Ọkọ̀ ojú omi tó kó èrò 77 yí dànù, èrò 46, tí ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ ọmọdé kú, 15 yè, wọn ń wá àwọn èèyàn 16 tó kù

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan, eeyan to to mẹrindinlaadọta ni wọn ti gbe oku wọn jade ninu isẹlẹ ijamba ọkọ oju omi kan to waye nilu Gorau, nijọba ibilẹ Goronyo nipinlẹ Sokoto.

Atẹjade kan ti ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Sokoto fisita salaye pe eeyan mẹtadinlọgọrin lo wa ninu ọkọ oju omi naa, to fi mọ ọkunrin, obinrin, ọmọde atawọn agbalagba nigba ti isẹlẹ naa waye.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Sokoto, Ahmed Rufai ni eeyan mẹẹdogun pere ni awọn ri yọ ninu odo laaye.

O wa salaye pe isẹ idoola ẹmi awọn eeyan yoku to wa ninu odo si n lọ lọwọ nigba tawọn ikọ adoola ẹmi si n sisẹ kara lati se awari awọn eeyan mẹrindinloku to ku

Lara awọn ikọ adoola ẹmi naa, gẹgẹ bi Rufai se sọ ni awọn ọlọpaa, awọn omuwẹ labẹle, ikọ to n pese eto pajawiri fun awọn ti ajalu ba de ba nipinlẹ naa ati labẹ ijọba apapọ.

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, amugbalẹgbẹ feto iroyin fun gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Dan'iya sapejuwe isẹlẹ na bi eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ.

O sisọ loju rẹ pe ọpọ awọn eeyan to ku naa lo jẹ ọmọde ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹwa si mẹẹdogun.

Ọpọ si lo ni wọn n rinrin ajo loju omi naa pẹlu awọn agbẹ atawọn agbasẹse.