Ilé ẹjọ́ wọ́gilé àṣẹ tí Trump fi de iléeṣẹ́ ìròyìn CNN, MS NOW àti Politico ní White House

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ kan nilẹ Amẹrika ti paṣe fun ile ijọba ilẹ naa, White House, pe ko pada fun ileeṣẹ iroyin CNN, MS NOW ati Politico lanfani lati wọ ibẹ fun iṣẹ iroyin ti wọn n ṣe.
Ṣaaju ni Aarẹ Donald Trump ti kọkọ fofin de awọn ileeṣẹ iroyin naa lọjọ Ẹti to kọja lọna ati fi iya jẹ wọn lẹyin to fẹsun kan wọn pe wọn n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri.
Lẹyin aṣẹ naa ni apapọ awọn ileeṣẹ iroyin ọhun pe ẹjọ tako aṣẹ Trump, ti wọn si ni o tako ofin orilẹede ọhun, eyii to sọ pe ẹtọ araalu ni iroyin.
Ninu idajọ rẹ, adajọ Timothy Kelly sọ pe aṣẹ Aarẹ ọhun tako ẹtọ awọn akọroyin naa lati ṣiṣẹ wọn ati ẹtọ araalu lati gbọ iroyin.
Kelly sọ pe ofin ilẹ Amẹrika fun araalu laaye ki wọn kọkọ gbọ tẹnu wọn ki ijọba to fofin de wọn lori irufẹ ẹsun ti wọn fi kan awọn akọroyin naa.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Trump yoo bu ẹnu atẹ lu awọn ileeṣẹ iroyin, paapaa ileeṣẹ iroyin CNN.
Lara awọn ẹsun to maa n fi kan CNN ni pe wọn maa n mọọmọ gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri.
Wayi o, ofin ti Trump fi de awọn ileeṣẹ iroyin wọnyii lo n waye lasiko ti ọpọ araalu ko gba tirẹ mọ, koda, a gbọ pe o ṣeeṣe ki ẹgbẹ oṣelu rẹ, Republican lulẹ ninu eto idibo ti yoo waye ninu oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii.
Ọkan pataki lara awọn idi ti awọn ọmọ ilẹ Amẹrika kan ko fi gba ti Trump mọ ni ogun ti ijọba rẹ ati orilẹede Israel n gbe ri Iran.
Mi o mọ̀ bóyá kí n pa Iran run ni, tàbí ká jọ sọ àsọyépọ̀ - Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump, sọrọ to milẹ titi nibi ipade awọn olori orilẹede agbaye to n lọ niluu New York lAmẹrika.
Trump mẹnu ba orisiiriṣii nnkan bii ogun Russia ati Ukraine, ọrọ lori ọgbọn atọwọda ti wọn n pe ni AI to fi mọ ọrọ lori ogun to bẹ silẹ laarin Iran ati Amẹrika.
Wọnyi ni diẹ lara awọn nnkan ti Trump mẹnu ba ninu ọrọ rẹ:
''Ṣe ki n pa Iran rẹ ni, abi ka jọ sọ asọyepọ?''
Trump beere bo ya adehun pẹlu Iran le jẹ ki orilẹede naa dara si i ju ti atẹyinwa lọ.
O beere boya ki oun fi opin si orilẹede naa ni, abi koun tete ṣekupa awọn eeyan orilẹeede naa.
Aarẹ Amẹrika ni oun tun le pa gbogbo orilẹede naa rẹ ti ko si ni si orilẹede kankan ti wọn n pe ni Iran mọ lọjọ iwaju.
Amọ, Trump ni oun gbagbọ wi pe awọn yoo pada buwọlu iwe adehun lẹyin eto idibo Amẹrika oṣu Kọkanla to n bọ.
Orukọ AI yoo yipada si SI
Aarẹ Trump tun sọ pe orilẹede Amẹrika ni akọkọ to kọkọ ṣe imọ ijinlẹ ọgbọn atawọda, iyẹn AI.
Trump ni oun ko fẹ orukọ ''atawọda ti wọn n pe AI tori o jẹ ko dabi nnkan ayederu.
Aarẹ Amẹrika ni kii ṣe nnkan ayederu rara, nnkan to lagbara gidi gan an ni AI.
Aarẹ wa sọ pe Amẹrika yoo yi orukọ AI pada si SI eyi to tumọ si ''Super Intelligence.''
Awọn aṣoju orilẹede Cuba binu jade lẹyìn tí Trump ni orilẹede wọn ti kùnà
Bi Trump ṣe n sọrọ lori orilẹede Cuba ti o si ni orilẹede naa ti kuna lawọn aṣoju orilẹede Cuba binu jade nibi ipade náà
Trump ni "ìjọba mi n wa ọna lati ṣe ayipada ìjọba apaṣẹ wa a to wa ni Cuba.
Orilẹede naa ti kuna lai ṣe ani ani.
Ilẹ Cuba ti kuna, yoo si pada wo lulẹ.
Marco Rubio ti n ba orile-ede Cuba sọrọ, a maa ri nnkan to maa ṣẹlẹ.
A o ni faye gba awon ọta Amerika lati lo orilẹede to sun mọ wa láti ṣe wa ni ibi.
Lori ogun Russia ati Ukraine
Aarẹ Amerika sọ pe ijọba oun n ṣiṣẹ pọ pẹlú Russia ati Ukraine lori ọna lati fopin si ogun naa.
O ni ko ní pẹ rara ti ogun naa yoo fi pari.
"Àwọn ọmogun to le ni ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn ti wọn jẹ ọdọ ni wọn n ku losoosu ninu ogun yìí.
