti Aarẹ Tinubu atawọn ẹgbẹ oṣelu tọwọ bọ bi ipolongo ibo ṣe bẹrẹ?

Oríṣun àwòrán, INEC/ X
Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni wọn ẹgbẹ oṣelu to n dupo aarẹ ati ti ile igbimọ aṣofin kọwọ bọwe alaafia lori bi idibo ọdun 2027 yoo ṣe lọ.
Nibi eto naa to waye niluu Abuja ni wọn ti ṣeleri lati yago fun rogbodiyan, sisọ ọrọ odi sira ẹni, gbigbe iroyin ofege jade, kikoju ara ẹni atawọn iwa mi-in to le ṣakoba fun idibo naa.
Igbimọ to n ri si alaafia (National Peace Committee) lo gbe eto naa kalẹ pẹlu ajọṣepọ Kukah Centre, niluu Abuja.
Lara awọn ti wọn kọwọ bọwe alaafia naa ni Aarẹ Tinubu ti Akọwe ijọba; George Akume ṣoju fun.
Peter Obi to n dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu NDC.
Awọn mi-in ni Omoyele Sowore to n dupo aarẹ ninu ẹgbẹ African Action Congress ati Adewole Adebayo lati ẹgbẹ Social Democratic Party (SDP).
Bakan naa ni Alaga INEC, Ọjọgbọn Joash Amupitan wa nibẹ pẹlu ọga ọlọpaa pata ni Naijiria, Olatunji Disu, ti wọn si sọ pataki igbesẹ ọhun, ati bo ṣe jẹ adehun tawọn oloṣelu gbọdọ tẹle.
Lara awọn oloṣelu tawọn eeyan reti nibi eto naa amọ ti wọn ko yọju sibẹ ni Atiku Abubakar to n dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ADC ati gomina ipinlẹ Oyo; Seyi Makinde to n dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APM .
A le fi ara wa ṣe ẹfẹ, amọ ẹ yago fun jagidijagan, ẹlẹyamẹya ati ọrọ ẹsin- Tinubu
Ninu ọrọ ikilọ ti Aarẹ Tinubu sọ nibi eto alaafia naa lo ti ni ki awọn oloṣelu ma ṣe ba ara wọn ja nitori pe wọn fẹ sin ilu.
Tinubu sọ pe wọn le fi ọrọ ẹnu ṣe yẹyẹ ara wọn, amọ ki wọn yago fun ohun yowu ti yoo mu jagidijagan wa.
"A ko gbọdọ sọ idibo yii di bo o ba o pa a, ifẹ Naijiria lo si gbọdọ wa lọkan wa ju pe a fẹ jawe olubori lọ.
"A le tako ara wa lasiko ipolongo ibo pẹlu ẹgbẹ mi-in, a si le ta sira wa lawọn igba mi-in, ṣugbọn gẹgẹbii ọmọ Naijiria kan naa, a ko gbọdọ gbe ẹlẹyameya tabi ọrọ ẹsin wọ ọ nitori a n wa ipo agbara."
Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu ti George Akume ṣoju fun wi nibi eto naa.





























