Tinubu ti lò kọjá ọjọ́ 21 níta, ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin gbọ́dọ̀ gbé ìṣàkóso Naijiria fún Shettima bíi Adelé ààrẹ - Sowore

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore/Facebook
Ọrọ nipa Aarẹ Bola Tinubu ti ko si ni Naijiria lasiko yii, ti wọn si tun kede afikun ọjọ rẹ loke okun ṣi n ja ran-in nilẹ.
Yatọ si Atiku Abubakar to ti kọkọ kọminu lori ọrọ yii, Omoyele Sowore, Ajafẹtọọ ọmọniyan to tun n dupo aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAA) naa ti ke gbajare tuntun.
Gbàjarè e Sowore
Lọjọ Iṣẹgun ni Sowore ke gbajare, pe ohun to yẹ bayii ni ki ile igbimọ aṣofin gbe agbara iṣakoso Naijiria le Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima, lọwọ lati maa tukọ orilẹede yuu lọ.
Sowore sọrọ yii lori afikun ọjọ ti ileeṣẹ Aarẹ tun kede pe Tinubu yoo tun lo loke okun.
Ajafẹtọọ ọmọniyan to tun jẹ agbẹjọro naa gba Olori ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ati Olori ile igbimọ Aṣoju; Abass Tajudeen, nimọran lati lo abala 145(2) ofin Naijiria.
Abala naa lo sọ ohun to yẹ kijọba ṣe bi aarẹ ko ba si nile fun igba to ju ọjọ mọkanlelogun lọ.
Abala naa ka pe aarẹ yoo kọ lẹta sile igbimọ aṣofin ati aṣoju lati sọ fun wọn nipa ai le si ni ọfiisi rẹ lasiko kan fun isinmi tabi fun idi miran.
Iwe naa ni yoo gbe agbara le Igbakeji rẹ lọwọ lati maa dele de aarẹ lọ.
Bi Aarẹ ko ba kọwe naa laaarin ọjọ mọkanlelogun, ile igbimọ aṣofin ni agbara lati faṣẹ si I pe ki Igbakeji rẹ maa ṣejọba lọ.
Wayi ti Aarẹ Tinubu ti lo ju ọjọ mọkanlelogun lọ lẹyin odi, ti ko si ti i ṣafihan iwe to fi faṣẹ le igbakeji rẹ lọwọ, Sowore sọ pe:
"Ọjọ mọkanlelogun ti kọja, ile igbimọ aṣofin agba gbọdọ bẹrẹ igbesẹ naa pẹlu titẹle abala 145(2), lati paṣẹ fun Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima, pe ko maa dele lọ bii Adele Aarẹ."
"Ile igbimọ aṣofin apapọ gbọdọ bẹrẹ igbesẹ ofin lẹsẹkẹsẹ".
Sowore sọ pe bi ileeṣẹ Aarẹ ṣe n pe isinmi aarẹ ni eyi to mu iṣẹ lọwọ ko yi ohun ti ofin sọ pada nipa asiko ti ko ba si nile.
"Ileeṣẹ Aarẹ ko le gbe awuruju isinmi iṣẹ kalẹ (Working vacation). Bi wọn ṣe n sọ pe o n dari lati oke okun ki i ṣe ohun ti ofin sọ."
Amọ ileeṣẹ Aarẹ ti fesi ṣaaju, pe ai si nile Tinubu lasiko yii ko tumọ si pe o lufin kankan.
Kí ni òfin Nàìjíríà sọ nípa fífa agbára lé Igbákejì ààrẹ lọ́wọ́ bí ààrẹ kò bá sí nítòsí? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Pẹlu bi asiko isinmi ọsẹ mẹta ti i ṣe ọjọ mọkanlelogun (21) ti Aarẹ Bola Tinubu lọ fun ṣe ti pe, ti aarẹ ko si ti i pada de si Naijiria, ọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori ohun to yẹ ko ṣẹlẹ bi ọrọ ba ri bayii.
Labẹ ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999, abala 145 (2), o ṣalaye pe bi aarẹ ba lọ fun isinmi lẹnu iṣẹ, tabi ti ko ni anfaani lati ṣiṣẹ rẹ bo ṣe yẹ fun idi kan, igbesẹ wa ti yoo gbe labẹ ofin.
