Òkú sùn, dúkìá ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù bàjẹ́ lásìkò táwọn awakọ̀èrò gbìyànjú láti gba gáréèjì ní Ikire

Aworan awọn janduku kan nibi iwọde.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Rogbodoiyan tun bẹ silẹ lori ọrọ gareeji gbigba ni ipinlẹ Ọṣun ni owurọ ọjọ Aje eyi to ṣokunfa iku awọn eeyan ati biba ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye jẹ.

Iroyin to n tan kaakiri n sọ pe eeyan marun un, meji ninu wọn jẹ araalu to n lọ jẹjẹ wọn lo ba iṣẹlẹ naa lọ, amọṣa awọn to ba BBC News Yoruba sọrọ lati ilu naa sọ pe eeyan meji lo ti ku ti ẹni kẹta si wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.

Gẹgẹbi ohun ti a gbọ, awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ero to wa labẹ igun kan naa ni wọn n ba ara wọn ja lori wi pe igun kan lo kan lati ṣe akoso ẹgbẹ naa dipo ẹni to ti wa nibẹ lati igba ti gomina Ademọla Adeleke ti wọle sipo ni ọdun 2022.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ko tii fi idi iye awọn to ku ninu iṣẹlẹ naa mulẹ, amọṣa, DSP Abiọdun Ọjẹlabi to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ṣalaye fun BBC News Yoruba pe awọn ti da ọlọpaa kogbere sigboro ilu Ikire bayii lati da alaafia pada si ilu naa.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Ṣaaju asiko yii, lawọn iroyin kan ti n jade pe awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ero NURTW kan to wa lẹyin Ọlamilekan Ajagungbade ti ọpọ mọ si Emir n fẹ gba gareeji ati akoso ẹgbẹ naa lọwọ alaga ẹgbẹ naa, Wakeel Nurudeen Alowonle ti eyi si ti n da ọpọ wahala silẹ.

Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Ọṣun, Kọla Alimi, ti kọkọ pariwo sita lọjọ Aiku pe awọn eeyan kan n gbimọran lati da wahala silẹ lawọn gareeji ọkọ ero kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

"Alaafia fun idagbasoke ni ipinlẹ Ọṣun nilo bayii, kii ṣe oṣelu onijagidijagan."