Àrùn diphtheria tó pa ọmọdé méje ní Imo ti rápálá wọ ìpínlẹ̀ Eko, wo bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ

Awọn ọmọde to wa nile iwosan
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ijoba ipinlẹ Eko ti kede pe arun diphtheria ti ra pala wọ ipinlẹ naa lẹyin ti ayẹwo fi han pe eeyan mẹfa ni arun ọhun nigba ti wọn ṣi n ṣayẹwo eeyan mẹtalelaadọta lọwọ.

Kọmiṣọna eto ilera, Akin Abayomi to fi ikede naa sita lọjọru sọ pe awọn ti n ṣetọju eeyan mẹfa to ko nigba awọn ti bẹrẹ si n wa awọn eeyan ti awọn eeyan naa ti farakan ṣaaju.

Lẹyin naa lo rọ awọn araalu ki wọn ma foya nitori arun ọhun ko tii di ohun to burẹrẹ nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ijọba ipinle nan n ṣe ohun gbogbo yẹ lati ri daju pe arun naa ko burẹkẹ ju boṣe yẹ lọ.

Abayomi ni, "A n rọ gbogbo olugbe ilu Eko ki wọn ma foya.

"Arun diptheria ko tii burẹkẹ nipinlẹ Eko. A n ṣe ohun gbogbo yẹ lati dena rẹ."

Ẹwẹ, Abayomi ti rọ gbogbo awọn obi ati alagatọ ki wọn lọ fun awọn ọmọ wọn labẹrẹ ajẹsara lati dena arun naa lai fi akoko ṣofo.

Kí ni àrùn Diphtheria tó pa ọmọdé méje ní Imo, tó tún mú kí ilé ìwòsàn kún fọ́fọ́ ní Katsina?

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide San-Olu nibi eto ilu kan

Aisan diphtheria ti burẹkẹ nipinlẹ Katsina, o si le to bẹẹ ti ile iwosan ijọba apapọ Federal Teaching Hospital, FTH, to wa nibẹ ko fi gba ero mọ bayii.

Ninu atẹjade kan ti ile iwosan naa fi lede, wọn ni ọpọ awọn ọmọde ni aisan naa kọlu ti ero si ti pọ ju bo ṣe yẹ lọ ni ẹka itọju ọmọde nile iwosan ọhun.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ojojumọ lawọn obi n ko awọn ọmọ wọn to lugbadi arun naa wa sile iwosan ọhun bayii, ẹsẹ ko si gba ero mọ.

Bo tilẹ jẹ iye awọn alaisan naa ti fẹ pọ ju iye olutọju to wa nibẹ lọ, FTH ni awọn n sa ipa awọn lati ṣetọju awọn ọmọde naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, aisan diphtheria yii kan naa ti ran ọmọde meje lọ sọrun aitọjọ nipinlẹ Imo lọdun 2023.

Abẹrẹ diphtheria

Nkan to yẹ ki o mọ nipa Diphtheria

Aarun diphtheria jẹ oriṣi kokoro aifojuri ‘bacteria’ to ma n kọlu eroja (mucous membranes) to n daabo bo imú ati ọ̀fun.

Lootọ ni oogun oyinbo ma n wo diphtheria, ṣugbọn to ba ti pọ ju ninu ara, o le ba ọkàn, kindinrin ati ọpọlọ jẹ.

Koda pẹlu itọju, aarun naa ṣi le pa eeyan, paapaa awọn ọmọde.

Kilo n fa diphtheria?

Oriṣi kokoro aifojuri ‘Corynebacterium diphtheria’ lo n fa a . Kokoro aifojuri naa yoo ma a pọ si ni ọna ọfun tabi ni awọ ara.

Ti ẹni to ni aarun diphtheria ba sín tabi hu ikọ sinu afẹfẹ, ẹni to ba sunmọ ọ tabi kọja lasiko naa le fa C. diphtheria si imu. Ọna kan pataki ti diphtheria fi ma n di ajakalẹ re e , paapaa ni ayika ti eero ba pọ si.

Eeyan tun le ko aarun yii, to ba fi ọwọ kan awọn ohun elo bi aṣọ inuwọ, ati awọn nkan mii, ti ẹni to ni aarun diphtheria lo nitori pe o ṣe e ṣe ki aarun naa ti sa pamọ si wọn lara.

Yatọ si ọna ọfun, diphtheria tun le farahan ni awọ ara.

Iru eyi ma n fa irora ninu ara, ara wiwu ati ara pipọn.

Botilẹ jẹ pe ko wọpọ niru agbegbe bi Naijiria, o le ṣẹlẹ laarin awọn eeyan ti imọ toto wọn ko ba dara to, tabi awọn to n gbe ni ibi ti eero ti pọ ju bo ṣe yẹ.

Awọn ami ti diphtheria ma n fihan ninu ara:

Laarin ọjọ meji si marun-un, ni aarun diphtheria ma n farahan to ba ti wọ ara.

Lara awọn ami naa si ni:

  • Egbo ni ọna ọfun
  • Ọrun yoo wú
  • Idiwọ si eemi tabi ki eeyan o ma a mi lakọ-lakọ
  • Ikun imu yoo ma jade lai dawọ duro
  • Ara gbigbona ati otutu
  • Aarẹ yoo mu ara
  • Kẹlẹbẹ to ni awọ eeru yoo bo ọfun

Bakan naa lo ṣe e ṣe ki ẹni to ni diphtheria, ma ri ami kankan – iru awọn eeyan bayii lo ma n ṣaba pin aarun naa kiri, lai ṣe pe awọn funra wọn dubulẹ aisan.