Ki ni ofin sọ?
Igbesẹ ọhun bi ofin ṣe wi ni pe Aarẹ yoo kọ iwe si olori ile igbimọ Aṣofin Agba ati Abẹnugan ile igbimọ aṣoju, ti yoo fi kede ai le ṣiṣẹ to gba lasiko naa fun wọn.
Lẹyin eyi ni Igbakeji Aarẹ yoo si bẹrẹ iṣẹ naa gẹgẹ bii ẹni to n delé de Aarẹ titi ti yoo fi pada si ẹnu iṣẹ rẹ.
Abala naa tẹsiwaju, pe bi Aarẹ ko ba fi iru iwe bẹẹ ṣọwọ titi ti ọjọ mọkanlelogun fi pe, ile igbimọ aṣofin agba yoo gbe iṣẹ naa le Igbakeji aarẹ lọwọ lati maa ṣe e lọ.
Amọ ni ti Aarẹ Bola Tinubu to rin irinajo yii, ohun ti awọn alẹnulọrọ n sọ ni pe Aarẹ ko fi iwe kankan silẹ bi ofin ṣe wi.
Bakan naa ni wọn si n sọ pe ile igbimọ mejeeji paapaa ko gbe igbesẹ to yẹ nipa fifa iṣẹ Aarẹ le Igbakeji rẹ lọwọ bo ṣe yẹ.
Tẹ o ba gbagbe, Aarẹ Tinubu kuro ni Naijiria lọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, ileeṣẹ rẹ si tun kede lọjọ Aje pe afikun ti ba iye ọjọ ti Aarẹ yoo lo lajo, wọn lo di opin ọsẹ ko too de si Naijiria bayii.
Tinubu kò lùfin kankan pẹ̀lu àì sí nílé rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni Atiku ń sọ - Iléeṣẹ́ Ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Presidency/Atiku Abubakar/Facebook
Lẹyin awuyewuye to n waye lori isinmi Aarẹ Tinubu nilẹ Europe ati bo ṣe ran Igbakeji rẹ, Kashim Shettima lọ ṣoju rẹ l'America, ileeṣẹ Aarẹ ti fesi pe Tinubu ko lufin kankan nipa bo ṣe wa lajo lasiko yii.
Awọn atẹjade to n ti ileeṣẹ Aarẹ wa lo n kede pe Atiku Abubakar atawọn mi-in to n sọrọ lori aisi nile Tinubu ati Igbakeji rẹ n sọ ase ni.
Ṣaaju ni Atiku ti bu ẹnu atẹ lu bi Tinubu ko ṣe yọju sipade apapọ awọn olori agbaye l'America, UNGA 81, to ran Shettima lọ.
Nigba ti ileeṣẹ Aarẹ si tun kede lọjọ Aje, pe Tinubu ti ṣafikun ọjọ rẹ lajo, Atiku tun ke gbajare pe ta lo n dari Naijiria gan-an nigba ti Aarẹ, Igbakeji rẹ at Olori ile igbimọ aṣofin agba wa lẹyin odi.
"Ọjọ mọkanlelogun ni Aarẹ ni lati sinmi, ọjọ mẹẹẹdogun lo ṣi lo ninu rẹ"
Ni itẹsiwaju alaye pe Tinubu ko lufin kankan ninu alakalẹ ofin ọdun 1999, Amugbalẹgbẹẹ agba fun Aarẹ lori eto iroyin; Tope Ajayi, ṣalaye fun ẹka iroyin THISDAY pe:
"Ọjọ mẹẹẹdogun pere ni Aarẹ ṣi lo ninu ọjọ mọkanlelogun isinmi to mu iṣẹ lọwọ to gba labẹ ofin."
O ni Tinubu ko lufin kankan latigba to ti bẹrẹ isinmi naa lati ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ.
Ajayi ṣapejuwe Atiku bii ẹni to fẹran ka ri mi, kawọn eeyan le maa ri tirẹ ro.
Gẹgẹ bo ṣe wi:
"Atiku wulẹ n ṣe ka ri mi lasan ni, ipolongo rẹ ti daru, o si n wa ohun ti yoo so o mọ."
