Àwọn ọlọ́jà ní àwọn kan ló mọ́ọ̀mọ̀ sọná sọ́jà Oranyan ní Ibadan, pè fún ìwádìí látọ̀dọ̀ ìjọ̀ba, Sarafadeen Alli ṣèlérí ìrànwọ́

Agbegbe ti ijamba ina ti ṣẹlẹ, awọn eeyan n ṣa awọn nnkan to jona ku
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Oranyan to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo mu sẹnu loru mọju ọjọ Aje, ọsẹ yii, nigba ti ọja agbegbe naa jona.

Bi awọn kan ṣe n kawọ mọri sunkun, naa lawọn miran n gbera ṣanlẹ, nigba ti awọn yooku n wa ẹkun mu bi gaari lasiko ijamba ọhun.

Ọpọ dukia olowo iyebiye, to fi mọ ọja ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun lo ba ijamba ina ọhun ti ẹnikẹni ko tii le sọ pato bo ṣe ṣẹlẹ.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ina mọnamọna lo ṣokunfa ijamba naa, bẹẹ lawọn miran n sọ pe kii ṣoju lasan, ti wọn si n rọ ijọba lati tọpinpin ohun to ṣokunfa.

Alaga ọja naa, Ọgbẹni Ayobami Sanusi nigba to n sọrọ, ṣalaye pe ijamba ọhun ti ko ibanujẹ pupọ sọkan awọn ara ọja naa.

Sanusi rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Oyo lati tete dide iranlọwọ fun awọn to kagbako ijamba naa, paapaa ni ẹka ti wọn ti n ta aṣọ.

O ni rau-rau ni apa kan ninu ọja Oranyan naa jona, to fi mọ gbogbo ṣọọbu to wa nibẹ, ti ko si sẹni to fẹẹ da ibi ti ṣọọbu rẹ mọ mọ.

O sọ siwaju pe ọpọ awọn ti ṣọọbu wọn jona ni wọn ko ni ibi ti wọn ti le maa rọwọ mu lọ sẹnu mọ, to si rọ ijọba lati dide iranwọ.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni gbogbo igbiyanju lati pa ina ọhun lo ja sip abo, pẹlu bi awọn waya ina to yi ọja naa ka tun ṣe ṣe iranlọwọ fun ijamba ọhun.

O wa banujẹ wipe ijamba naa ti ko ọpọ awọn tọrọ kan sinu oko gbese pẹlu awọn nnkan ti wọn padanu.

Kí ló fa awuyewuye?

Ajoku isọ kan lọja Ọranyan

Ṣugbọn sibẹ, oniruuru awuyewuye lo waye lẹyin ijamba ina ọhun ninu ọja naa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn ọta inu ọja lo mọ-ọn mọ ju ina sinu ọja ọhun, naa lawọn kan n sọ pe awọn ti ko nifẹ ilọsiwaju ọja naa ni wọn ṣiṣẹ ibi yii.

Sibẹ, lawọn kan n rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Oyo lati boju aanu wo awọn, lori awọn dukia to jona.

Awọn agbegbe ti wọn ti n ta goolu, igi, aṣọ bọsikọrọ atawọn miran la gbọ pe ina ọhun sọ di eeru, ti ko si sẹni to ri ohunkohun mu jade.

Kí ni ìjọba sọ ṣáájú?

Awọn eeyan n duro ni isọri-isọri ni ọja to jona ni Ọranyan.

Ṣaaju asiko yii ni oludamọran pataki si Gomina Seyi Makinde lori ọrọ ina, Morof Akiwande ti fidi ijamba ọhun mulẹ.

Akinwnde, ẹni to tun jẹ alaga ileeṣẹ pannapanna nipinlẹ naa rọ awọn eeyan lati dẹkun gbigbe iroyin ti ko tọna nipa iye ṣọọbu to jona kaakiri.

O sọ pe lẹyin iṣẹ iwadii kikun, ni awọn yoo too le sọ pato iye ṣọọbu to jona, ati iye ọja to wa ninu ṣọọbu kọọkan.

Sharafadeen Alli, Oludije ẹgbẹ oṣelu APC ṣèlérí iranwọ?

Awọn eeyan n duro ni isọri-isọri ni ọja to jona ni Ọranyan.

Oludije sipo gomina ipinlẹ naa, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lọdun 2027, Sharafadeen Alli, lasiko abẹwo to ṣe lọ si ọja naa ba awọn eeyan kẹdun.

Sharafadeen ṣeleri lati dide iranlọwọ to yẹ fun gbogbo awọn to padanu okoowo wọn.

Nibẹ lo ti sọ pe oun yoo fun wọn ni miliọnu lọna aadọta naira lati fi ṣe iranwọ fun wọn.