Gómìnà Adeleke gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣe ìwádìí àwọn ìpànìyàn tó wáyé nílùú Ikire

Oríṣun àwòrán, OsunStategovernment
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti gbe aṣẹ tuntun fun idasilẹ igbimọ oluwadii dide lati ṣewadii awọn ipaniyan ati iwa ipa to waye ni orita Naira ati Kobo, garaaji ọkọ ni ilu Ikire, ijọba ibilẹ Irewole ni ọjọ Kerinlelogun, oṣu Kẹjọ.
Igbimọ oluwadii naa ti adajọ Majisireeti Ayokunle Shiyanbola ko sodi ni wọn yoo ṣewadii ohun to ṣokunfa ikọlu naa, ṣe agbejade iye ati orukọ awọn to fori sọta iṣẹlẹ naa, ṣewadii ohun to ikọlu ọhun ati boya o ni nnkan ṣe pẹlu iku to waye nibẹ.
Aṣẹ naa, ti yoo bẹrẹ iṣẹ lọjọ Kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 2026 tun fun igbimọ naa laṣẹ lati ṣewadii ipa tawọn ẹṣọ aabo ko lori ikọlu naa ati lati mọ boya wọn ṣina ibọn bolẹ ni ilana to ba ofin mu lasiko ti ikọlu naa fi waye.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina Adeleke, Olawale Rasheed fi lede lọjọ Abamẹta lo ti kede aṣẹ tuntun ti gomina ṣẹṣẹ kede rẹ yii.

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Facebook
"Igbimọ naa maa ni agbara lati ranṣẹ pe awọn ẹlẹrii, beere fun awọn akọọlẹ ileeṣẹ ọlọpaa ati akọọlẹ ile iwosan"
Rasheed ninu atẹjade naa fikun pe igbimọ naa yoo tun ṣewadii boya iṣẹ tabi ihuwasi awọn kan tabi ẹgbẹ kan lọwọ ninu ohun to kan kun ikọlu ọhun.
O ṣalaye pe igbimọ naa ni agbara lati darukọ ọlọdanni, lẹgbẹlẹgbẹ, ẹṣọ aabo, oloṣelu, ọmọ ẹgbẹ onimọto, tabi ẹlomiran ti iwa tabi iṣe wọn ba da kun iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni igbimọ naa maa ni agbara lati beere fun ijiya to tọ fun awọn ti ade iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori nigba ti wọn si le sọ iye owo gba mabinu to tọ si awọn ti wọn fori ṣọta ikọlu naa.
Igbimọ naa yoo tun lagbara lati ko ẹri jọ, ti wọn si le ba awọn ẹlẹrii sọrọ lati jẹrii lori iṣẹlẹ naa.
"Igbimọ naa maa ni agbara lati le ranṣẹ pe awọn ẹlẹrii, beere fun awọn akọọlẹ ileeṣẹ ọlọpaa ati akọọlẹ ile iwosan, ṣe abẹwo sibi ti iṣẹlẹ ti waye atawọn ibi to ṣe koko mii."
"Gbogbo awọn ti ade iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori ni wọn maa foju wina ofin"
Gomina Adeleke tun paṣẹ ṣiṣe akoso awọn ohun ẹri daadaa eyi to le fidi ohun to waye nibi ikọlu naa mulẹ.
Idari gomina naa tun paṣẹ dida aabo to peye bo awọn to ba jade jẹrii lori ikọlu naa atawọn ẹbi awọn to ba ikọlu naa lọ, ki wọn si ri daju pe aabo to daju wa niluu Ikire titi ti iwadii naa fi maa pari.
Lara igbesẹ lati mu ki iwadii igbimọ naa kẹsẹ jari, wọn rọ ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, ajọ to n mojuto ileeṣẹ ọlọpaa ati Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Osun lati lati gbe igbesẹ ofin to yẹ lori ọlọpaa ti wọn ba ri pe iṣẹ rẹ le ṣe idiwọ fun iwadii naa.
Laaarin ọjọ meje ti wọn ṣe agbedide igbimọ yii ni wọn yoo bẹrẹ iṣẹ, ti wọn si ni ọgbọn ọjọ lati fi abọ iwadii ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Osun lẹyin ọjọ akọkọ ti wọn ba jokoo.
Ijọba wa rọ gbogbo awọn to ba ni ẹri to le ran igbimọ naa lọwọ lori iwadii wọn lati fi ranṣẹ si igbimọ naa.
Bakan naa ni wọn rọ awọn ẹbi awọn to fori ṣọta ikọlu naa, awọn ti iṣẹlẹ ṣoju wọn, awọn akọroyin, awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ, awọn olori ilu lati jade fi ẹri wọn ṣọwọ si igbimọ naa.
Gomina Adeleke tun ṣeleri fun awọn eeyan ilu Ikire ati ipinlẹ Osun lapapọ pe iwadii naa maa lọ lai ni ẹja n bakan ninu.
O fi kun pe gbogbo awọn ti ade iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori ni wọn maa foju wina ofin.
Adajọ Shiyanbola lo maa jẹ alaga igbimọ naa nigba ti ọgbẹni Abiodun Badiora yoo jẹ akọwe igbimọ.
Lara awọn ti wọn maa jẹ ọmọ igbimọ naa ni Aderanti C. Kayode, Dele Akintayo, aṣoju ẹgbẹ awọn agbẹjọro, Wale Balogun aṣoju ẹgbẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, aṣoju awọn ọmọ ilu Ikire ati bẹẹ bẹẹ lọ.



























