Ìjọba Nàìjíríà kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ láti má ṣe gba pápákọ̀ òfurufú ńlá Ethiopia rin ìrìnàjò, ìdí abájọ rèé

Papakọ ofurufu nla Addis Ababa pẹlu awọn eeyan kan to n gba iwaju rẹ kọja
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba orilẹede Naijiria ti kilọ fawọn ọmọ orilẹede rẹ lati ma ṣe gba papakọ ofurufu nla orilẹede Ethiopia rin irinajo, paapaa awọn arinrinajo ti ilera wọn ko kun to.

Ijọba kilọ yii latari bi papakọ ofurufu naa ṣe jinna silẹ to, eyi ti wọn lo lewu gidi.

Alaye ijọba Naijiria ni kikun

Ileeṣẹ to n ri si irinajo ilẹ okeere lati Abuja ṣalaye, pe ọmọ Naijiria mẹrindinlogun (16) lo ti ku lọdun yii latari pe wọn ni ailera kan tabi ikeji wọn si wa gba Addis Ababa to jẹ olu ilu Ethiopia kọja nipasẹ papakọ ofurufu yii.

Ijọba orilẹede Naijiria tẹsiwaju pe awọn eeyan to ba ni ailera ọkan abi ti eemi wọn ko ja geere to, wa ninu ewu bi wọn ba gba papakọ ofurufu yii.

Nipa bi ilu naa ṣe ri, onka giga naa ni won lo jẹ 2,334m (7,657ft) to fi ga ju okun lọ, eyi to mu ko jẹ ọkan lara awọn oke giga lagbaaye.

Papakọ ofurufu apapọ ti wọn pe ni Bole International Airport yii lo jẹ oju ọna ti ọpọ eeyan maa n gba lati rin irinaajo laaarin Africa, Middle East ati Asia, miliọnu-miliọnu eeyan lo n gba ibẹ lọdun.

Ṣaa, ijọba Naijiria ko fi orukọ awọn ti wọn ni wọn di oloogbe naa lede, bẹẹ ni wọn ko sọ idi iku wọn.

Ijọba rọ ẹnikẹni to ba ni ailera ti oke giga le ṣakoba fun lati ro o lẹẹmeji ko too gba ọna Addis Ababa.

Wọn ni ki wọn si gba itọsọna lori ilera wọn ki wọn too rin irinajo naa.

Ki lo de to lewu fawọn eeyan to ba ni ailera ọkan ju?

Gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si irinajo ilẹ okeere l'Abuja ṣe ṣalaye, ki I ṣe pe ijọba fẹ dẹru ba awọn ọmọ Naijiria lati ma ṣe gba olu ilu Ethiopia.

O ni gbigba ibi giga kọja fawọn eeyan to ni ipenija ọkan ati ti ẹdọforo yoo mu ki atẹgun eemi to yẹ ko de ọkan wọn dinku, yoo si ṣoro lati de inu ẹjẹ, bawọn amoyẹ ṣe sọ.

Eyi tumọ si pe ọkan yoo ni lati maa ṣiṣẹ agbara ju bo ṣe yẹ lọ lati ri eemi to to (oxygen) si ẹya ara, eyi to le mu ki ọkan daṣẹ silẹ, gẹgẹ bi American Heart Association ṣe sọ.

Ai si eemi lori oke giga yii le fa ki ooyi maa kọ eeyan, o le fa ko maa rẹ eeyan o si le ma jẹ kawọn eeyan to ni ilera pipe gan-an mi daadaa.

To ba wa jẹ pe awon ti wọn ti ni iṣoro eemi tẹlẹ ni, wahala gidi ni yoo da fun wọn bi iwadii ṣe sọ.