Wo gbèdéke owó tí òfin là kalẹ̀ fún olùdíje sípò ààrẹ, gómìnà àtàwọn olùdíje míì láti ná fún ìpolongo ìbò 2027

Ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, labẹ iṣakoso Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe apapọ owo ti oludije kọọkan ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ lọna, yoo na ko gbọdọ kọja biliọnu mọkanlelaadọrin-lelẹẹdẹgbẹta (N571bn) naira.
Ko din ni oludije mẹrindinlaadọjọ ti wọn ti n gbaradi fun eto idibo apapọ ilẹ Naijiria ti ọdun 2027, leyi ti awọn oludije sipo aarẹ, gomina, ile igbimọ aṣofin ati aṣofin, to fi mọ tipinlẹ.
Apapọ owo ti oludije kọọkan yoo na, lo lọ ni ibamu pẹlu iwe ofin eto idibo ti ọdun 2026 ti wọn ṣe atungbeyẹwo rẹ.
Abala kejilelaadọrun-un ninu iwe ofin eto idibo tuntun ni Naijiria lo fidi rẹ ilana ẹnawo ipolongo ibo naa mulẹ
Oludije mọkandinlogun kaakiri awọn ẹgbẹ oṣelu ni wọn n gbaradi, ti apapọ owo ti ẹnikọọkan yoo na ko gbọdọ kọja biliọnu mẹwaa naira.
Awọn oludije sipo gomina mẹtadinlaadoje (127) to n dijẹ lawọn ẹgbẹ oṣelu ni wọn ko lagbara lati na ju biliọnu mẹta-mẹta naira lọ fun eto ipolongo wọn.
Abala kejilelaadọrun-un ninu iwe ofin eto idibo tuntun yii lo fidi rẹ mulẹ.
Apapọ owo ti awọn ololudije sipo aarẹ yoo na fun ipolongo lo jẹ biliọnu lọna igba-din-mẹwaa Naira (N190bn)
Awọn oludije sipo gomina yoo na biliọnu mọkanlelọgọrin-le-lọọdunrun Naira.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ìpínlẹ̀ tí ètò ìdìbò yóò ti wáyé
Ajọ eleto idibo ilẹ Naijiria, INEC ti fidi rẹ mulẹ pe ipinlẹ mejidinlọgọn ninu mẹrindinlogoji ni eto idibo yoo ti waye.
Awọn ipinlẹ bi Anambra, Bayelsa, Edo, Ekiti, Imo, Kogi, Ondo ati Osun ni eto idibo ko tin ii waye, nitori pe ko tii pẹ ti awọn ipinlẹ naa ṣẹṣẹ ṣe eto idibo ti wọn.
INEC sọ pe ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2027 ni eto idiboyan sipo aarẹ ati ile igibmọ aṣofin yoo waye, nigba ti eto idibo sipo gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yoo waye lọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2027.
Wo iye owo ti aarẹ, gomina, ile asofin apapọ, asofin ipinlẹ, alaga ijọba ibilẹ ati kanselọ yoo ná fun ìpolongo ibo ní ìbamú pẹ̀lú òfin
Abala kejilelaadọrun iwe ofin eto idibo tọka si iye ti ofin gba oludije kọọkan laaye lati na lasiko ipolongo eto idibo, leyi to yatọ si eyi ti wọn na tẹlẹ.
Iwe ofin yii tun sọrọ lori awọn to n fi owo ta awọn oludije lọrẹ, to si ṣalaye pe ẹnikẹni ti yoo ba fi owo ṣe iranlọwọ fun oludije kan, ko gbọdọ na ju ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira lọ.
- Oludije sipo aarẹ kan le na to biliọnu mẹwaa naira fun ipolongo
- Oludije sipo gomina ko le na ju biliọnu mẹta naira lọ
- Fun ipo aṣofin, ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira ni oludije kọọkan yoo na
- Awọn oludije sipo aṣojuṣofin ko si gbọdọ na ju ẹgbẹrun lọna ọtalenigba naira lọ
- Oludije to ba n foju sọna fun ipo aṣofin nipinlẹ ko gbọdọ na ju ọgọrun miliọnu naira lọ
- Oludije sipo alaga kansu yoo na milliọnu lọna ọgọrun Naira
- Oludije sipo kansẹlọ ko gbọdọ na ju miliọnu mẹwaa naira lọ
- Ẹnikan ko gbọdọ ta oludije kan ni ọrẹ owo ju ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira lọ.
Ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá
Siwaju sii ni iwe ofin naa fidi rẹ mulẹ pe oludije to ba mọ-ọn-mọ na ju iye alakawe owo yii, yoo foju winna ofin.
