Gomina Makinde:Osù tó ń bọ̀ la ó gbé ètò ààbò ilẹ̀ Yoruba jáde!

Ìwò-Òòrùn Naijiria
Àkọlé àwòrán, Gomina Makinde:Osù tó ń bọ̀ la ó gbé ètò ààbò ilẹ̀ Yoruba jáde!
Published

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti ni awọn gomina ni ẹkun Iwo-oorun guusu Naijiria ti mura lati se ifilọlẹ eto aabo to gbooro ni osu to n bọ.

Makinde sọ ọrọ yii ni Ọjọ Isinmi nibi ayẹyẹ iranti iya rẹ to doloogbe ni ile ijọsin Saint Paul's Anglican church, Yemetu, Ibadan.

O ni ki oun to lo ọgọrun ọjọ ni ijọba ipinlẹ naa ni awọn yoo bẹrẹ eto aabo to munadoko kaakiri ipinlẹ naa.

Gomina ipinlẹ Ọyọ naa ni awọn gomina ni ẹkun naa n se ipade igba de igba lati wa ọna abayọ si eto aabo to dẹnu kọlẹ, eleyii ti o ti jasi iku fun awọn eniyan kan ni agbeegbe naa.

Ìwò-Òòrùn Naijiria

Laipe yii ni gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu, Gomina ipinlẹ Ọyo, Seyi Makinde, Gomina ipinlẹ Osun,Adegboyega Oyetola, Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi,Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati Gomina ipinlẹ Ogun, dapo Abiodun parapọ se ipade ni Iwo-Oorun Naijiria lori ọna abayọ si ipenija eto aabo to mẹhẹ ni ilẹ Yoruba.