Bakan naa ni Bayo Onanuga, Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, kede ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, pe ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni awọn eeyan bii Atiku n gbe kiri nipa Tinubu.
Onanuga sọ pe Tinubu lo ran Shettima lọ si New York lati ṣoju rẹ, ki ẹnikẹni ma ṣe da Atiku to n beere pe ta lo n ṣakoso Naijiria lohun rara.
Bakan naa ni Minisita eto iroyin ati Ilaniloye, Mohammed Idris, ṣapejuwe Atiku bii ẹni to fẹ da rugudu silẹ pẹlu ai si nile Aarẹ.
O ni:
"Aarẹ Tinubu wa nisinmi ọlọdọọdun lọwọ, ipinnu rẹ lati ni ki Igbakeji rẹ lewaju ikọ Naijiria ki i ṣe ohun ti oju o ri i.
"Ijọba apapọ ti n ri awọn ọrọ ti Igbakeji aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar n sọ lẹnu ọjọ mẹta yii, to n wadii Aarẹ to si n gbe awọn igbesẹ ti ko nidii.
"Atako ninu oṣelu ki i ṣe ẹṣẹ, ara Democracy ni. Amọ ko ye ka maa pa irọ fọmọ Naijiria tabi awujọ agbaye lati mu ododo jade."
Bẹẹ ni Idris wi.
Atiku ń bèèrè: Ta ló ń darí Nàìjíríà báyìí tí Tinubu, Shettima àti Akpabio wà lókè òkun?

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/ X
Bi Aarẹ Bola Tinubu ṣe ṣafikun isinmi ọlọsẹ mẹta to lọ fun nilẹ okeere, ti yoo pada sile lopin ọsẹ, Atiku Abubakar to n dupo aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ African Democratic Congress (ADC), ti beere pe ta lo n dari Naijiria bayii ti Aarẹ ko si nile.
Atiku ninu atẹjade to fi sita loju opo X rẹ lọjọ Aje tun sọ pe Kashim Shettima ti I ṣe igbakeji Tinubu naa ko si nile, bẹẹ naa si ni Godswill Akpabio to jẹ olori ile igbimọ aṣofin agba Naijiria naa n bẹ loke okun.
Igbakeji aarẹ Naijiria nigba kan naa tẹsiwaju, pe ibeere to yẹ ki ileeṣẹ Aarẹ fesi si fun ọmọ Naijiria leyi, o ni ohun to n ṣẹlẹ yii ko yẹ bẹẹ rara.
"Lonii, awọn ọmọ Naijiria lẹtọọ lati beere ibeere kan to tọna labẹ ofin: Ta lo n ṣakoso Naijiria?" Atiku lo beere bẹẹ.
"Tinubu ko fi iwe to fi fa iṣẹ le Igbakeji rẹ lọwọ han awọn araalu gẹgẹ bi ofin ṣe wi"
Ni itẹsiwaju ẹhonu Atiku lori ọrọ yii, o ni abala 145 ofin orilẹede Naijiria ti wọn ṣe ni 1999, fi aaye silẹ fun Aarẹ lati kọwe ti yoo kede pe oun n lọ fun isinmi.
O ni yoo fi iwe naa ṣowọ si Aarẹ ile igbimọ aṣofin ati Abẹnugan ile igbimọ aṣoju.
Lẹyin eyi lo ni Igbakeji aarẹ yoo maa ba iṣẹ lọ gẹgẹ bii Adele Aarẹ.
Atiku ni lati ọgbọnjọ oṣu kẹjọ ti Aarẹ ti rin irinajo, wọn ko ti fi iwe kankan to faṣẹ le Shettima lọwọ han.
O ni bi Aarẹ ko ba fi iru iwe bẹẹ han laaarin ọjọ mọkanlelogun, ile igbimọ laṣẹ lati faṣẹ le Igbakeji rẹ lọwọ.
Amọ ni ti Naijiria ti Tinubu n dari yii, Atiku sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ rara.
O ni Igbakeji rẹ naa ni ko si tun si nile bayii, to tun ti lọọ ṣoju Tinubu nipade awọn olori agbaye to n waye ni New York, l'America.
"Ẹ ko le maa dari Naijiria pẹlu awọn ọrọ tẹ ẹ n kọ ranṣẹ lati Europe."