Iwe ofin naa sọ pe ẹni to ba tapa si agbekalẹ yii, yoo fi ẹwọn oṣu mejila gbara, tabi ki iru ẹni bẹẹ san owo itanran tii ṣe ida kan ninu apapọ gbedeke iye owo ofin la kalẹ, ati pe iru ẹni bẹẹ tun le san owo itanran, ko si tun lọ sẹwọn.
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti pari akojọpọ iroyin yii ni BBC News Yoruba ko tii le fidi rẹ boya ẹnikẹni ti wa to ti lugbadi ofin yii ninu awọn oloṣelu ilẹ Naijiria lati ọdọ ajọ INEC.
Bẹẹ si ni ko tii si iroyin kankan to gbe e sita wi pe oloṣelu kan ti na ju gbedeke iye owo ti ofin sọ.
Àjọṣepọ̀ INEC àti INEC pẹ̀lú ICPC
Nigba to n ṣalaye nipa bi ajọ eleto idibo INEC yoo ṣe tọpinpin bi awọn oludije yoo ṣe nao wo ipolongo idibo, alaga ajọ naa to n ri sọrọ ilanilọyẹ ati ikansira-ẹni, Mohammed Haruna sọ pe awọn yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ajọ to n gbogun ti iwa jibiti nilẹ Naijiria.
"Ojuṣe ajọ yii ni lati tọpinpin eto iṣuna awọn ẹgbẹ oṣelu kọọkan," Haruna sọ bẹẹ.
Awọn ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu bii EFCC ati ICPC ni ojuṣe lati fọwọsowọpọ pẹlu ajọ INEC lati mọ bi awọn oludije ati ẹgbẹ oṣelu ṣe n nao wo, ati bi wọn ko ṣe gbọdọ na ju gbedeke lọ.
Gbedeke naa fidi rẹ mulẹ pe nigba ti oludije sipo aarẹ ko gbọdọ na ju biliọnu mẹwaa naira lọ, oluranlọwọ kan ṣoṣo le gbe ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira kalẹ lati fi ṣe iranwọ fun oludije kan.
Bẹẹ naa lo si ri lọdọ oludije sipo gomina ti ko gbọdọ na ju biliọnu mẹta naira lọ fun ipolongo.
Àwọn olùdíje sípò ààrẹ
Ajọ eleto idibo INEC ti gbe orukọ oludije ati awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo du ipo aarẹ ilẹ Naijiria soju opo wọn, fun awọn araalu lati ri, lara wọn si ni Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.
Oludije mọkandinlogun ni ajọ INEC fi soju opo wọn, nibi ti awọn bii igbakeji aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar to n dije lẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC; ati gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, Peter Obi toun di n dije lẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress, NDC, ati awọn miran wa.
Awọn oludije bii Sandy Onor tẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party; Omoyele Sowore tẹgbẹ oṣelu African Action Congress; Seyi Makinde tẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement; Donald Duke tẹgbẹ oṣelu Peoples Redemption Party ati Adewole Adebayo tẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party ni wọn wa ninu akọsilẹ INEC wi pe wọn yoo kopa.
Bakan naa la tun ri awọn oludije lawọn ẹgbẹ oṣelu bii: National Democratic Party, Young Progressives Party, Action Alliance, Boot Party, Democratic Liberty Alliance, Zenith Labour Party, Labour Party, National Rescue Movement, Action Democratic Party, New Nigeria Peoples Party ati Action Peoples Party ninu akọsilẹ ọhun.
Olùdíje sípò gómìnà mẹ́tàdínláàdóje
Olùdíje sípò gómìnà mẹ́tàdínláàdóje
Kaakiri ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun ni a ti ri awọn oludije mẹtadinlaadoje (127) ti wọn n du ipo gomina lawọn ipinlẹ mejidinlogun nilẹ Naijiria.
Gbogbo wọn ni yoo kopa ninu eto idibo gomina ọdun 2027 ti yoo waye ninu oṣu keji.
Ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP lo ni awọn oludije to pọ julọ, mejidinlọgbọn ni oludije kọọkan ti wọn ni; nigba ti ẹgbẹ oṣelu ADC ni oludije mọkanlelogun; ti ẹgbẹ oṣelu Labour si ni oludije mẹrindinlogun; atu ẹgbẹ oṣelu NDC pẹlu oludije mẹsan.
Ẹgbẹ oṣelu SDP ni oludije mẹfa, nigba ti awọn ẹgbẹ oṣelu bii APM, PRP ati Accord ni oludije mẹta-mẹta.
Gbogbo wọn yii ni ofin la kalẹ wi pe wọn ko gbọdọ na ju biliọnu mẹta-mẹta naira lọ.




























