Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ikú tó pa mọ̀lẹ́bí mẹ́rin lẹ́yìn tí wọ́n jẹ àmàlà tán ní Kogi

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Kogi, Ahmed Usman Ododo, ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori iku eeyan mẹrin ninu idile kan to jade laye lopin ọsẹ niluu Ihima, ijọba ibilẹ Okehi, ipinlẹ Kogi lẹyin ti wọn jẹ amala tan.
Koda, aja ti idile naa n sin paapaa jade laye lẹyin to jẹ ninu amala to pa awọn olowo rẹ.
Yatọ sawọn mẹrin to jade laye lori ounjẹ yii, iroyin kan sọ pe eeyan mẹsan-an lo tun wa nile iwosan latari ounjẹ kan naa ti wọn jẹ
Igbesẹ ijọba Kogi
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo ṣe kede ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamẹta, o ni Gomina Ododo ti paṣẹ fun ẹka eto ilera ipinlẹ naa lati wadii ohun to fa iku awọn eeyan naa ati aja wọn.
Fanwo sọ pe iwadii naa ṣe pataki lati ṣe, ki wọn le mọ boya ounjẹ naa ti lugbadi awọn ohun to le da bii majele fun ara bi eeyan ba jẹ ẹ ni.
"Iwadii naa gbọdọ fidi ẹ mulẹ, boya ounjẹ tawọn oloogbe naa jẹ ti ni ẹgbin ninu, tabi boya awọn nnkan kan lagbegbe wọn lo fa iku ọhun.
"Gbogbo awọn ohun to le da bii ẹ̀rí pata ni ki iwadii yii gbe yẹwo, ni ilana ilera awujọ."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade ijọba Kogi naa ka.
Bakan naa ni ijọba Kogi paṣẹ pe ki ẹka ilera rẹ ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹka miran to tun le ran iwadii yii lọwọ, ki wọn le ri aridaju ohun to fa iku naa.
"Ijọba rọ araalu lati fi ọkan balẹ, ki wọn ma ṣe gba pe nnkan kan lo pa awọn to di oloogbe naa titi ti iwadii yii yoo fi pari, ti awọn ẹka to yẹ si fidi rẹ mulẹ."
Ijọba Kogi ba ẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn yii daro, ati gbogbo agbegbe Ihima pata.
Wọn ni awọn yoo maa fi bo ṣe n lọ lede bi awọn ohun to fẹsẹ mulẹ nipa iwadii naa ba ṣe n jade.
Awọn igba ti iru iṣẹlẹ yii ti waye ri
Ẹ o ranti pe iṣẹlẹ iku ojiji lẹyin ti mọlẹbi ba jẹun tan, paapaa amala, ko ṣẹṣẹ maa waye lorilẹede yii, wọnyi ni diẹ lara iru rẹ to ti ṣẹlẹ ri.
Kwara: Iya, ọmọ ati ọmọ-ọmọ jade laye niluu Ilorin lẹyin ti wọn jẹ amala tan lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024.
Kogi:Oṣu Kẹjọ 2024 : Eeyan mẹfa lo dagbere faye niluu Anyoke, ijọba ibilẹ Adavi, nipinlẹ Kogi lẹyin ti wọn jẹ amala tan.
Iroyin sọ pe awọn ẹya ara pataki lo da iṣẹ silẹ lara wọn lẹyin ti wọn jẹ amala ti wọn fi ẹgẹ to lewu ṣe.
Kano, oṣu Kẹjọ 2024: Obinrin opo kan atawọn ọmọ rẹ marun-un ni wọn jade laye lẹyin wakati diẹ ti wọn jẹ amala tan.
Paki ti wọn fi ṣe elubọ naa ni a gbọ pe o ni majele ninu.
Benue: Oṣu Kọkanla 2022
O to eeyan mọkanla to jade laye lẹyin ti wọn jẹ amala tan niluu Ikobi, ipinlẹ Benue.
Amala ajẹku tawọn kan ṣẹku nile kan ti wọn ti kọkọ jẹ majele ninu ounjẹ ni awọn eeyan naa jẹ to si gba ẹmi wọn.




