Atiku sọ pe ijọba Naijiria labẹ Tinubu ko le maa dari lati ilẹ okeere.
Ko ṣai kominu lori owo epo to wọn si i bayii ni Naijiria, igbesi aye ti ko dẹrun ti araalu n gbe, ati iku awakusa mẹtadinlogoji to waye nipinlẹ Niger.
O ni idari to foju han ni Naijiria nilo, ki i ṣe ki olori lọ fidi mọ ẹyin odi.
"Ìgbà yii ki i ṣe eyi to rọrun, sibẹ, Aarẹ wa lẹyin odi. Igbakeji aarẹ wa lẹyin odi. Olori ile igbimọ aṣofin agba naa wa lẹyin odi, won o si sọ nnkan kan fawọn ọmọ Naijiria bo ṣe yẹ ko ri nijọba Demokresi, pe lagbaja lo n ṣejọba."
Gbogbo eyi ni Atiku to ti n ka awọn aleebu ijọba Tinubu fun igba pipẹ sọ.
O ni ofin ko mọ ohun to n jẹ isinmi oniṣẹ ('Working vacation) bii ọna ti eeyan n gba gbe agbara aarẹ fun ẹlomi-in.
Abubakar Atiku sọ pe ilana kan naa lo wa labẹ ofin, oun naa ni Aarẹ gbọdọ tẹle.
Ààrẹ Tinubu ṣàfikún ọjọ́ tí yóò lò lájò,òpin ọ̀sẹ̀ ni yóò padà dé báyìí

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu, ti fi kun ọjọ ti yoo lo fun isinmi to mu iṣẹ dani to lọ fun ni Europe.
Ileeṣẹ Aarẹ lo kede eyi lọjọ Aje ọsẹ yii, pẹlu alaye pe opin ọsẹ ni Tinubu yoo pada si Naijiria bayii.
Tẹ o ba gbagbe, ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ni Aarẹ Tinubu kuro lorilẹede Naijiria lọ si London, ibẹ lo gba lọ si Paris.
Gbogbo ohun to n lọ ni Naijiria ni Tinubu mọ bo ṣe wa nilẹ okeere- Ileeṣẹ Aarẹ
Ninu atẹjade ti Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga fi sita lọjọ Aje, o ti ṣalaye pe Tinubu le ma si ni Naijiria lasiko yii, ṣugbọn gbogbo bo ṣe n lọ nile lo mọ.
Onanuga sọ pe Tinubu n ba gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria lọ nilẹ okeere to wa, bẹẹ lo si n dari orilẹede yii bo ṣe wa loke okun.
Bii apẹẹrẹ, atẹjade naa sọ pe àjò ni Aarẹ wa to ti paṣẹ itọpinpin iku awọn awakusa mẹtadinlogoji to waye nipinlẹ Niger, lọdọ awọn ẹṣọ NSCDC.
"Aarẹ Tinubu yoo pada si Naijiria lopin ọsẹ, lẹyin afikun ọjọ diẹ ninu isinmi to muṣẹ lọwọ."
Bẹẹ ni atẹjade naa wi.
Latigba ti Aarẹ Tinubu ko ti si nile ni Igbakeji rẹ, Kashim Shettima ti n dele de e, ko too di pe oun naa gbera lọ si America logunjọ oṣu Kẹsan-an, lati ṣoju Aarẹ nibi ipade awọn olori agbaye (UNGA) to n waye ni New York.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ Aarẹ ṣe wi, Akọwe ijọba apapọ, George Akume, to ti maa n ṣoju Aarẹ lode yoo maa ṣe bẹẹ lọ.
Onanuga tẹsiwaju pe Abubakar Yari, Adari apapọ fun igbimọ ipolongo ibo aarẹ lo ti n lewaju nibi to ba yẹ lati ṣoju ijọba apapọ fawọn lọbalọba kaakiri Naijiria.
O ni bi aarẹ ba ti de lopin ọsẹ yii,gbogbo awọn to n sọ ohun ti ko ri bẹẹ yoo dẹkun ariwo ti ko lẹsẹ nilẹ ti wọn n pa.




