Eyi kii ṣe nnkan ti mo fẹ maa ri mọ tori nnkan to buru ni."
Trump fikun ọrọ rẹ pe oun ti fopin si ogun bíi mẹjọ lati igba toun ti de ipò ààrẹ.
Lori ile ẹjọ agbaye ICC
Ààrẹ Amerika rọ gbogbo orilẹede to jẹ ọmọ ìgbìmọ̀ ile ẹjọ to n gbẹjọ iwa ọdaran lagbaaye, ICC wí pe ki wọn kuro ninu ìgbimọ ile ẹjọ naa.
O ni ile ẹjọ naa kun fun ibi, ko sí ṣeni to le dari rẹ.
Trump ni oun ko ni f'ayé gba ilé ẹjọ́ ọhun lati sewadii ọmogun Amerika kankan.
"Idi niyi ti mo fi n kepe awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ ile ẹjọ ICC lati kọwe fipo sílẹ."
Trump koro oju si b'awọn orilẹede agbaye ko ṣe sọrọ nipa oniruru iwa ibajẹ to n ṣẹlẹ káàkiri àgbáyé, sugbon ti wọn n bu Amerika nikan lori nnkan to n ṣe nípa ṣiṣe inunibini s'àwon Kristẹni, awọn ko-sakọ ko-sabo àti ọrọ àwọn èèyàn tó n wọ Amerika lọna aitọ.
Ìdí tí Trump fi fòfin de CNN àti iléeṣẹ́ ìròyìn méjì mii ní White House
Aarẹ Donald Trump orilẹede Amẹrika ti kede pe oun ti fofin de ileeṣẹ iroyin CNN, MS NOW ati Politico ni ileeṣẹ ijọba Amẹrika White House.
Trump ṣalaye loju opo X rẹ pe awọn ileeṣẹ iroyin naa maa n kọ irọ nipa ijọba oun ni gbogbo igba.
Amọ, aarẹ Amẹrika ko sọ apẹẹrẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin naa ti parọ nipa isẹjọba rẹ.
Trump ko ṣalaye bi ifofinde naa yoo ti ri, a o le sọ pe boya awọn akọroyin ileeṣẹ iroyin mẹta naa ko ni lanfaani lati wọ White House mọ.
Ẹwẹ, CNN ti ṣapejuwe ikede Trump gẹgẹ bi eyi to tako ominira ileeṣẹ iroyin Amẹrika ati igbesẹ to lodin sofin.
O ṣee ṣe ki kawọn ile iroyin tọrọ kan pe Trump lẹjọ lori ọrọ naa.
Awọn akọroyin CNN ati Politico si wa ni White House lẹyin ti Trump ṣe ikede naa.
Awọn akọroyin CNN tun ba Igbakeji Aarẹ Amẹrika JD Vance rinrin ajo lọ si Iowa.
Ileeṣẹ iroyin MS NOW ti wọn n jẹ MSNBC tẹlẹ kọ lati sọrọ.
Awọn alaṣẹ CNN ṣalaye ninu atẹjade kan ti wọn fi sita wi pe ikede Trump lodi sofin, wọn ni awọn wa lẹyin awọn akọroyin awọn to n ṣiṣẹ ni White House.
''CNN ni ẹtọ labẹ ofin Amẹrika lati ṣiṣẹ wa eyi ti ijọba ko si lẹtọọ lati ṣe idiwọ kankan fun wa.
Ti Trump ba tẹsiwaju lati fofin de awọn akọroyin wa ni White House, eyi ṣe ilodi si ẹtọ wa to wa ninu iwe ofin Amẹrika,'' CNN lo sọ bẹẹ.
Ileeṣẹ iroyin Politico naa sọ pe awọn yoo tṣiwaju lati maa ṣiṣẹ awọn ni White House.
Bakan naa tun ni ileeṣẹ iroyin naa sọ pe awọn yoo gbija ara awọn pẹlu ofin ti Trump ba ni kawọn akọroyin awọn ma lọ White House mọ.
Trump sọ pe ''Ko yẹ kawọn ileeṣẹ iroyin maa kọ irọ ninu iroyin wọn nipa aarẹ orilẹede Amẹrika tabi ijọba Aarẹ Trump tabi orilẹede Amẹrika gan an.''
Trump ko ṣalaye iroyin kan pato gẹgẹ bi apẹẹrẹ ninu ọrọ ti o kọ soju opo rẹ lori ayelujara naa.
Aarẹ ẹgbẹ awọn akọroyin White House, Jacqui Heinrich, sọ pe oun wa lẹyin awọn akẹgbẹ oun ti ijọpa yan ṣọju.
''Ọrọ yii kii ṣe nipa ẹtọ awọn akọroyin nikan, o niṣe pẹlu ẹtọ awọn eeyan Amẹrika lati gbọ iroyin lori gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ ni ọfiisi aarẹ Amẹrika,'' Heinrich ṣalaye.
Lati igba ti Trump ti bẹrẹ ijọba rẹ fun saa keji gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Amẹrika ni gbọmisii-omi-o-to ti n wa laari oun atawọn akọroyin White House.
Ti ẹ o ba gbagbe, Trump fofin de akọroyin CNN, Jim Acosta wi pe ko ma wa si ileeṣẹ ijọba White House mọ ni saa akọkọ rẹ gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika.
Amọ ileeṣẹ CNN gbe e lọ si ile ẹjọ nigba naa, wọn si da a pada.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post





























