Pásítọ̀ Olùdásílẹ̀ ìjọ Ọlọ́run ṣàlàyé ìdí tó fi fẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ di oníṣẹ̀ṣe tó sí pa orúkọ dà láti Felix sí Ifawamiri

Oríṣun àwòrán, Olabanjo Felix Gold/Facebook
Oludasilẹ ijọ Image of God Evangelical and Prophetic Ministry, Olabanjo Felix Gold, ti kede wi pe oun ti kuro ninu ẹsin ọmọlẹyin Kristi, oun si ti di ẹlẹsin ibilẹ bayii.
Ọgbẹni Gold to jẹ pasitọ tẹlẹ kede ninu fọnran kan to ti lu ori ayelujara pa wi pe oun ti yi orukọ oun pada si Ifawamiri Aworan-Olodumare Babalawo Onifa bayii.
Ifawamiri tun dupẹ lọwọ Oluwo rẹ, Baba Efuape Olusegun Olatunji, ti o jẹ Araba ilu Isara-Remo nipinlẹ Ogun.
Ọgbẹni Ifawamiri ko ṣai dupẹ lọwọ awọn ọmọkunrin meji Araba Isara-Remo, Fasegun ati Fawale fun bi wọn ṣe n tọ oun sọna.
''Mo tun dupẹ lọwọ Fatosin Arigbede to jẹ Ashawo ti ilu Isara-Remo bakan naa.
Mo dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ awo patapata ti mo ba ni ibi.
Mi o le ṣai dupẹ lọwọ wọn papaa julọ fun bi wọn ṣe gba mi tọwọ tẹsẹ,'' Ifawamiri lo sọ bẹẹ.
Ifawamiri tun fikun ọrọ rẹ wi pe ẹtan lo wa ninu ẹsin ajoji tawọn oyinbo mu wa silẹ alawọ dudu.
Ọgbẹni Olabanjo to jẹ oludasilẹ ijọ Image of God Evangelical and Prophetic Ministry sọ pe ''awọn ẹlẹsin ajoji kan n tan wa ni o, iṣẹṣe lagba.
Fun iwọ naa ti o ba fẹ wọ Gbodu, tabi ti o fẹ tẹ Ifa, o fẹ beere lọwọ Irunmọlẹ, o fẹ ba Ifa ni gbolohun, tabi o fẹ mọ bi ọrọ aye rẹ ṣe ri, mo n fi asiko yii sọ fun ọ wi pe ki o kan si Baba Efuape Olusegun Olatunji, Araba ti ilu Isara-Remo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post



























