Kí ni Ooni Ile Ife lọ ṣe lọ́dọ̀ Ààrẹ àná lórílẹ̀èdè Nàìjíríà?

Aarẹ ana, Muhammadu Buhari pẹlu Ọọni Adeyẹye Ogunwusi.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji bẹ aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari wo ni ile rẹ to wa ni Daura ni ipinlẹ Katsina.

Ko si atẹjade kankan to jade lẹyin abẹwo naa lati sọ eredi abẹwo naa amọṣa àwọn ọba kan ba Olori alade ilẹ Yoruba naa kọwọrin.

Aarẹ ana, Muhammadu Buhari pẹlu Ọọni Adeyẹye Ogunwusi atawọn lọbalọba to ba a kọwọrin.
Aarẹ ana, Muhammadu Buhari pẹlu Ọọni Adeyẹye Ogunwusi atawọn lọbalọba to ba a kọwọrin.

Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ fun aarẹ tẹlẹ naa, Ahmad Bashir ṣalaye ninu awọn fọto abẹwo naa to fi sita loju opo X rẹ.

O ni ki ọbalaye naa to fi ilu Katsina silẹ, oun ati Muhammadu Buhari tun ṣe abẹwo si aafin Emir ilu Daura.

Aarẹ ana, Muhammadu Buhari pẹlu Ọọni Adeyẹye Ogunwusi atawọn lọbalọba to ba a kọwọrin.
Ọọni ile ifẹ, aarẹ Ana, Muhammadu Buhari ni aafin Emir ilu Daura