Gómìnà Adeleke, mo kí ẹ kú oríire pé o wọlé fún sáà kejì àmọ́ ọ̀rọ̀ sì kù lẹ́yìn rẹ̀ - Oyebamiji, olùdíje gómìnà APC l'Osun

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Oludije sipo gomina ipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Oyebamiji ti ki akẹgbẹ rẹ to jawe olubori, Gomina Ademola Adeleke ku oriire.
Ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, ẹka tipinlẹ Osun, lo kede Ademola Adeleke gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo gomina ipinlẹ Osun lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.
Oyebamiji nigba to n ba awọn ọmọ ẹyin ati alatilẹyin rẹ sọrọ fun igba akọkọ lẹyin eto idibo naa, iyẹn lọjọ Abamẹta to kọja, lo ti sọ pe oniruuru aṣemaṣe lo waye lasiko eto idibo naa.
Nigba to n ba awọn eeyan rẹ sọrọ, Oyebamiji parọwa pe ki gbogbo idunkoko, ikọlu ati ipaniyan to n ṣẹlẹ kaakiri ipinlẹ Osun dawọ duro, fun igbayegbadun araalu.
O wa sọ pe lẹyin ti ajọ eleto idibo kede eto idibo naa, oun gbe igbesẹ lati ba awọn agbaagba, alẹnulọrọ ati awọn tọrọ kan sọrọ, lori igbesẹ to kan lati gbe, fun itẹsiwaju.
"Gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu, a fi ara jin fun eto idajọ ododo, bẹẹ si la maa tẹsiwaju lati beere fun idajọ ododo nipasẹ ofin, paapaa julọ ni ilana eto idibo.
"Mo wa rọ gbogbo yin lati ma ṣe ni irẹwẹsi ọkan. A ni lati duro ṣinṣin ninu iṣọkan, ka si duro lori igbagbọ si eto oṣelu awa-ara-wa, ati itẹsiwaju lati ni igboya ninu eto ofin to daabo bo ẹtọ wa labẹ eto iṣejọba awa-ara-wa," Oyebamiji sọ bẹẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe, "Ninu ẹmi eto oṣelu awa-ara-wa, ati bi a ṣe n ṣajọyọ ayẹyẹ idasilẹ ipinlẹ Osun wa, mo ki Ọlọlajulọ, Sẹnetọ Ademola Adeleke, gomina ipinlẹ Osun ku oriire lori aṣeyọri lasiko eto idibo gomina to waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026, gẹgẹ bi ajọ eleto idibo INEC ṣe kede rẹ.
"Bakan naa, mo n pe Gomina, gẹgẹ bi alabojuto ọrọ eto aabo nipinlẹ, lati ṣe ohun gbogbo to wa ni ikawọ rẹ labẹ ofun, lati daabo bo ẹmi ati dukia gbogbo araalu, paapaa lasiko ti eto idibo ṣẹṣẹ pari yii."
Àwọn tó lé ní márùndínlógójì ni APC pàdánù
Oyebamiji ninu ọrọ rẹ siwaju sii, lo ti ṣe iranti awọn ohun to ti ṣẹlẹ ṣaaju ati lasiko eto idibo gomina ọhun, to si lo yẹ ki ayipada rere ti waye.
O jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu to le ni marundinlogoji ni wọn padanu ẹmi wọn ninu gbogbo ikolu to ti waye nipinlẹ Osun.
Bakan naa lo rawọ ẹbẹ si ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii finnifinni lori awọn ikọlu ati ipaniyan to waye, ki wọn si rii daju pe wọn fọwọ ṣikun ofin mu gbogbo awọn to lọwọ ninu iwa ọdaju naa, lati le jẹ ki ofin sọrọ lori wọn nipa idajọ ododo.
A ní láti dúró ṣinṣin fún ìdìbò 2027
Siwaju sii ni Oyebamiji gbe oṣuba kare fun Aarẹ Bola Tinubu ati minisita nni, Adegboyega Oyetola fun atilẹyin wọn lasiko eto idibo gomina to waye.
O wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati tẹsiwaju nipa atilẹyin fun eto idibo apapọ to n bọ lọdun 2027, lati rii daju Aarẹ Tinubu jawe olubori fun saa keji.
"A ni lati duro ṣinṣin, lati le ro ara wa lagbara nipa agbekalẹ oṣelu ti a ni, ka si le rii daju pe Aarẹ ati gbogbo awọn oludije sipo kaakiri ipinlẹ Osun jawe olubori," Oyebamiji sọ bẹẹ.
"Ni ipari, mo gbe oṣuba kare fun igboya, ifarada ati iduro ṣinṣin si ẹgbẹ oṣelu wa, ati si awọn agbekalẹ ipinnu rere ti a duro fun. Eto oṣelu awa-ara-wa kii ṣe opin fun ara rẹ; o jẹ ọna ti ifẹ ati igbayegbadun awọn eeyan yoo fi ni itẹsiwaju.
"A ma maa tẹsiwaju nipa igbagbọ ati ipinnu si ipinlẹ Osun. Ipinlẹ ti ohun amuṣọrọ wa n lọ daadaa, ti awọn anfaani si wa ni arọwọto, ati ti ijọba n ṣe ojuṣe rẹ fun igbayegbadun awọn araalu, dipo iwa imọ imọtara-ẹni-nikan. Mo dupẹ lọwọ gbogbo yin."



























