A ti ṣetán láti ṣàtìlẹ́yìn fún ìjọba lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ – OPC

Oríṣun àwòrán, OPC
Ẹgbẹ Oodua People's Congress, OPC, ti ke si ijọba apapọ ko tete wa nnkan ṣe lati yanju eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.
OPC sọ pe awọn tun ti ṣetan lati ṣe atilẹyin fun ijọba apapọ lati koju iṣoro eto aabo naa.
Ọrọ yii lo jẹyọ lọjọ Abamẹta nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti n ṣe iranti idasilẹ ẹgbẹ ọhun lọdun mejilelọgọbọn sẹyin.
Aarẹ egbẹ naa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ burawọle fun nibi eto naa to waye niluu Eko, Wasiu Afolabi lo sọ bẹẹ.
Afolabi ke si Aarẹ Bola Tinubu atawọn ijọba ipinlẹ mii ki wọn ri eto aabo gẹgẹ bii ohun ti ko yẹ ki wọn fi ọwọ rẹpẹrẹ mu.
Nigba to n mẹnuba abala 14(2)(b) iwe ofin orilẹede Naijiria, o ni ojuṣe ijọba ni lati daabo bo ẹmi ati dukia gbogbo ọmọ Naijiria, wọn ko si gbọdọ kunọ ninu rẹ.
Lẹyin naa lo tun ke si awọn ọba alade atawọn olori mii ki wọn ji giri si eto aabo.
"A maa ṣatilẹyin fun Tinubu fun saa keji"
Ẹwẹ, OPC tun sọ siwaju si pe awọn yoo ṣatilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu lati ṣaṣeyọri ninu igbiyanju rẹ lati de ipo Aarẹ fun saa keji.
Afolabi ni OPC wa lẹyin Tinubu lasiko to n du ipo Aarẹ fun saa rẹ akọkọ, ẹgbẹ ọhun yo tun tii lẹyin lati ṣe saa keji.
Lẹyin naa lo ke si awọn ẹya mii ni Naijiria ki wọn ṣe atilẹyin fun, paapaa awon eeyan iha ariwa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o yẹ ki wọn ṣatilẹyin fun Tinubu lati ṣe saa keji gẹgẹ bi Tinubu funra rẹ ṣe ṣatilẹyin fun Aarẹ ana, Muhammadu Buhari lati lo ọdun mẹjọ lori oye.
O ni "Awọn eeyan ariwa ni lati mọ pe akoko ti to bayii lati san oore fun Tinubu nipa ṣiṣe atilẹyin fun lati wọle fun saa keji ko le pari awọn iṣẹ rere to ti bẹrẹ."
O pari ọrọ rẹ pẹlu arọwa si awọn igbimọ rẹ ti wọn ṣẹṣẹ burawọle fun ki wọn ma ṣe kuna ninu ojuṣe wọn faraalu.

























